Wednesday, 26 November 2014

KI NI A N PE NI IWOFA

Opolopo eniyan nii ro pe itumo Iwofa ni Eru. Be e ko, iyato wa ninu won. Ka muni ni Iwofa san ju ka muni ni leru lo.
Nigba t eru ba n sise ninu ojo ati oorun, ti oju re npon bi aso oyin ati ara re si ri siosio bi ti elede, sebi I se ni Iwofa I se tire ni iwon, ti alo ile olowo re jeje. Gege bi a ti mon wipe ohun ti a fi se eru a ko le fi se Iwofa nitoriwipe arapa la nra eru eni, bi o ku, bi  o ye, ko da nkan kan amuni ko si a fi awoni roro lasan.
Ilo ti an lo Iwofa yato patapata si ti eru nitori pe ona ti a gba ri won yato gidigidi. Eru ni eni ti a mu wa ile lati oju ogun. Bi o se omode, bi o se agbalagba bi a ba ti muu de odede, abuse ti buse. O di ko maa sise fun eni bi akura, ki a ran an ni igba ise ki o je leralera. Bi o ba si ku, bi igba ti ewure eni ba ku ni.
Sugbon ti Iwofa yato lopolopo. Iwofa ni eni ti a fi ya owo, ti mba ni sise titi onigbese yoo fi ri owo re san.  Gegebi a ti mo pe ika owo ko dogb, ti ese paapaa ko fi ori-kori. Bi a ti ri oloko nla ninu awon baba nla wa, bee ni a si ri supe eniyan ti ko le so kobo meta di kobo marun ninu won. Awon oloko nla ni awon alagbara, ti nwon n sise ti won si n lowo lowo. Ko si iru bira ti nwon ko le da, nitori bi nwon se n kole mo ile ni nwon si leesin leekan. Iru awon eniyan wonyi bi a lu won gba, a o ba owo lowo won, bi a ba ji won loju orun pelu kobo-kobo ni.
Awon ti ko ni iru ebun bee a lo ya owo fun gbogbo ohun pataki ti nwon ni lati se. Se eni ti ko ba le je “Saka” se a je “Soko”. Bi a ba to ile ko a o ko ile, bi a ba to aya fe, a o fee. Bi a ba si to awon nkan wonyii se ti ko si kobo nko? Dandan ni ka gbe itiju ta ka lo si ile eni ti o ju ni lo. Ko si ohun meji bikose lati ya owo. Bi alagbara ba si ronu re titi a ya oluware lowo. Eni ti o lo ya owo ni yoo se ileri ohun ti o maa se. Bi o ba je eniti ko ti bi omo rara, o le fi ara e s’ofa owo ti o ya. Bi o ba si je eni ti o ti bi omo, yoo fi omo re s’ofa owo ti o ya.


Iru omo bee ti a fi s’ofa owo ti a ya ni a n pe ni Iwofa. Ise Iwofa yi ni lati ba olowo baba re se ise ni ile ati l’oko. Ohunkohun ti a ba ni ko se lo gbodo se. Sugbon ohun ti a ko ba le fun omo ara eni se a ko gbodo fun Iwofa se. Nitori bi ope bi o ya, Iwofa yo pada lo si ile re. “Iwofa n bo wa di oga, akoko ti yoo se ni eda ko mo”. Bi a ba daso fun omo ara eni a o da fun Iwofa pelu. Onje ti omo wa ba je naa ni Iwofa yoo je. Eni ba gba Iwofa sodo gbodo sora re gidigidi ki o rii pe oun ko si iwofa naa lo. Iwofa ko gbodo ku si ile eni, ki gbese ma baa ju eyi ti o wa nibe fun olowo.
Iwofa yi yoo maa sise titi baba re yoo fi san gbese re tan fun olowo. Ni aye igaani awon obi n fi omo won sofa tori kobo marun ti an pe ni egbaa tabi kobo mewa ti a n pe ni egbaaji. Elomiran le se iwofa fun osu meta tabi mefa ki owo naa to pe. Bi o ba si je owo to to egbaarun ti a npe ni kobo medogbon tabi oke kan ti a npe ni aadota kobo, dajudaju iwofa yoo se to ise odun meji si meta.
Baba ti o fi omo re sofa ko ni joko lasan, oun naa yoo maa sise taratara ko ba le tete mu omo re pada. O le san owo naa leekan tabieemeji. Sugbon ojo ti o ba san owo re tan ni omo re yoo kuro ni oko ofa.

A ri iwofa miran ti o je pe bi o ba pe pupo a fe di ara ile eni. Nitori pe awon miran wa ti awon obi won ku ki nwon to san gbese won. Iru iwofa be yoo ma sise lo. Yoo lo opolopo odun, yoo si maa se bi omo ni ile olowo re. Iru awon bee le fe iyawo nile olowo won, ki nwon si di eni a nfi gbese naa ji patapata.
Mo fe je ki a mo pe okunrin nikan ko la fi ma n s’ofa. A le fi okunrin s’ofa sodo okunrin ati obinrin sodo obinrin. Bi a ti nya owo lodo okunrin l’n nya owo lodo obinrin. Iwofa okunrin a ma ba olowo re se ise oko, Iwofa obinrin a maa ba olowo re se isekise ti o ba kan nile olowo re. Nwon le ran owu ki nwon si hun aso. Ojo mefa-mefa ni iwofa I se ise l’oko olowo re ninu ose pelu ero pe yoo lo ojo kan ti o ku fun ara re. Ninu sise eyi ni oro naa ti suyo eyi ti a npe ni IWOFA tabi IWO-EFA (sise ise ojo mefa-mefa).   

Tuesday, 25 November 2014

ASA ILA KIKO NI ILE YORUBA

Bi a ba wo oju opolopo awon omo orile-ede Naijiria, a o ri orisirisi ila loju won. Ogooro eniyan ni ko mo idi re ti a fii ko ila.
Nje kini idi re ti a fi ko ila?
Idahun fun enikeni ti o ba se ibeere yi pin si ona meji. Nigba laelae, ogun ati ote po ni orile –ede Naijiria.
Lakoko yi ni omo nsonu lairo-tele. Awon alagbara nko awon omo eniti ko ni agbara bi ti won ta. Bi nwon ti n ko omo won be ni nwon nko aya won paapaa. Beni opo gende (youth) nsonu, ti a nfi won se awaari. Bi a ti nko won la n tawon leru fun awon orile-ede miran. Bi awon ti a ta leru wonyi, yala lati idile kan naa tabi ilu kan naa ba pade, nwon ko ni mo ara won rara. Sugbon awon agbalagba ronu pe o ye ki kini kan bi ami wa, eyi ti nwon yoo fi maa mo ara won. Ti nwon o si le so lesekannaa ilu ti eniyan kan ti wa ni kete ti aba rii. Ogbon ila kiko yi kii se ti gbogbo orile-ede yi ni lati ibere bikose ohun ti awon eniyan orile-ede yi jogun lati Iwo-Orun nibi ti asa naa ti koko bere.
Alaye keji fun ila kiko ni pe boya awon eniyan Iwo-orun nibi ti asa yi ti bere ro pe yoo bukun ewa ara won nipa sise bee. Bi a ba wo ju elomira ninu awon Okunrin tabi awon obinrin ti o ko ila, ao rii pe ila naa dara pupo loju opolopo won. Dajudaju, asa lati bu si ewa ara ni iru awon bee ka ila kiko si. “Bi a ko ba tori isu jepo, a o tori epo je isu”. Bi a ba wo finnifinni, a o rii pe ila yi yato si ara won lati agbegbe si agbegbe tabi ilu si ilu nibomiran. Awon Oyo nii ko orisirisi Abaja, Pele ati Ture. Nwon tun nko Abaja meta-meta, tabi Gombo, Keke ati Gombo papo. Awon Ekiti a bu meta-meta ti o gbooro, tabi eyo kan soso ti o gbooro, tabi meta oro lori meta ibu ti o gbooro. Awon Egba ni nko meta-meta ti ko gun ti ko si gbooro. Awon Ijebu a maa ko meta-meta tabi meta loke, meta ni isale re. Awon Owu naa mbu Abaja, nwon si mbu Keke pelu. Pupo ninu awon Ife kii kola, sugbon awon miran nko meta-meta nigba miran. Awon Ijesa nko mefa. Ondo nko meta-meta. Awon Iyagba nko meta-meta ti o fere papo l’eba enu won.
Ogunlog ile la ti pa asa yi re, sugbon opolopo idile wa ti ko fe fi asa yi sile rara. Lara awon apeere iru awon ila ti awon Yoruba ma n ko niwonyi lati fi dawaloju pe awon ila wonyi yato si ara won lati ilu ati ile si ara won.

ABAJA
Eyi ni awon ila meta ti a fa nibu lori ara won tabi mefa ti a to ni meta-meta nibu bakanna.

ABAJA MERIN
Iyato to wa laarin eleyi ati eyi to ea loke yi ni pe. A bu ila toke ni meta-meta, sugbon a bu eleyi ni merin-merin.
ABAJA ALAGBELE
Iru abaja eleyi ni a ma n bu si oju eniyan ti a si tun gbe meta oro miran le lori.

PELE
Ila meta ti a fa sereke ti o duro looro. O maa nye awon ti o ba bu ila bee. A si maa npe awon eniyan bee ni “peleyeju” fun ewa tii fun won.

TURE
Ila meta kekeeke looro ati meta miran ti o gun ju meta isaaju lo.

KEKE TABI GOMBO
Awon ila ti o gun ti a fa lati ori wa ti o si te woroko logangan aarin oju ati eti si isale eeke.
Gbogbo awon ila oju wonyi lati ekini (1) titi de ekefa (6) lo wopo laarin awon omo Oyo, Ibadan, Ogbomoso, Ede, Iwo ati Osogbo.
Awon ila miran tun wa ti o fi diedie yato si awon ti o wa loke wonyi.
Opolopo won lo dabi abaja, keke, pele sugbon nwon ko gbooro to abaja, keke ati pele awon Oyo.
Apere awon ila bee niiwonyi:
ABAJA OLOWU
Ila meta oro ati meta ibu ni isale won.

KEKE OLOWU
Eleyi yato si keke ti akoko. Siso ni keke Olowu, bibu ni Keke Oyo.

PELE IFE
Ila meata oro

ILA ONDO
Eyokan soso ti o gun ti o si jinle ni

PELE IJEBU
Ila meta ti o gun die ni

ABAJA EGBE
Meta ooro ati meta ibu, ti a ko lori ara won.

PELE IJESA
Meta looro

ABAJA IJESA

Merin ni ibu.

PELE ATI ABAJA EKITI
Awon wonyi yato si pele ati abaja ti a ti salaye soke nitori pe nwon gbooro pupo ju ti isaju lo.
                                                                   ABAJA EKITI

                                                                        PELE KAN

                                                                      PELE META

OWE ATI AKANLO EDE YORUBA

Ede Yoruba rorun lati ko ati lati gbo pelu. Akeko ni lati fi okan ati eti sile dada, ki o baa lee mo pelu irorun. Bi eniyan ba sunmo awon agba, yoo tete gbo awon owe ati asayan oro ijinle ede Yoruba, bakannaa ni kika re yoo si rorun, nitoripe faweli (vowels) re farakinra pelu oyinbo.
Awon ami ti o wa lori oro kookan, ni nmu aka yeni to ni itumo t’o kun rere wa.
 ami isale – sokoto, eru, kokoro, fila, isale (Trouser, Fear, Papa, Cap, bottom)
ami oke – digi, papa, dupe, sibi, kokoro (mirror, grassland, female name, spoon, key)
Oro ti ko ba ni ami Kankan lori ni ami aarin – aso, esin, emu, pupa, omi. (cloth, horse, palm, wine, red, water)
A ma nlo owe tabi gbolohun atenumao lojoojumo nibigbogbo, nigbagbogbo tabi lore koore.
Awon agba ati odo t’o ba m’ oye je orisun owe tabi asayan oro ijinle. Bi eniyan ba sunmo won, onitohun yoo ni itumo t’o kun – ile eko yi, enu agba ni o. 
1. Awon Owe To Wa Fun Esin – Sise Ife Ati Liana Olorun (Godliness)
   Olooto kii l’eni sugbon ko si sun si’ poi ka.
   B’o l’aya, o se’ka, b’o ba ranti iku Gaa k’o sotito.
   A dun-un se bi ohun ti Olorun l’owo si, a soro se b’ohun t’ Olorun ko l’owo si.
   B’oore po, a di bi.
2. Awon Owe Fun Ise Sise (Industry) Oju boro ko ni a fi ngb’omo lowo ekuro. A gbe’ le ya’na, ni a gb’ oko yaa’ run. Igba yi l’aaro, t’ arugbo nko’ gba. O ko s’emu l’o gbe, o ko t’ eguro l’ofa, o de di ope, o gb enu s’oke, ofe ni nro?
3. Awon Owe Fun Iwa Rere (Decency)
   Ajobi ko f’ eke.
   A wo ‘lu ma te, iwon ara re lo mo.
   Falana gbo tie, t’ara eni l’a ngbo.
   B’ o see re, o ban be.
4. Awon Owe Fun Ibowo Agba (Respect)
   Ai f’agba f’enikan, ko j’aye o gun.
   Enu agba l’obi ngbo.
   A gba ko si, ilu baje, bale ile ku, ile d’ahoro.
   Ai feni p’eni, ai f’eniyan p’eniyan, l’ara oko fin san bante wo lu.
5. Awon Owe Fun Aibikita (Carelessness)
   Enu ko sun won, elenu pon la.
   Ibi ti a r’aye l’a je, b’ ojo npa o, maa to sara.
   Ara o bale, olori arun. Oju yo ro, ni’ rore nso.
6. Awon Owe Fun Awon Ika (Wickedness)
   A k’eyin je, ko mo pe’ di nro adie. A di’kuta s’eru eni o fuye.
   B’ eniyan ba nyo’ le da, ohun buburu a maa yo se.
   B’oo ba, o pa, b’ o bu l’ese.
7. Awon Owe Fun Igboya (Courage)
   Ai lee ja, ni won o bi mi ni le yi. Yijo ekun, t’ojo ko.
   Omo ajanaku ko ni ya’ra, omo t’ekun bi, ekun ni o jo.
   Piri l’olonge nji, a kii b okunrun eye lori ite.
8. Awon Owe Fun Ifowosowopo (Cooperation)
   Ajeje owo kan ko gb’eru d’ori. A kii l’agbara to kekere sikekji.
   Aja t’o ba l’enu l’ehin lo np’obo, eyiti ko l’eni l’ehin, a p’aaya.
9. Awon Owe Fun Eniti O Nse ’Mele (Laziness)
   A de bi eyin ma si agba ole.
   Akuko ko, ole pose.
   Ole ba ti, o gb’odo nla.
   Ibi ti a r’aye l’a nje, b’ojo npa o, maa to sara.
10. Awon Owe Ti A Fi Npon Ni (Flattery)
   Yojo l’enu araye nda.
   B’aye ba t’ ori eni, iwa ’baje l a nhu.
   Eni t’araye fi np’Adegun, naa ni won fi np’Adeogun.
   Mo dagba nko S’oge mo, owo ni ko si

                          EYI NI AWON ASAYAN OWE ATI AKANLO EDE YORUBA
1. A ke kaakaa k’oloro o gbo b’oloro ba gbo kinni o se!
2. Agba kii wa l’oja, k’ori omo titun o wo.
3. Apata le, oloko da si.
4. Ayangbe aja ni ndun, sugbon ki ni a o je, k’aja o too gbe?
5. A k’eyin je, ko mo pe ’di nr’ adie.
6. Agba t’ o ni suuru, ohungbogbo lo ni.
7. A kii kanju tu’lu aran, igba re ko to se l’obe
8. A ki lo si Ede k’a ba odede je, toripe bi a ba t’ Ede de oode naa l’nbo.
9. A ki rue ran erin l’ori, ki a tun ma woe era nle.
10. Ai gbo ’fa l’a nbo.
11. Ajeje owo kan ko gb’eru d’ori.
12. A kii l’agbarato kekere sikeji.
13. Alagbede t’o nlu’ rin loju kan naa, ni ohun to fee mu jade nibe.
14. A gb’oju l’ogun fi ‘ra re f’osi ta.
15. Atete so’ ko, lo ns’ogututu, enit’o so kehin a so’ daro.
16. Aja to ba l’ehin l’o np’obo, eyiti ko l’ene l’ehin a p’aaya.
17. Aladugbo kii d’ola.
18. Aileeja ni, won ko bi mi ni ile yi.
19. Agba tan l’angb’ ole, b’a d’aso, fole a pa l’aro.
20. A t’ehin rogbon, a ke ti aja, a ke l’eti tan, o nm’obe pamo.
21. Aye yi ki s’awaa lo, orun nikan l’aremabo.
22. Amona esin, ko j’amona mo.
23. Agbara ojo ko p’ohun o ni ’le wo, onile ni ko ni gba fun.
24. Ara ile eni ko s’eni, eniyan eru ko s’eniyan, a ko ni fi w’alaroo lasan.
25. Ale o mohun ti ns’ osafi, osafi nkuu lo ni ’le, ale re npe ni ’ta.
26. A pe ka too sun ni ’le wa l’ana, ibere ofofo.
27. A kii l’gbara nle, k’a w’egbaa r’ode.
28. Aye ko fe’ni f’oro, a f ori rni.
29. A dagba ko’la, nso ni nso.
30. A pe loowe, o l’aro nrue.
31. A tete de kii s’ana, enu o ku ’waju lo mo.
32. A bi nu fufu l’o nw’onje fabirun-were-were.
33. Agbe ‘le ya ‘na, ni a gb’oke yaa’ run.
34. Aja kii roro, k’o s’ ojule meji.
35. A kii s’oosa l’pju ofon, b’ o ba d’ale a maa tu pepe.
36. A kii na’ma tan k’a f’owo ko’mu.
37. A ki l’oko ni ’le, k’ a beere aso.
38. Alara l’aro k o r’ oun, e lo ku aisun, o ku aiwo.
39. Ara eniayn ni’re wa.
40. Ailora ogongo, a ko le fi we t’agilinti/adigbon nanku.
41. Ara la mo, a ko mo’nu yin.
42. Abere kii ko’hun aso, ko gbodo k’ohun odo.
43. A t’apata nde, o soro se.
44. Adie funfun, ko m’ara re lagba.
45. Alaran ni gba’ara re ga, bi adie oba wo ’le, abere.
46. A jaa-jo, ti kin je k’okunrin o l’omu.
47. A soro yan ’ro l’o p’lenpe akoto, t’ni ’gba wuwo j’awo lo.
48. A s’ape fun were jo, oun were ogboogba.
49. Aiku eklu, a ko lee f’awo re se gbedu.
50. Adan d’ori k’odo, o now’se eye.
51. Akuko l’o f’ogbe ori re fun kolokol ye wo.
52. Abata ta kete bi enipe ko b’odo tan.
53. Ayeku l’a nma ayo.
54. Apon ti ko l’obinrin, a bebe oran, a ni joo o, o ba nda’ k obo.
55. A nki, a nsa, o l’oo m’ eni o ku.
56. Aiduro ni’jo.
57. Agbigbo, o ku eru ori.
58. Alate rogodi, l’o nd’oko duro d’olosinsin.
59. A nge peepeepee bi awo baba ‘sona.
60. Ai rin jinna, ni a ko labuke okere, b’ aa ba pe l’ori imi, a o rebuke esinsin.
61. A sare nu eekan ko sa lasan, bi ko le nkan, nkan le.
62. Aja kii gbagbe oloore.
63. Adie rano, kii se ohun ajegbe.
64. Aipo nile wa ni ko jeki a ho ni a nwi. A ko gbodo so pe a kop o, ni ko je k’a gbon.
65. A k’adie ta, a f’owo ra’wo, awo naa ye mefa, o pa kan, soso.
66. Abiamo b’oja gbooro gbooro.
67. Ai tete m’ole, ole nm, oloko.
68. A kii so ’ri olori, k’awodi o gbe tei lo.
69. A ko gbodo tori awijare, ki’to o tan l’enu.
70. A kii gb’enu okunrun m’ oogun.
71. A ko gbodo gb’eru eleru l’ori, ka fa t’eni lowo.
72. A ko gbodo gb’eru d’obe nu.
73. A kii gbon bi eniti nso ni.
74. Ai mori eku de, kii je k’a mo p’ologbo ns’ode.
75. Ai f’eni p;eni, ai feniyam p;eniyan, ni mu ara oko san bante wo lu.
76. Aparo kan ko ga ju’kan lo, a f’eyi to ba gori ebe.
77. Aidun osan l’anmu ‘kan soso, nbosan ba dun, ao m’ogbon.
78. Ai gbe’ le m’ eni ogun o pa.
79. Awodi t’o nre ‘bara, efufu ta ndi kan, o ni o kuku ya.
80. A kii r’ajeku oro.
81. A kii ma gun ma ate ki’ yan ewura ma l’emo.
82. Aja m’ omo re fun l’omu, o ma t’ekulu ki mo le.
83. Awa ti g’oke agba, k’afara o too ja, eyin to ku, k’mura.
84. Ajeele gbese, kii je k’egbaafo o to o na.
85. A kii r’ajanaku ta l’eemeji.
86. Ai jeun sun ekun, ko ni si oju aja.
87. A kii tu ‘fun abuke l’ehin re.
88. Aja t’o re ile ekun to bo, ki a ki ku ewu.
89. Agemo kii ku ni kekere, a fib o ba tepa ileke.
90. Arun t’o n so ogoji, l’o ns oodunrun, ohun to ns’ Aboyade gbogbo oloya l’o nse.
91. Ahere ni yoo kehin oko, aatan ni yoo kehin ile.
92. A wo’lu ma te iwon ara re lo mo.
93. A ti ku ko tejo, bii k’ a r’eni f’ehin sile fun.
94. Aisi nle ologbo, ile di ‘le ekute.
95. Ai mase ‘ko orogun –oka, lo jek’o t’ori boo mi gbigbona.
96. Aye l’oja, orun ni’le.
97. A kii f’ola la’ yo.
98. A sese jade akan, a ko mo’ bi t’ o nlo.
99. A sese yo ogomo, t’o l’ohun o kan ‘run, ko beere lowo baba re – igbago?
100. Arike, ariyo, ni t’omo titun.
101. A kii t’oju elese mesan ka.
102. Adie to fo’oju, oru ni won nta.
103. Alejo to fo’ju oru ni won nta.
104. Alejo to t’tori obinrin wo ilu, opa l’ o npa won je.
105. Amukun eru re wo, o ni oke le now, e o wo ’le.
106. Ai f’ele ke boosi, ni ko je ko see jo.
107. A ti ran mu gangan, ko s;ehin eekanna.
108. A kii fi gbese s’orun se oso.
109. A ngb’omodie lowo iku, o ni ki e jeki ohun lo si koto aatan.
110. A l’aje f’enu lo ‘le bi adie.
111. A gb’oojo, kii gb’ojo kan an ti.
112. Ai m’asiko, l’o naamu eda.
113. A ge ku ejo, ti ns’oro bi agbon.
114. Agba to r’ejo ti ko sa, ara iku l’o nya.
115. A so ‘ro an d’omi, ki ‘le to mo – alayidayida.
116. Akunleyan, ohun l’adayeba.
117. A nb’omode gbe yeepe, o ni meta-meta l’ohun ngbe, taa l’a ni ko gbe gbogbo re.
118. Aye oko bi aye ile, aye agbe bi aye aje rorun.
119. Abiku s’ologun d’eke.
120. Awodi jeun epe sanra.
121. Adie nlaagun, iye ni ko je k’a mo.
122. Apaadi ti a ma mo ogiri, t’ogiri ni nse.
123. A dif a feniti nla koto agbara l’eerun won ni bawao, o ni bi ko ba gba be l’eerun, yoo gba l’ajo
124. Arun t’o ti ‘lekun, iku ni yoo si.
125. Atelewo eni, kii tan ni je.
126. Asaale l’oja ntoro.
127. A kii f’owo r’ooyi, k’o mo ko ni l’ oju.
128. Araba nt’ara mu, odo ngb’arere, eniti o mo we nb’ odo lo.
129. A ri t’eru maa wi, a f’appadi feere bo tire mo ile.
130. A pe jeun, kii je ‘baje.
131. Ajoje o dun, g’enikan ko ba ni.
132. Alejo t’o f’oru wo’ilu, igi da ni yoo je sun.
133. A ti gbe ‘yawo ko t’ejo, owo obe, l’o soro.
134. A kii pe k’omode o ma d’ete, b’o ba ti le dagbo gbe.
135. Ai s’ eniyan keta ni eniayn meji nj’ajaku akata.
136. Alaso kan, kii s’an are.
137. A kii s’ore alabere, ki a duro lowo otun.
138. A kii le’ mo buruku f’ekun pa je.
139. Awodi oke, ko mo p’ara ‘le now hun.
140. Ai ko wo rin ejo, l’o nse ku pa won.
141. A kii nii ‘mo, k’a nu’le.
142. Abere a lo, ki ona okun o too di.
143. Ala t’aja ba la, inu elede ni ngbe, oro huu-hun inu elede ni ara si.
144. A gun t’aso lo.
145. Ajulo ko pin, ti ‘jakadi ko.
146. Asiwere eniyan ni nwipe, ori oro l’oun ba, oun ko ba idi re.
147. Agbara ojo ko p’ohun o ni le wo, onile ni ko ni gba fun.
148. Aabo oro l’a nso f’omoluabi, b’o ba de ‘nu re, a di odidi.
149. A kii f’ogboju j’ eleko.
150. Ai fagba f’enikan, ko j’aye o gun.
151. Aropin ni t’eniyan.
152. A kuku joye, ya jenu ni o ka ‘lu lo.
153. A kii s’ore ero ka yo, ero o loo ‘ le e bo d’ ola.
154. A ti mo ‘wa eniyan, l’o soro.
155. A kii ba ni m’adie, k’a f’orunkun bo.
156. Afinju booni, ti nf’ekisa diiba.
157. Ase baje sebi t’oun l’a nwi, asebuburu, e ku ara fu.
158. Atiro m’ese ko le, ona jin.
159. A kii l’ahun niyi.
160. Abamo l’o ngbehin oran, gbogbo otokuhe pe won ko r’ebo abamo se.
161. A f’ase gbe ‘jo, o ntan ‘ra re je.
162. Aare npe o, o difa, bi ifa ba fo ‘re, ti aare ba fo ‘bi nko?
163. Apani ki fe ki a mu’da koja l’ori oun.
164. Ati jelede yungba – yingba, a ti san wo e tiketike.
165. Awon ara won ko sia ba ‘ra won ja.
166. Agbekele kii pa ni lebi.
167. Aba ni ‘kan nda, ikan ko lee m’okuta.
168. Agbalagba kii s’oro bi ewe.
169. Aisi owo, baba ijaya.
170. Aje ke l’ana, omo ku l’oni, taani ko mo pea je ana l’o p’ omo je?
171. A kii dagba s’ohun t’ao ba mo.
172. Adaba npe’de, o se b’eyele o gbo, eyele gbo kirikiri l’o kiri.
173. A ko ni so p’ ogbon tan l’aye, ki a wa lo s’orun.
174. Awo felele bo’nu, ko je k’a mo kun asebi.
175. A kii du ni l’oye, k’a f’ona ile bale han ni.
176. Aala ni yoo f’oko ole han.
177. Agba ti ko binu, l’omo re npo.
178. Alagbata ni nso ‘ja d’owon.
179. A gbe jo nikan da, agba o si ka.
180. A jii nise, ti nfeses je’ gboro.
181. Ai t’ehin ka, ni a nd’owo bo.
182. Anikan rin ejo, l’o nse ‘ku pa won.
183. Arire ba nije, agbon ‘sale b; eni ba ku l’aaro a ya l’ale.
184. A kii kere l’aaye eni, a kii tabi laaye alaaye.
185. A kii ba ni tan, k’a fa ni ni tan ya.
186. Alaini – kan – se, ti nfa ‘re aja.
187. Adie ba l’okun, ara o r’okun, ara o r’adie.
188. Ai l’owo l’owo, ko lee pa ni l’oruko da,
189. Ai lee ja, ni won ko bi mi ni ‘le yi.
190. Ai ra kun ogun pin.
191. A gb’owo ka l’ole, o difa baba asusan.
192. A kii m’ojo so l’okun.
193. A mu ni ko lu ni, alangba ori esu.
194. Akara tu epo.
195. Aye dun je ju ‘ya lo.
196. Ajanaku ko l’eekan, oba ti o merin so ko tii je.
197. A dun se bi ohun t’Olorun l’owo si, a soro se bi ohun t’Olorun ko l’owo si.
198. A kii f’ohun –olohun tore, bi ko se t’ eni.
199. Agbe ma ja kan ko si, ajaagbile nikan ni ko sunwon.
200. A ja ‘ra wa lo, ‘jakadi ko.
201. Ai f’akara mu’ko, kop e k a l’esin l’eekan.
202. Aye lo se’ la, t’ ila fi ko, aye lo se kan, to fi as’ ewu eje.
203. A ba ni l’obirin sun ko f’oju ire wo ni, imnoran ika ni t’ehinkule ngba.
204. Afefe ti fe, a ti ri idi adie.
205. Ao ri ‘bi sun, aja nhan ma je ‘kan.
206. A kii s’owo meji, k’eran ma je kan.
207. Ajeje, owo kan ko gb’eru d’ori.
208. A kii k’egbe inu te.
209. Agba aja kii ba ‘wo je.
210. Ajunmobi ko kan taanu.
211. Aaye l’a njo gun ore, b’ore ba ku tan, ogun re ko kan ni mo.
212. A o ri ‘hunf;ayo a fi ope.
213. Ajanaku koja mo ri nkan firi, bi a ba rerein, a a pe a rerin.
214. Alaseju ni np’ oke ni baba,
215. Ai duro ki won ni ‘le Ooni, aibere ki won ni ‘le Ooye.
216. Asa fo fee, awodi fo fee, rikisi ko je k’adie o fo.
217. Atari ajanaku, ki se eru omode.
218. A ni ki olokunrun o se to, o ni oun ko lee se tootoo.
219. A kii ran ‘mo ‘na, si ‘na.
220. A so ‘ro kele bojuwo ‘gbe, igbe kii soro, eniti a nba soro ni nro ni – a se buburu, e ku ara fu.
221. A di ‘kuta s’eru eru eni o fuye.
222. A ni k’a j’ekuru ko tan, e tun ngbon ‘wo re s’ awo.
223. A moni-seni, a faimoni se ni, a seni – bani – dar, ki Olorun gba wa lowo aye. Amin.
224. Arugbo s’oghe ri, akisa lo gba ri.
225. Aja kii gbo, k’ enu re o ya.
226. A kii ni ‘nu re, k a gba win ‘ka s’orun.
227. Asiwere eniyan l’ojo igboro npa.
228. Asiri nawo nawo kii tu, t omo ahun kii bo.
229. Ala kii ba ni l’eru, k’a ma lee ro, bob a ti r ni e wi.
230. Ahun kii mi ki eniyan o ma.
231. Agbele pin ope, ija lo nda sile.
232. Ara ko ro ‘wofa bi onigbowo, abani yawo l’ara nni.
233. A rii gbodo wi, ikun imu bale
234. Arokan l’o n m’ekun asun – da wa.
235. Ati gbe, ati to l’adie nya po.
236. Ayan fe jo, adie ni ko je.
237. Agbalagba t’o l’oun o t’ese b’ere, t’oju t’enu ni o yi.
238. A ju ehin, l’eegun nju so.
239. Aasiki agemo, asa ko lee gbe.
240. Aranbara ete nibi onje saraa.
241. Agba to w’ewu t;o koju resehin, bi o ti dara, o wa l’orun re.
242. Ajobi ko f’eke
243. Aroye ni ‘se .baaka, igbe kike ni se eye.
244. A kii b’adelebo leere ibi t’o ti gbe oyun wa.
245. Abere bo lowo adete, o d\egbe.
246. A ko gbodo so pe aye d’aye oyinbo, k’a maa f’oju egbo tele.
247. Agbalagba kii s’ohun ki lo ba ‘yi wa.
248. Agba kii soro bi ewe.
249. Agbalagba ko gbode se langba-langba.
250. Ara ode kii ma ni l’eru, ara ile l’o ntoka eni.
251. Ada-sini-lorun ibinrin odongo, t’eleru nwi eru, o ni ki won jeki oko oun t’oko de.
252. A kii r’omi ta ni koko.
253. Agbado inu igo, d’awomoju f’adie.
254. Arise l’arika, arika, baba iregun.
255. Adaba ko naani a nkun ‘gbe, igi da, eye oko fo lo.
256. A waye ma rere jo, o jo were tesetese; ko jo baba, ko joy a, o so ‘lu onilu d’ahoro.
257. Asiri eko, kii tu l’oju ewe.
258. A ja tuka nit u l’oju ewe.
259. Asinwin a maa sin win, ko ma mo’na.
260. Afefe yeye, ewe odan se ju bee lo, eran lo fi je.
261. Ai r’omo pe ranse ni nj’agba ni ya, ai reni jabo fun l’o ma ndun omode.
262. Ayipada nbe fun talika, olowo ni ko loo sora.
263. A kii binu ori, ka fi fila de’badi.
264. A nroju j’eko, obun, obun tun nda ‘ko re kere.
265. Arun t’ons’ obo ko tile se ‘gun, igun pa l’ori, obo pa nidi.
266. Adun lo ngbehin ewuro.
267. Adete ri were, o kan lu’gbe, nkan ju nkan lo.
268. A se’ ni, yoo se ‘ra re.
269. Ai tete ji, inun ota ndun, a ji tan, inu nbi won.
270. A kii dara ki a ma ku si ‘bikan.
271. Ara lile l’oogun oro.
272. A took rook, d’oko roboto.
273. A korira kii yo.
274. Agba l’etu, omo de l’awo.
275. A nju won ko see wi l’ejo, iya ilara ko tan boro.
276. Agba to roof ika, bo pw titi, omo re a je nibe.
277. A nlee bo lehin, o nl’ara iwaju.
278. A njoorin, a o m’ori olowo.
279. A ti gun l’a nko mo, a kii ko ni ati so.
280. Ai joni loju l’osan l’anjarunpa lu ni l’oru.
281. Aye la ba, aye l’a o fi si lo.
282. A s’otan s’osi, ma ba ‘bikan je.
283. A nke l’owo, o tun nb’oruka.
284. Asa ko lee wo, ‘le gb’eyele.
285. Agbalagba to nsoro t’o nlaa gun, ekun l’o nsun.
286. Adanikan gbero, ti nba ;ya re sun.
287. A kii m’oko omo, k’atun ma le mo.
288. Alaye ko k’ajo, ohun to ba da l; oo ko.
289. A kii ba ni rin, k’a ma mo ‘le eni.
290. Alejo l’owo, e toju e.
291. Afopina t’o l’ohun o pa fitila, ata re ni o pa.
292. Alaseju, pere ni nte.
293. Agba waa bura, b’ewe o se o ri.
294. A kii joko, l’oju eniti nwa nkan.
295. Aladugbo kii d’ola.
296. Adie ka ‘we, oyinbo ka ti.
297. A lee fi pa m’esin lo s’odo ko lee fi ‘pa mu m’omi.
298. Aye nlo, a nto.
299. A tapa fila li nbi ololaya ni, bi nu ba ti oko laya, kni ni yoo see?
300. Akuko ko, ole pose.
301. A de ‘bi eyin ma si, agba ole.
302. Asopa ni ibiti a ba l’eni si, l’a nko ‘di si.
303. Agba ni nba ni to ‘lu, omode ni ntun ‘le se.
304. Agborandun bi ‘ya ko si, iya l’alabaro omo.
305. Asare tete ko ni koja ile, arinrin gbere ni yoo oye dele.
306. Aje aye ko le p\omo aje orun je.
307. A fi joba, o nd’awure, se o fee j;olorun ni.
308. A wayee ku ko si, orun nikan l’aremabo.
309. Ajal, ta nna o, o ni eyin naa nuu.
310. Alagemo ti bi ‘mo re tan, aimaajo, d’owo re.
311. Aye nreti eleya, nibo l’e fi t; oluwa si?
312. Agba ko si, ilu baje, bale ile ku ile dahoro.
313. Ajanajku t’o sopa, inu oloode lo fi dun.
314. Ajangbala jugbu, jagun ni emu ko san wo.
315. Aja t’o ri ni t’ o nyoru, t; o ba ri ni t’ ngbo, ka kiyesara.
316. Ara nba da, owo ko je.
317. A bu ni bi e nla yin, a s’owo ete bi eni nta ‘ja.
318. A se gbe kan ko si, asepamo l’owa.
319. Ao fe o ni ‘lu, inda, rin, b’o bad a rin naa tan, tani yoo gbe?
320. A bu di ni t’odo.
321. Aso alaso l’oga nda bo ‘ra.
322. Adura ni ngba, agbara ko.
323. A too ku ma ku, a mo ‘na orun ma lo.
324. Abiyamo kii gb’ekun omo re, k’o ma ta ti were.
325. A sunkun ro ‘jo, ile ni ntu.
326. A mo’ran bi ni oyo, a gbagbe odo, o ni le nlo?
327. A gun ;baje ko l’odo, enu l’odo won.
328. A ke kaakaa k’oloro o gbo, b’ololoro ba gbo kin ni o se?
329. Agbo to ta di m’ehin, agbara lo lo mu wa.
330. A tete l’obinrin, ko k’omo bibi.
331. A mule ti ;gbo, l’o ngb ‘;hun eyekeye
332. A da ni tan ti dani tan, ki abanije too de, nigbati abanije de tan, o ba ni lowo atunise.
333. Aja lo l’eru, iro ni pepe npa.
334. A ni k’a diju, k’eni buburu o koja, eni rere maa si lee koja.
335. A yun lo, a yun bo, l’owo nyun erue.
336. A gbe juu le, l’omode ngbe gi eera.
337. Ai ridi okun, ai ridi osa, a kii ride omoru-gede-gede.
338. A ri gi to dara ni gbo, k’a too fi igi omo gbe lu.
339. A ko ri ru eleyi ri, eru la fi nda ba oloro.
340. Agbo meji, ko le m’omi ni koto.
341. Ara ile eni lo nmo l’amodi, were l’ara ‘ta o pe.
342. A dake ma fohun, ao ma t’eni to nse?
343. Apon ti ko l’obinrin a bebe oran, a ni jo o o, ba nda k obo.
344. A kii si wo lu mi.
345. Alagbado ko fi ‘idi tore.
346. Afinju wo ‘ja a rin gbendeke, obun wo’ja, a rin sio sio.
347. Adie da mi l’oogun nu, ma fo l’eyin?
348. Adie to su si koto, abuku ara re lo ta.
349. A kii fi tiju k’arun.
350. A kii r’ajeku oro.
351. Adie fa ‘ri, o d’obe.
352. Adie kii ku, k’a d’eyin re nu.
353. Adaniloro, f’agbara ko ni.
354. A kii korira atokun, k’a dugbo lu eegun.
355. Aja kii g, ti a so mo l’orun.
356. Asa wo ‘igbin koro, o sebi o see gbe, ikarahun, re nko.
357. Alawo a ku, onisegun a r’orun, iku a p’adahunse/
358. A ki fi ‘na s’ori orule sun!
359. Apani, kii je k’a mu’ da koja l’ori oun.
360. Awa yo, ni ndi ‘ja.
361. Atakoro wo nu ado, ko lee m’omo re wo.
362. A bi ‘mo ko gbon, a ni ko sa ma ku, ki l’o npa omo, bi kose ago?
363. A j’eyi t’toloko o lee je.
364. Akuko gaga, ko fe ki t’ abe re o ko.
365. Ago t’o gbon sasa, ebiti pa, aton bori olobiikoto rairai.
366. Ara mama ko ya, ara mama ko ya, beeni eko nwole, ewe njade – eni ara mama ko ya.
367. A ki ro ‘le apakan.
368. A kii belenu ji ‘ja oganjo.
369. Aimo mo, yo esinsin lo fi ku s’ori oti.
370. Agba ti ko ba fat i okere, omi obe ni o je.
371. Ail’apa l’ada o mu, agada owo see san ko.
372. Atelese ni nye na.
373. Alagbaa nlagbaa, oyin ti a nsa fun ni alangba nsa je.
374. Amodun ko jina, k’eni ma w’ebu sun je.
375. Adakeje kii l’oju aanu.
376. Awaari agan, lo nmu won daba abiku.
377. A fi fila p’erin, ojo kan l’o wuyi mo.
378. Akobani l’ekute ile, ejo nje igbado?
379. Ator l’aye, b’ o ba lo siwa, a tun lo sehin.
380. A ni ka pa se po, k’ a j’ iyan ‘ko, enikan l’oun lagba.
381. Afinju alapata, l’o nj edo eran.
382. Akera l’o nb’omo olowo je.
383. Ai l’awo lowo ni ebi ko si, bi a ba l’owo ttan, t’aja t;eran ni ma npe ni ni baba.
384. Agbon se, oloko se, oju oloko ni yi kulubu-kulubu?
385. A kii b’onisu wa de ;bi egun.
386. Agbe ko ni hun ta l’orun, k’owo ‘su re sat i pe.
387. A ni o je ko je, a ni o mu ko mu, o fi gba okele to be wo.
388. Agbe t’oko de, l’oun gbo royin kan,eye lo so fun ni, abi ajuba?
389. A ro ni l’ero, tin fun ni l’akoja.
390. Alatise l’o nm’ atise ara re.
391. Akitan kii ko ‘lekile.
392. Alejo loju ni, ko mo ran wo.
393. Ara kii wuwo, k’alars o msa lee gbe.
394. Ara la mo, ao mo ‘nu yin.
395. A joko t;agba, ma se pe ran.
396. Agba- wo ewu bi ko fun ni yoo so ni.
397. A ri gbo ma gbo, ti nte iku ya re sile to npe oua oloya.
398. A b’omi l’amu l’o nreegun, kin ni enit’oloopa yoo se?
399. Ara mee rii ri, a r’ori ologbo l’ate.
400. Aponle ni ‘ya kaa ko si ya ni kaa
401. Akanpo oko re ola.
402. A ri ma lee lo, a wo pada s’ehin.
403. A jebi ma mo, ‘l o nk’ ogun ja lu.
404. Alagbara ma m’ero, baba ole.
405. Aja t’o np’ekun, t’o npa agidan to’o ba pa lili enu re s se eje.
406. A waye ma te loruko, t;a np’ omi.
407. Aja kii ja ;mo, lehin ekun.
408. Ai t’omo ran nse ni t’o ba de, o wa gba nkan.
409. Aaya l’ohun ntoju omo ohun se, oju bad i pokita.
410. Aye l’ohun, eniyan l’osa.
411. A ji na ‘se, ni yoo jeun aji – gbb ni.
412. Ara o bale, olori arun.
413. Awodi gbomo die agbebo, agbebo mura ija, se yoo loo pade re loke ni.
414. Ajanaku foju ise wobo, obo ko toror je.
415. Ara re se ya gaga, bi ara akeko aso?
416. Ao da sile, ao tun sa, kii s’oro omo eleyin.
417. A kii je lehin mp yo.
418. Agemo t’o nrin keekeekee ku, atonbori opolo t’o njon ‘ra re mole.
419. A ji se bi Oyo l’a nri, Oyo kiise bi enikan.
420. Aja pada s’eebi re. Petru keji 2:22.
421. Atitebi, aya ni npa ni yan.
422. Asun kaaka, kii gbo fe.
423. Ayo a b’aara tin-tin.
424. Aro elese kn t;o nda ‘ron, orun elese l’o nda si.
425. A b’eleja yan.
426. Ada l’enu talika, igbo la o fi san.
427. A mo ni se ni, afai-mo-ni se ni, a se; ‘ru a ni daro. ki Olorun o gba wa ni
428. A j’egbodo w’eni rere kun ra.
429. Aso funfun, kii k’ohun aro.
430. A soro se, kii soro ta.
431. Apoti s’alakara kabiawo.
432. Awo ya.
433. Alagbara eniyan, lo nje onje orita.
434. A fe a je, ma fe a yo.
435. A ku tan l’oko, iro l’o nje be, eniyan lo waa so ni ‘le.
436. Aba –yo-mi, oluwa ni ko je.
437. Aroye ko san gbese, k’a kari bonu ko tan ‘soro.
438. Aseju ni ‘run aya, t’abe ti to.
439. Ajanaku sun bi oke, erin – lakatabu ku, ko le dide.
440. Apejuwe, l’agbede nro.
441. A wa ri l’obinrin nwa nkan obe.
442. Aaya gbo, ogungbe gbon, b’aaya ti nitro ni ogungbe nbere.
443. A kii w’aago alaago sise.
444. Agbalagba to w’ewu aseju, ete ni yoo fi ri.
445. A kii ko mi tan, k’a so pe nkan nrun.
446. A kii m’owo pe, ni sa akeeke.
447. Aparo ni ohun ko l’oogun, afara l’ohun ni, b’oloko ba ti nbere, ohun o fo – ifura l’oogun agba.
448. A m’oore su ni se.
449. Aja t’ o yo ki b’eyiti ko yo sere.
450. Aribi – ya – wo, ohun oloro, egbera.
451. Asin de, oorun de.
452. Aluwala t’ologinni nise, ogbon ati k’ eran je ni.
453. Aisan l’aa now, enikan ki wo ogba.
454. A kii gbe ‘le f’orun yin.
455. A pa ni ma yo ‘da.
456. A ba fi yi se wo, iwo je gba?
457. Akuku – bi, egbe agan.
458. A ra ‘so ogoje, a fi han egbefa eniyan, iyi ti tan lara aso.
459. A gb’ oleri won, ojonto.
460. A d’ogbon jale, omo alapata, o ni kanni janja.
461. Alangba t’o wo ‘le akan, rifaasi ni o ba jade.
462. Aifari kii s’obo ntulu, aijeun nikan l’eewo re.
463. Ara ija ni ehin wa.
464. A kii f’agbara ni ‘ko to ku.
465. Aye fa mi l’ete ntuto.
466. A s’esin mo’le, gogo re nyo nit a.
467. Agba ti ko j’ajewehin, ni o ru gba re de ‘le.
468. Agbga merin l’o nse ‘le, agba okunrin, agba obinrin, agba omode, agba alejo.
469. Akoda oro, ko dabi adagbehin.
470. A kii s’oore tan, k’a loso ti.
471. Aye l’o nso ‘gba d’ogbun.
472. Aye ni iro mo.
473. A kii s’ore oni sona, k’a ma l’ami aso l’ara.
474. Alakoba, ki salamo.
475. Afai mo ‘na, l’o nda pade pade.
476. Ade l’afi nmo oba.
477. A gba l’owo meeri.
478. Agba to nke ni kaa, tiko l’owo l’owo, ma da l’ohun, a ja ni ngbo, l’oruko re.
479. A toro obe ni n ma ‘ye a ko ‘la.
480. A kii ba yi’mi ‘ju ‘mi du ‘mi.
B
481. Bi owe, bi owe l’a nlulu ogididgbo, ologbon ni jo, omoran ni nmo.
482. B’o seere, o ban be.
483. Bi won ba nbu etu, ori a maa ro awo.
484. Bi ko ba ni idi, obinrin ki je kumolu.
485. Bi’ na ko ba r’oyin, eje ko le tan ni eekanna.
486. B’omode ba r’oyin, a s’akara nu.
487. B’omode ba nge ‘gi, agba ni yoo ma ‘bi t’o maa wo si.
488. B’oju owo ko ba yo ni, eni ko lee yo ni.
489. Bi a ba peri aja, ao peri aja, ao peri koko ti a fi se.
490. B’egungun ban le ni l’oko, patako ko gbodo l ni l’odo.
491. Bi a ba so ‘ko s’oja, ara ile eni ni nba.
492. B’a ba j’opolo, a j’eyi to l’eyin.
493. B’oju ba nse’pin, ao yo, a ho fi han oju.
494. B’a bar o bi eenu, yoo to aso hun.
495. Bi ere bi ere, alaborun d’ewu.
496. Bi’le njo, b’ole nja, eni ebi npa, a maa wi tire.
497. B’onile ba ni k’a k’a je tan, alejo a ni k’ aje ku.
498. B’a f’owo otun b’omo wi, a fi t;osi fa mo’ ra.
499. B’a bat a ara ile eni l’opo, a ko lee ri ra l’owon.
500. B’eniyan ba nyo, ‘le da, ohun buburu a maa yo se.
501. Bi ‘mu iwofa ti wu ko gun to, olowo re ni oga re.
502. B’oni ti ri, ola kii ri bee, l’o nmu babalawo di ‘fa oroorun.
503. Bi ‘na ko ba l’awo, ko lee g’oke odo.
504. B’ogiri ko ba la ‘nu, alaamu ko lee wo be.
505. B’ ao ku, ise ko tan.
506. B’ori pe ni ‘le, a di re.
507. B’o ti wu k’a p’eepo ose to, ara ni yoo fi san.
508. B’okete ba dagba tan, omu omo re nmu.
509. B’a ba wo didun ifon, ao ho ;ra de eegun.
510. Bayi l’a nse ni ‘le wa, ewo ‘bomiran,
511. B’a ba so pe omi ni yo s’eja jinn a, ao so pe ‘ro ni.
512. B’ ao ti se l’a nwai, enikan kii yan ana re l’odi.
513. B’eniyan ba f’odun meta pile waere, ojo wo ni yoo too bu ‘gi je?
514. B’aa gun ‘yan ninu eepo epa, ti a se ‘be ninu eepo egusi, eniti o yo, yoo yo.
515. Bintin ni mo fib a lagbaja tan, enikan ko le f’obe bu.
516. B’a ba ko ‘so fun awere, were o lo so gbo.
517. B’ao s’ode ri, a m’ese ko lo nihin.
518. Bi ‘le san, bi ko san, awo laa wo.
519. B’a ba nge gi ni gbo, a f’oro ro ‘ra eni wo.
520. Elulu ba k’oju, aala a maa to.
521. B’oju ba koju, aala a maa to.
522. B’a ti rin, l’a nko ni.
523. B’aladi ko ba si ni ‘le, omo ni njogun ebu.
524. B’eniyam ba pe l’ori imi, eesin keesein yoo ba nibe.
525. B’omode o ba te, agba kii ni yi.
526. B’omo ko jo sokoto, yoo jo kijipa, baba eni l’a njo.
527. B’owo ti mo, l’ogun o mo.
528. B’ori agbo ko ba wo koto, ao la si meji.
529. B’ewe ba pe l’ra ose, yoo d’ose.
530. B’obinrin o ba ko ni, ejo ni ro.
531. B[obinrin ko bag be ‘le oko meji, ko ni m’eyi t’o san.
532. B;a ba nsokun, a maa ri ran.
533. B’ode bar o ‘se to ro ‘ya, bob a p’eran, ko ni fe enikan je.
534. B’omode ba l’aso bi agba, ko lee l’akisa bi agba.
535. B’ao r’adan mo, a f’oobe s’ebo.
536. B’obinrin ba pa oko da, ti ko ba pa iuwa da, oosa tin se won ni ko tii sin l’ehin awon.
537. A’a ba fileke s’ahun l’orun, yoo ka ‘ri bo nu.
538. Bi ‘ya nlala ba ngbe ni ssan le, keekee a ma gori.
539. B’ ona kan ko ba di, okan kii la.
540. B’aa r’aye, l’a nje, b’ojo npa o, o maa to s’ara.
541. B’eye ba ti fo, l’a nso ‘ko.
542. B’I a tile f’owo so ‘wo elese ki yoo laai jiya. Owe 11:21.
543. B’o ti wa ni liki, l’o wa ni gbanja.
544. B’ ebiti ko p’eku mo, a f’eyin f’elegun.
545. Bi sobia, o ba degbo, olukanbi l’a nke si.
546. Ba mi na ‘mo ni, ko de ‘nu olomo.
547. B’eru o ba je’fun, edo ni nkoko beere.
548. B’olowo ba j’orogan, iwofa ko gboda j’ agunmote.
549. B’a peri aparo, a ja ‘ko.
550. Bi oru bi oru, l’o ns’eku inu agbe.
551. B’ ao gbekel’ akasu, a kii pa ‘ta s’efo.
552. B’eni ba ku, eru ni ku.
553. B’onile ba gba ‘yawo alejo, alejo ni o lo, b’alejo ba gba ‘yawo onile, alejo ni o lo.
554. B’ oju ba ye ‘ju, kohun ma ye ‘hun.
555. Binu ti ri, l’obi nyan.
556. B’a ni ‘ya l’a nhun, b’a bah un s’ eni, a gba ni ni gi lenu,
557. B’oore po a di ‘bi.
558. Bawo ni obo se s’ori, ti naki ko se?
559. B’erin ba je ti ko yo, igbe l’oju o ti.
560. B’omode ko ba m’owe, ti ko ni ewe, ao di swe s’owo otun, owe s’owo osi, ao si fi han.
561. Bi a ba ran mo ni se eru, a fi t’omo je.
562. Bi a fi o j’oye awodi, o ko lee gb’adie.
563. Bi ba ku l’a nd’ere, eniyan ko sunwon l’aaye.
564. Bi ao ba r’egbaa s’owo, bi ole l’a nri, b’ao r’eni gbekele, a tera ma ‘se eni.
565. Bi waju ko ba see lo, ehin yoo se pada si.
566. Nbibi l’a nbi ‘do wo, k’a to wo.
567. B’ebi ba kuro ninu ise, ise buse.
568. B’o ba d’ ale, ere l’a nf’omo ayo se.
569. Bamu bamu l’a yo, a ko mo ebi np’omo enikookan ko see ilu to dara.
570. Bi ‘igi ba wao lu ‘gi, t’oke re l’a nkoko gbe.
571. Bi a ko b gbagbe oro ana, ao ni r’eni ba sere mo.
572. B’eti ko ba gbo yinkin, inu kii baje.
573. B’a ba dagba, omode l’a fi nreje.
574. Bi ‘ku ‘le ko pa ni, t’ode ko lee pa ni.
575. B’olorun ko pa ni, oba ko lee pa ni.
576. B’a ti beru la b’omo.
577. B’omode ba gbon-gbon kuku, iya re a gbogbon sinsin. B’a ba f’omo w’omo, a o tori epo je su.
578. B’ a ba f’omo w’omo, ao lu omo pa
579. B’ao ba tori isu j’epo, a o tori epo je ‘su
580. B’ekute ba farabale, yoo je ninu awo ologbo.
581. B’eniyan ba paro, ti a ko ba ja, a nda ‘so asiri bo ni.
582. B’a ba f’ori ki, ao ma bere.
583. B’ao ba se bi elede l’ona ijebu, a ko lee se be Adegboro l’oja oba.
584. B’eniyan bar u nbu nbu, yoo ko ‘gbo.
585. B’o ba ja, ng o so, a maa ni koko.
586. B’ewon ba ja, ko lee pe mo.
587. B’orun ba wo eegun, yo f’ohun eniyan.
588. Bi ‘na ba jo ni, t’o j’omo eni, t’ara eni l’a ko nyanju na.
589. B’adie f’ese wa ‘le, ire l’o nwa.
590. B’ara ile eni ba l’enu , k’awa naa o si l’ese.
591. B’eniyan ba l’opo oogun, t’o ba leke, ko lee je.
592. B’ao ba lo ni ‘lu, ma ohun to nle ni.
593. B’o ba ti ye l’ouse, eku, yoo ye lowo ebiti.
594. B’eniyan ba ti fee to, ni kii je ko si ‘wa hu, beniyan ba ti fe mo, ni ki jek’o ma wa hu.
595. B’eni a nparo fun ko ba mo, eniti npa yoo mo.
596. Bi a ba tori igi gbodi, o ye ko suna fun ni je.
597. B’omi bad a ni, k’olorun ma jeki agbe o fo.
598. B’a ba f’agbo f’eegun, a jiee tokun – tokun.
599. B’a ba lee pa koriko bo ‘le orisa, a ko gbodo yo t’ara re.
600. B’oju ri, enu a dake.
601. B’omode ba subu, a wo iwaju, b’agba subu, a w;ehin wo.
602. Bi ‘nu ba se ‘gba, a ba si wo.
603. Bi ‘na ba wo ‘le, okunkun a parade.
604. Bi ‘se ba s’omo l’ogun odun, ti ko ba pa omo, yoo sin l’ehin omo.
605. B’eyi o se, omiran yoo se.
606. Bayi ni ng o se nkan mi, ko yipada.
607. B’omode o ku, a j’agbalagba lo.
608. B’oko ko jinn,m ila kii ko.
609. B’ale ba le, a f’omo ayo f’ayo.
610. B’eja ba sun, eja a maa f;eja je.
611. Bi a ba nja, bii k’a ku ko.
612. B’o pe b’oya, okoto iro yoo jadi.
613. B’o ti wu k’orun o mu to, sanmo dudu die yoo wa.
614. Bi nab a ku, a f’eeru bo ‘ju, b’ogede ba ku, a f’omo re ro po, omo eni lo n sin ni.
615. Bale le di meta, eru nba meji.
616. B’ewure ba b;oju w;ehin, a fepe p’ao fi d’aya.
617. B’o ba pa, b’;; ba, o bu l’ese.
618. B’o ba buru tan, iwo nikan ni o ku.
619. B’o ba o pa, b’oo ni ‘ka, soro , enu re k’a gbo.
620. B’oo ni ‘ka, boo ni ‘ka, soro enu re ka gbo.
621. Bi Sango np’araba, t’o nfa ‘roko ya, bii t’igi nla ko.
622. Bi ‘nu omo eranko ko ba baje, inu omo eniyan kii dun.
623. B’oju ba fara bale, a a ri mu.
624. B’a gba ‘le, bi a gba ‘ta, aata l’a ndari re ko.
625. B’ao ba ku l’ogun odun, baba enikan ko lee gbe wa sin.
626. B’o ba nle ‘ku si won, ti won ban le ‘jo si o, ore mi iyen o buru. Fi won l’Olorun l’owo.
627. B’agbalagba ba nsoro, t’o nlaagun, ekun l’; nsun.
628. B’a ba wo ti pela, ijo yoo baje, bi ko ba si pela, ijo ko lee dun.
629. B’a ba nsokun, a maa reran.
630. Babalawo a ku, onisegun a rorun, iku a p’adahunse.
631. B’eegun eni ba joo re, ori a y’atokun.
632. B’oba ti ri ni e wi, ala kii ba ni l’eru, k’a ma lee ro.
633. B’a o l’obinrin ai d’ooyo si, g’a ba d’ooyo si, eran eleran ni o fi je.
634. Bi ‘gbin fa, ikarahun a te le.
635. B’omode ba de ‘bi eru, o ba.
636. B’oko ro oku, b’o r’osa, a f’ori f’elebute.
637. B’oloje ri ni t’o roju, ma f’aije te.
638. B’a j;ewa tan, erin l’a nrin, bi a ba ji iyan tan, oorun l’o nkun ni.
639. B’apa ba kun tan, a maa to’ wa.
640. B’a o ba wi t’asaran f’asaran, asaran ko ni ye aran se.
641. B’a ba fa gburu, gburu o fa ‘gbo.
642. Bi ‘su eni bat a, aa d;owo bo ni.
643. Bi won ba npe gbe-gbe-gbe, ti o ko ba won gbe, won o gbe s’ehinkule re.
644. B’aye ba t’ori eni, iwa ibaje l’a nhu.
645. B’omode ti wu k’ o tete ji to, oko ni yoo ba kukute.
646. Bi mo ba ri eleeke eebu, kin ni n o se bu san, nigbati mo lee san pada nipa suru ti kii tan.
647. B’ara ile eni ban je kakoro buburu, ti a ko ba tete wi fun, here-huru re ko nig bonwo, awo ate.
648. Bi’le o dun, bi ‘gbe ni ;lu nri.
649. B’a b l’ogun eru, ti a ya ‘wofa ogbon, omo eni l’omo eni.
650. Bi fa ba fo ;re agunla, b’opele b f’oe aguntete, b’ori mi ba ti fo re, abuse –buse.
651. Bi ‘fa ba fo ‘re agunla, b, opele ba f;ore aguntete, b;ori mi ba ti fo re, abuse-buse.
652. B’owe ba j’owe eni, bi a ko ba lee fohun, eru ija l’o nb ani.
653. Bibi re, ko see f’owo ra.
654. B’ori kan ba sunwon, a ran gba.
655. Bi ‘le ngb’osika, timko gb’olooto, ohun rere a su’ ni se.
656. B’agbalagba ko ba ri bi joko, gbe ‘di a maa gb’omode.
657. Bi ‘na ba njo ‘le eru, ti a ko ba gba, a maa jo ile omo.
658. B’o ba l’aya, o se ka, b’o ba ranti iku Gaa, k’o sotito.
659. Bi ole ile ko ba si, t’ode kii ja.
660. Bi ‘le ko ba kn ‘le kii j’ajoran.
661. B’adie ba j’okuta, omi ni yoo fi su.
662. B’a gb’adie gori adie, iye ti o ye, ni o ye.
663. B’owo ko ba ka iroko, a ka egbo idi re.
664. B’omo o ba ba ‘tan, yoo ba ‘wigbo.
665. B’onisere ko ba firigba mo, eyiti o ti fun ko lee parun.
666. A’enu akata ba le ‘wo kii s;enu adie lao ti gbo.
667. B’a aja ba gb’egungun eran, a dodo bale, gbooro.
668. B’o ba ba se pe b’ona ofun se gbooro to lao se b;okele onigege yoo gbe iyan mi t’abo t’abo.
669. B’o r’owo mi, oo ri ‘imu mi.
670. Bi ko si aso, omo elomiran a bo ‘ra sile, a j’obo, omiran a jo ‘naki – bi koko, bi agbaarin.
671. B’a ba j’eko a dari j’ewe.
672. B’a bat a, nto laa to, b’ao ba to, eran din l’o nda.
673. B’ao ri ‘gun ao s’ebo, b’ ao rakal, ao s’ oogun.
674. B’a ba ta, nto laa to, bi ao ba to, eran din l’o nda.
675. B’alejo ba m’ejo re l’ebi, ko nip e l’ori ikunle.
676. B’ogun eni ba da ni l’oju, a ma nfi gba ri mi.
677. Bi gada ba ja, kinni wahala ni owo iba ri.
678. Bi ko si atanpako, bii kumo ni ni owo iba ri.
679. B’omode ba ko ‘yan ale, agba a fi tan ba le.
680. B’ao ba sunmo aatan, a ko le mo p’on run.
681. B’owo omode ko ba t’eeku ‘da, ko gboda beere ilu to pa baba re.
682. B’ogun ba je lo, ogbon a maa je bo.
683. Bi’ nab a jo l’oko, majala nii sofofo.
684. B’awo ti nlu, l’awo njo.
685. B’ao ba ran ni s’oja, oja ko lee ranse si ‘le, o difa fun gbada to mu agbagba lo s’oja, t;o fi ri ijo mu pada lo s’oko.
686. Baba jona, e nbeere ‘rungbon, ki lo mu ‘na jo?
687. Bi nkan ko ba se ese, ese kii se lasan.
688. B’a ba ni baba ngb’ejo, b’a ba ro’jo ebi, won o da wa l’are.
689. B’a ba p’ori akoni, a fi ‘da l’ale gaaraga.
690. B’olorun ba fun kain-kain l’agbara bi esin, atapa ni’ ba t’eniyan.
691. Bi gbogbo o ba ti je ni o je’ oloosa, taani yoo maa ke heepa?
692. Bi o ba ti je ni o je, elegbo a t’oko re ni o sun.
693. B’eniyan ko bad a so k’aso kii pe’kan l;akisa.
694. Baba t’o nke ni kaa ti ko l’owo l’owo aja ni ngbo, l’oruko re.
695. B’ ao ja, a kii re.
696. B’a f’ efun ko ‘le aje b’a f’osun ko le oosa, akoola oro, ko dabi adagbehin.
697. Bi abere, bi abere, l’a nse ‘ke, nigba t’ o ba t’ oko ro ni npa eleke.
698. B’eni ba je, oju o ti.
699. B’oro ba pe ni ‘le, a maa gbon si,
700. B’ase-je, obi tin so l’eerun.
701. Bi won mu mi, ma d’onile, bi won ba mu mu, maa d’ole.
702. B’eniyan ko ba l’owo, ko l’eenu, bi ko ba l’eenu ko l’oro rere l’enu.
703. Bi won ban tan e, o ma tan ‘ra re baba mogba.
704. Bi ‘di ba baje, tonidi ni o da.
705. Bi a ba pe ni ni ab’enu yan nyan, a si enu na mo.
706. B’olorun ba ti f’ota eni han ni, ko lee pa ni mo.
707. Bi ilu ba ti yi, ki ‘jo naa yi pada.
708. Ba’ nu so, ma b’eniyan so.
709. Bi a ba nbomode je ‘su l’oko, ganmu ganmu imu lo ma now ni.
710. B’owo ba ni k ‘a ma san ‘un a ka le ri.
711. Dida to da l’omo d’egbe, egbe kii se ‘le omo.
712. Da tooro, da tooro, da tooro, agba ti ko da tooro omu obe ni yoo je.
713. Dan-an wo, lo bi ‘ya okere.
714. Die die, ni mu elede now ‘gba.
715. Dagunro ko see je, bi e ba je tete, e ma je, dagunro, dakunro ko se je.
716. Didun lo dun l’a nb ore je ‘fo, ti ‘le oge to’ ge je.
717. Dindinrin kii ba ni l’agba, kekere lo ti nba nii lo.
718. Die die, ni ‘jo now ;ra.
719. Digbo l’egun, digbo l’egun, labalaba t;o ba digbo l’egun, aso re yo fa ya.
720. De daadaa, gee re, ipenpeju l’aala fila.
721. Die ni ti ;koti ninu eru iyawo.
722. Dandan l’owo ori, tulassi laso bora.
723. Die okunrin, ko to.
724. Dada ko lee ja, sugbon o l’ aburo t;o gboju.
725. Dandogo koja ewu abinu da.
726. Epo ni mo ru, oni yangi ma ba temi je.
727. Erin lo to ‘wo efan gba mu.
728. Eniyan lo nbe nidi oro l’oro nke.
729. Elo l’a nm’orunkun wundi, t’adelebo nr’arin wodi.
730. Eegun s’enu jeeje mu ti.
731. Eti ob anile, eti oba loko, eniyan l’o nje bee.
732. Eera ko fe poporo de ‘nu.
733. Eniyan ko fe k’a rere k’a so ori eni l’o nso ni.
734. Ere ori igi, aseku omo edun.
735. Ekute ile paramole, ologinni t’ajo de.
736. Eku t’o l’opo nle, kii t’are sa.
737. Ebi lo npa ni bakannaa, oro kii dun ni bakannaa.
738. Ewu ina kii pa ‘awodi, awodi o ku ewu.
739. E wu nbe l’oko longe, longe gan an, ewu.
740. Ero l’obe gbegiri, bi a ko bar o ko lee ki.
741. Epe kii jek’omo ole o dagba.
742. Eniyan ko fe ‘ni f’oro, a f’ori eni.
743. Eniyan buburu sa nigbti enikan ko le, sugbon olododo l’aya bi ki niun. Owe 28:1
744. Epe po j’ohun nyan, a t;ahun a t ejo eran jije.
745. E bi np’ejo, ahun nyan, a t’ahun, a t’ejo eran jije.
746. Eku t’o da iyi sile l’o nj’ eda.
747. Egbinrin ote, b’a tin pa kan, l’ okan nru.
748. Ewure nbinu, o nf’ese wa ‘le, yoo b’olowo re je bi?
749. Eeko ila, gba ‘ra re l’owo obe, yerepe gba’ra re, gba ‘gi oko.
750. Eedi kii mu omolangidi.
751. Eko akete, ilu ogbon.
752. Ewure kii bi ni, k’a ya so agutan.
753. Eniyan l’aso mi.
754. Eniyan die l’o nse ‘lu.
755. Erin kii fon, k’omo re o fon, fere tan mi ‘le ni.
756. Ero kii mo buso k’orun o wo.
757. Erigi laa mo, k’a to mo ehin.
758. Eni buburu b’eni rere je.
759. Esinsin t’onb’ode rin, yoo mu ‘je yo.
760. Ewure w’alapata bi ko ku!
761. Eni meji kii padanu iro, b’eru a npa fun bamo, eniti npa ro, yoo mo
762. Erin ku mongudu je, efan ku, mongudu je, mongudu naa wa ku, ko r’eniti yoo je ohun.
763. Ehin kn ni gbese ni, bi a ba ti ka, gbese tan.
764. Esuro padi da, o nl’ aja.
765. Eniyan tiiri l’ogun.
766. Eyi t’o wu mi, ko wu e, ni ko jeki omo-iya meji pa ‘wo po fe ‘binrin.
767. Eniyan ko ri bi sun, aja nhan – run?
768. Epe kii ja l’oojo.
769. Eniyan bi aparo l’aye nfe.
770. Ejika dun-ni, melo ni t’ejo?
771. Ewure meta egbeta, agutan mefa, egbefa, o ta nkan paali ra nkan, o t’ori gangan, o fi ra’so kijipa!
772. Erin ko lee j’;ko abe e.
773. Ewe l’o nbe l’ara isu, t a nbowo fun sun.
774. Emi a jeun ku f’omo mi, adaba jeun ku f’eyele, orofo jeun ku f’awoko, emi a jeun ku f’omo mi.
775. Eniyan buburu po, o jug be, eni rere waon, o j’oju lo.
776. Eefin ni wa.
777. Ewe nla, ko ni pada ru wewe.
778. Eleti pandi bi eti ‘kun.
779. Eti l’obinrin fi ngb’ohun oro.
780. Eegun ma jo, ode o dara.
781. Eegun fere kase nle, t’omo alagbaa yoo akara mu’ko.
782. Eepa npa ‘ra re, o l’ohun npa’ja, b’aja ba ku nko, nibo ni yoo lo.
783. Eniyan l’Adimu, Adimu ko l’o ni ra re.
784. Esu l’o ns’omo agutan, to duro wo kooko l’oju.
785. Ebi ni yoo ‘ko were l’ogbon.
786. Ebi kii wo nu, k’oro miran o wo.
787. Ere t’aja f’ogun odun sa, faaji ni f’esin.
788. Ebi npa mi, olose nt’ose, igbati nko we nu, ng o se we ‘de?
789. Ebi ni yoo pa lagba ku, imoran ota ni yen.
790. Eewo orisa, aja kii j’obi.
791. Ebi kii r’alaje loju.
792. Eniyan ko ni gogoogo, ko ma mo ‘le baba re.
793. Elete l’ete nye, elet ko pa l’oju eru, ehin eru l’a ngb’ imoran ika, b;oju ba k’oju, enu a ri deere – deere.
794. Ere l’obinrin nje, l’abo oja.
795. Eyin nbe l’enu nigbati obi gbo, ejika nbe l’ojo ewu kenke.
796. Eekan l’agba, t’o ba kan ni, kii yo’wo.
797. Ebi npa mi ko see fi fe wi.
798. Egungun meje, olele mefa, enit’o ba sun m alagbaa ni je.
799. Eera gb’ohun to ju.
800. Eyi-o-wu-a-wi, t’Oluwa ni yoo se.
801. Eniyan ko le mu se je, ko mu se je.
802. Ewure t’o wo ‘le, ti ko k’ago, o di mimu so, agutan t’o wo ‘le, ti ko k’ago, o di mimu so, ogo lehin asi were.
803. Eniyan lo nso ‘gba d’ogbun, igba o pile, gbun.
804. Eyin mu j’abe lo.
805. Esuke fo wo rara.
806. Eegun mo ni, eniyan ko mo.
807. Eku ibikan, eliri ibormiran.
808. Ejo to wo ‘le akan, rifaasi ni o ba jade.
809. Eji l’ore, ore ko gb’eleta.
810. Eniyan kukuru kii yin Olorun, o di gba t’o ri arara.
811. Ekuro l’o war a, omo-eran se de ‘gba?
812. Eemo lukutu pebe, iyawo l’oyun, ona o gb’oko.
813. Ehin eni l’a ngb’imoran ika, b’oju ba k’oju, enu a ri dere – deere.
E
814. Enito nlo se gbonse, t’o nja ‘we gbure nu’di, bop e titi, ewebe yoo beere.
815. Eni oju re o roran ri, e je o wi.
816. Enu o ma, mo je ri.
817. Eku ‘se ni nsaaju bun mi ni’su je.
818. Enit’o bi’mo oran ni yoo pon.
819. Enit’o ni owu ko t’eru, a je wipe eyiti yoo fi tan ina lo mu.
820. Eni ebi npa, ko gbo yago.
821. Egbin odo, kii pa ni.
822. Eerun lo, ojo nlo, eni k’a di sa eku pinpin?
823. Enit’o ma se okukun, k’o ma d’osupa l’oro.
824. Eni ti a ko fe ni ‘lere nijinna.
825. Eni ba l’oju, l’oju nti.
826. E ma gb’omo oba f’osun.
827. Emi oro gun j’emi eniyan lo.
828. Eni ba f’oju kekere w’okp, ibeji ni yoo fi bi.
829. Egbe eye l’eye now to.
830. Eso pele l’ejo ng’ agbon.
831. Eni bad a mi siwaju ni o te le tutu.
832. Eni a ni a ta k’a fi r’eenu, o l’ebu ohun k’odunrun.
833. Eniti o gb’awin akara, yoo gb’omo alakara jo.
834. Enikan kii ba yimi – yimi du’mi.
835. Eni t’o fun ni l’omo, pari oore.
836. E am f’oro ejo, k e fi we t’agbon.
837. Eni ba we ni njare oye.
838. Ela l’oro, b’ao ba ladi re, ko lee ye ni.
839. Eemeji l oju ahjeun – dun-ni npon,
840. Eniti ko fe t eni, aalo ko ran.
841. E ti ns’oku l’orun?
842. Eni gbogbo lo ye k’o dinwo aro, ko y’atoole.
843. Ebiti ko p’eera, ara ile eni l’o nse ni.
844. Eran to m’erun run, lo mu ki gbegiri o san.
845. Eniti o j’oyin ori apata, ko ni woe nu aake.
846. Eni a wai fun, oba je o gbo.
847. Eniti ko ya ni l’owo, ti ko ya ni l’aso kii pe ni l’arun gun.
848. Eni a ni o kin ni l’ehin f’egun s’owo, eni a ni o fe ni l’oju f’ata s’enu, nwi a ni ko wo’le de ne, lekun l’o ti gboin – gboin.
849. Ehinkule l’ota wa, ile l’aseni ngbe.
850. Eni a fe l’a mo, a ko m’eni to fe ni.
851. Eyele f’esin re ha para, o wa ns’eleya adie.
852. Enit’o lehin, ko l’agbado, eni l’agbado ko l’ehin.
853. Eni a ni o wa wo gobi, o ni kin ni yi gobi-gobi.
854. Ekun l’ana, enikan kii ri fin.
855. Eni ti ‘gbin fi b’orisa, orisa fi lo le.
856. Eni ba se nibi pepe, ye ko je nibi pepe.
857. Eyin le k’eranke l’ogbon, eyin t e de takute, t’e o fi yeepe si ….
858. Eko ni koko, ko ni koko, kii s’ejo alagbado.
859. Ejinna s’ejo t’ao be lori, iku ti o pa ni, aa jinn a si ni.
860. Eni egun gun, l’ese, ni nse lakalaka to alabe le.
861. Enit’o nw’ori ahun, t’o nw’ese ahun, odidi ahun ni ora.
862. Enit’o nje esuru ko mo yi, o d’eniti nr’owo re bi o se nlo s’enu.
863. Eni a fe ‘ya re l’omo re nwu ni.
864. Eni ara re ba wu, l’o ntan na ale.
865. Eni a ko ni’ka t’o gba, ni tinu re se ni.
866. Eni a se l’oore ti ko dupe, dabi olosa ko ni l’eru lo.
867. Erukan ni nmu ni bu’gba eru.
868. Eni m’yide olunnagun, ni yoo m’atile re.
869. Eni gbe ‘su l’aja ko jale, bi enito gba fun.
870. Eni gbe oku aparo, gb’aapon.
871. Eni aa-mori ibaa ku, Amori gan an nko?
872. Eni gb’adie otosi, gbe t’alaroye.
873. Eni koko re ye, lo maa lo.
874. Eye to ba f’ara we ‘gun, ehin aaro ni o sun.
875. Eni be ‘Ge Adubi nse, ara re lo be; Adubi ko ni je beeru ko ni ko.
876. Esin ‘waju ni t’ehin now sare.
877. Eran ti ko ba moju ode, ehin aaro ni o sun.
878. Eo ba mi b’ole wi, eni ;biti mo fi nkan mi si ko dara.
879. Eni sango t’oju re wole, ko ni b’oya l’eke.
880. Eran ile (ewure) ko mo ‘yi ode.
881. Eniti o s’owo ogun, aja re ni o ra.
882. Eyin l’ohun, bob a bo sile, ko see ko.
883. Eko gbigbona nfe suuru.
884. Eniti ko l’ehin oke, t o l’oun fee je’pa, erin pa mi titi.
885. Egan ko pe k’oyin ma dun.
886. Eni o mi kukute, ara re lo mi.
887. Eniti ko ba mo’nu ro, ko ni m’ope du.
888. Emi abata ni nm’odo san, ola baba ni nm’omo yan.
889. Eni a nbo ko mo pe yan mu.
890. Eni a tori e pa die, iwe ni je.
891. Eye kii fo, ko f’ori so gi.
892. Eemeji l’oti awin npa ni.
893. Eni beere oro, l’o fe ‘di ree gbo.
894. Eni nwa ‘fa, nw’ofo.
895. Eni ba f ori ko ‘le agbon, l’agbon nta.
896. Eniti o fun ni l’ewu wo, t’orun re l’ao wo.
897. Eni ba ju ni lo lee ju ni nu.
898. Eni to ju ni lo, l’of’owo ila pa ni lori.
899. Eni ba dupe oore ana, yoo r’omiran gba.
900. Enu fifo, kii dun yanmu – yanmu.
901. Enit’ o so pe ara ile aoun ma la, ara ode l’o nya l’ofa.
902. Eni s;ohun to dun ni loni, lee s’ohun to dun mo ni l’ola.
903. E je ki a ta keekeeke, bi ofa imodo.
904. Eda ko l’aropin.
905. Eye mejim kii j’asa.
906. E je ki a ti bi pelebe m’oole je.
907. Eku ijeta, ko dun bi e ku ana.
908. Eni aro re ba jade l’a nre.
909. Eni a ni a ta, k’a fi r’atupa, o ni oun ajitan nawo l’oru.
910. Eja kii ja, kop e mo.
911. Eni ngbe ‘yawo bow a ba, kii gb’ori ganna woran.
912. Ete awo erin ogberi ni.
913. Eniti ko ba l’oogun irin do ko gbodo j’aayan.
914. Epon agbo nmi ni, ko nii ja.
915. Eniti ko ki ni kabo, padanu kule.
916. Eni moo-rin, iyan nii ba.
917. Esin kii ko ‘re-asaloo-le.
918. Eniti ogun ya l’ogbon, ri lo lee rohin ogun.
919. Eniti ko yelomo se, kii p’alakara.
920. Eni a ni o waa je saraa, t’o ni ojo wonu, kinni ona?
921. Enikan kii je, ki’le o fe.
922. Eni toro obe, ni nma ;ye a ko ‘la.
923. Enikan ni nbi ‘mo, igba eniyan ni now.
924. Eni a ba l’aba ni baba, eni a ba niwaju ni baba.
925. Eni ay nfe, kii l’abuku kan l’ara.
926. Eni a fee sun je tele, t’o fepo pa ra, t’o duro sehin aaro?
927. Erin l’agbara nrin pade odo.
928. Elemu ndo gbon, alaaru ndete, enito’ra l’awin nw’oju.
929. Eni a ba mo, kii ru’mo.
930. Eni aba ninu ijo, kuro ni s’ara le.
931. Enikan ki j’awa de, opo eniyan, l’o nje jan moo.
932. Enu bale ko lee gba, pew ki oku kan o ku, ko so pe, e d’aso bo ki a maa jeun lo.
933. Eni ba d’oti mu, yoo mda were se.
934. Eni ba r’oyun Filani, ti mo pe, pupa ni yoo bi.
935. Eni a d’ebo fun, t’o nyo ‘wo malu, ko ni sanwo ebo.
936. Eran ku ‘lu ailobe.
937. Ehinkule l’ota wa, ile l’aseni ngbe.
938. Enit’o se fun ‘na. ko lo se f’oorun.
939. Eni ba sun l’a nji, a kii ji apiroror.
940. Eleko ana, ko lo ro l’oni.
941. Eni ba jin si koto, ko ara iyoku l’ogbon.
942. Eko t’o ni ewe, agba ni nje.
943. Eniti yoo ga, ese re yoo tinrin.
944. Eni ba s’ohun etufu, ko kiyes ehinkule, asebuburu, e ku ara fu.
945. E mase f’eku kan re’mo meji.
946. Eniti ifa ko si, l’o npe ni haramu.
947. Enu opuro kii s’eje.
948. Ejo kii s’ejo eni, k’a ma mo ‘da e.
949. Ejo l’a nko, a kii ko ‘ja.
950. Enit’o gbin ‘gba oka, t’o ni egberun l’ohun gbin nigbat’o baje igba otito tan, a seku egberun iro.
951. Eni a fori e f’agbon, ko ni duro je nibe.
952. Eda nlulu ibaje, Olorun oba ni ko ni jeki o dun.
953. Eni mi o s’eni, eniyan mi o s’eniyan, ao ni fi we alaroo-lasan.
954. Ejeki a se bi won tin se, ko lee ri b’o ti ye k’o ri.
955. Enit’o bad a ‘le, yoo ba ‘le lo.
956. Egbe buburu, ba iwa rere je. Korinti kinni 15:33.
957. Eni f’arugbo kehin, ni yoo sinku arugbo.
958. Eyin l’e ni k’ole o ja, eyin l’e ni, k’oloko o so ‘ko .
959. Eni apa ka l’a nle ‘di mo.
960. Esan ko gb’oogun.
961. Enu t’araye fi np’adegun, ni won fi np’Ade-o-ogun.
962. Eekinni, keebe, eekeji keebe, eleeketa l’aje-nje-tan.
963. Eniti’o yo, ko ma yo, eni ebi npa, k’o ma baraje.
964. Eni a f’oro lo, t’o ni t’ohun baje, kin oloro o se?
965. Eniti ko ri bi ahun, o nw’ewu abona.
966. Eniti ngbe ‘le l’o np’oku mo eniti nsokun, ariwo lasan l’o npa.
967. Eni Olorun ko pa, oba ko lea pa.
968. Eniti ko tii ku, l’o ni oko oke ati ti ‘sale.
969. Eni nwa wahala ti ko ri, k’o o wo ‘ku moto ko ra ‘kan.
970. Eni oro ku le lori, ko see ba sire mo.
971. Eni eegun nle lo, k’o maa roju, b’o ti nr’eniyan, l’o nr’araorun.
972. Eni a now l’awosunkun, t’o now ra e l’aworerin.
973. Eni bad a ‘ye je, yoo da ‘ya je.
974. Enit’o tafa soke, to yi ‘do bo ‘ri b’ oba aye ko ri, t’orun now.
975. Enit’ o gbo’ fa ko m’offa, enit’ o m’offa, ka gbo fa, beeni ifa ta l’offa.
976. Eru ko b’ode, eniti o wo ‘do, l’ominu nko.
977. Eemeta l’omode ntan ‘na ale.
978. Eniti o wo ‘seju akan, yoo pe l’eti omi.
979. E je ki a mo ‘wa ara wa, ki a ma baa se ra wa.
980. Elejo kan ro, a so ‘pa nu, bi ti enikeji ba wi tire nko?
981. Enu agba l’obi ngbo.
982. Enu kii ka afedii-le.
983. Eni ba f’agba a da, ko tun ‘waju se.
984. Ahin ito, l’a ngbon ‘ko.
985. Eleru ni ngbe nibit’ o wuwo.
986. Enit’o ran ni nse l’a nberu, a ki beru eniti ao je fun.
987. Ahun l’o ndun aoloku ada si.
988. Enu dun ro fo, agada owo see san ‘ko.
989. Eni a s’aser fun ko loyun, eni too wo bi’beji.
990. Eni Olorun ko pa, ko nii ku.
991. Esin kii da ni, ki a ma tun gun.
992. Eda to m’ola, ko si.
993. Enu ki sin lara afo-keemu.
994. Eniti ko r’eni pe, kii daa ku.
995. Enit’o gbon, to l’enikan ko mgbon, oun ni baba were.
996. Eniti ko ni ‘ya, kii d’egbo ehin.
997. Enit’o f’oyinbo ni ‘le ana, yoo tumo re.
998. Eni a nba na ‘ja, l’a now, a kii w’ariwo oja.
999. Eni ba m;ojo owo, o m’ ojo iku.
1000.Eni f’ori jona, yoo gb’oorun ara re.
1001.E jeki a le eleyoro jinna, I a too b’adie wi.
1002.Enu oforo ni o p’oforo, orofo t’o bimo mefa, t’o ni ‘le ohun kun tete.
1003.Enu ko sunwon, elenu pon la.
1004.E ma fi agbalagba se yeye, tori a ti sun.
1005.Eni ba le ‘ku meji, yoo p’ofo.
1006.Eni a ri, l’a nmo l’oju.
1007.Eniti a ya l’egbefa ti ko san, pa ‘ko dina egbeje.
1008.Eniti nya ‘gbe ayao l’o nyo, o d’enit’o d’aatan ti ko ri mi su.
1009.Eni d’eerie l’eeru nto elete, l’ete nye, ohun ti a ba se l’o nye ni.
1010.Eni ba gba ‘le ni le, nmo fun.
1011.Eni a ntori e gba aawe, t o nj’osan.
1012.Eniti ko ni ‘yawo, ana re kii ku.
1013.Ebe l’a nbe ‘ka, ko ma ba ohun t’o dara je.
1014.Eniti ko ni ‘mi je, ko gbodo l’aja l’aatan.
1015.E mase f;oju oloore gun gi.
1016.Ese giri nibi a nj’ofe, ofe lo tan ese da.
1017.E jawo ninu aapon ti ko yo, e gb’ omi ila ka ‘na.
1018.Elulu ni kaka k’ohun o ma dun ‘be, t’apa ti ‘tan l’ohun o run sibe.
1019.Eni ba ku ni ku, l’a nba j’aye.
1020.Eni mo bi oro o subu si l’ota oloro.
1021.Eni ri nkan he, t;o fe ku pelu e, owo eniti o ti sonu nko?
1022.Enit’ o go, k’o ma binum enito gbon ni yoo ko.
1023.Enit’o mo ni, l’o ma binu eni a binu bi nda ni.
1024.Eni ore da, k’o ma binu, eni a binu nda ni.
1025.Eru ku, iya ko gbo, omo ku, ariwo ta.
1026.Ejeki a t’enu isa pin eku.
1027.Esin ti were o se, ni ko jeki o ku ni kekere.
1028.Enit’o f’awo agility s’oogun aiku, bi agility ko ba ku, se yoo ri awo re s’ oogun?
1029.Elese yoo sa, nigbti enikan ko le, sugbon olododo yoo laya bi kinnin. Owe 28:1.
1030.Eni ba ya’wo l’ogun ngbe.
1031.Eni a laa jo, nju l’a nju.
1032.Eru inu, l’a fi ngbe t’ode.
1033.Emi gigun l’o nsan’ya.
1034.Enit’o sunkun si fi pamo ni, bi ko ba wa ni kelebe, yoo wa ni ‘kun.
1035.E ma fote ba ‘hun to dara je.
1036.Eyin l’e soro t’eo se bee ma, ajangoloto yin.
1037.Eniti a se, ti ko dariji ni, bob a fun ni l’obi, k’a ma ma je.
1038.Eti r’oju ekun si, k’e to p’eran ki lo pa?
1039.Eni ba fe jeun gboin-gboin, yoo tilelun gboin-gboin.
1040.Eni ba moyi wura l’a nta fun.
1041.Enit’o l’ana, to l’oni ko lee ni ola, Olorun nikan lo l’ojo gbogbo.
1042.Eniti ko si ‘le, l’ewure re nbi ikan.
1043. Emo ku, oju nopo di.
1044.Eniti ko ba moo jo, kii jinna s’onilu.
1045.Elenu rerun, l’amu iya re.
1046.Eni oran o ba, ni npe ‘ra re l’okunrin.
1047.Eniti ko ba sunmo aatan, ko le ma p’on run.
1048.Enikan kii bimo, ko so ni bale, kikan l’o nkan ‘niyan.
1049.Eniti ao ta l’aa bo.
1050.Eni ba ta’ja yeepe yoo gb’oeo okuta.
1051.Enit’o bere t’o now’sa okete, ko ranti p’enikan now furo oun.
1052.Eranko t’o ba siyemeji l’ode npa.
1053.Eru osan ni won nab, ko s’ohun ti won ko lee f’oru se,
1054.Enu ni ‘fa wa.
1055.Eni ba ko ;le ‘mo, ko lee nikan gbe be.
1056.Ekun ku, a f’owo ba.
1057.Ewa ni np’okin iku ara re rire l’o np’ odidere.
1058.Eru ku, owo gbe.
1059.Ebo lile kan, ko ju ‘ku lo.
1060.Eleeda npeede npeede, o l’eedegbeta, nibo l’o ma o pari eede re si?
1061.E korira ofan, e ti’na bo ‘le ofan, ile o si jona.
1062.E ma fi ‘gba kan bo ‘kan nnu.
1063.Eni ojo pa ti sango o pa, k’o maa dupe.
1064.E ja ‘we bo ‘mi, ki a lee jeun yo?
1065.Faari aseju, oko olowo (eru) l’o nmu won lo,
1066.Foni ni adie nbo oko eemo.
1067.Fi ‘ja f’Olorun ja, f’owo leran.
1068.Falan gbo tire, t’ara eni l’a ngbo.
1069.Fofo-foofo’ mu yawo ya ju, yara fifo lo.
1070.Firi ndi, oke, a lo k’olohun kigbe.
1071.F’oro lo mi nda si, ojugun leta eti.
1072.F’eso jaye, b’aye ba ja, ko see se.
1073.Fere – ku – fe, eru la fi nda ba ‘ra wa.
1074.Fila ete, fila abuku! Omoluabi kii de.
1075.Fin ni fin ni aseju, ajisefinni fee te nuu.
1076.Gan-nkan-je, gan nnkan –je, nka l’ao fi s’awo, k’a to wipe ki won maa gan – nkan – je.
1077.Gaari olooye, o ti l’adehin agbere ni suga. Ngbe.
1078.Gele ko dun, bi k’a maa we, fila ko dun bi k’a maa de, k’a maa de ko dun bii pe k’o ye ni.
1079.Gaani-ya-fii-ji, irohin kom t’afojuba.
1080.Gun un gun kii ku l’ewe, dandan, a fa sai darugbo.
1081.Giripa ko si lekun, enito ba ni kokoro l’o nsi.
1082.Gan-ni-ke tori ookan kungbe, o ni ‘bi t’o bo si ni ko t’ohun l’orun.
1083. Gogo so.
1084.Gbe koto ota re ma ni won, k’o ma baa je wipe iwo gan an l’o jin sibe.
1085.Gbogbo aso ko ni a nsa l’Orun.
1086.Gbogbo eniyan ni ole, ati ile bad a.
1087.Gbe jee ki I niyi arami, tete kii te l’awujo efo.
1088.Gbogbo aye l’o nb’odun s’owo.
1089.Gba mu, ko ran ‘ba.
1090.Gbangba d’ekun, kedere be wo.
1091.Gbede-gbegbede bi ogun iya, Kankan bi ogun baba.
1092.Gb’omo waa ki mi, owo ‘o nna ni.
1093.Gbingbin la gbin ‘gede, lilo l’a lo ‘reke.
1094.Gbajumo, kii wa nkan ti.
1095.Gbese ko pa ni, bi ojo owo.
1096.Gba ran mi, se lee di t’eleru?
1097.Gbogbo wa ko gbodo sun k’a ko ‘ri si bikan naa.
1098.Gbogbo alaamu lo dobola, a ko m’eyi ti nu nrun.
1099.Gbogbo orin l’aranmu ko lee ko, sugbon b’o ba di san-saa-lubo, a ni pon-ran-pon.
1100.Gbon-gbon kan ko si, a f’eniti o te gbese.
1101.Gbogbo ohun t’ondan, ko ni wura.
1102.Gbanko ko ni won fi nbe ‘lubo, enit’o ni ‘su ni nbe.
1103.Gb’omo nle ng o te nkan, a f’eniti o te gbese.
1104.Gbogbo ohun t’oju ba ri, ko ni enu nso.
1105.Gbogbo ika lo f’oju de s’ookan, atanpako nikan l’o ya tire s’oto.
1106.Gbo-gbo-gbo, l’owo nyo j’ori.
1107.Gba mi l’ojo ki ngba o k’eerun.
1108.Gb’oyun lo, k’o gb’omo bo.
1109.Honti-honti ko m’eyin, b’eyin ba se meji, ko sa funfun.
1110.Ile ni o p’osika, eke ni np’eru.
1111.Iku wa ajoku, aawe wa ajo gba.
1112.Iya nbe f’omo ti ko gbon, ekun nbe f’omo t’o nsa kiri.
1113.Itakun t’o ni k’erinb ma f’odo, t’ohun t’erin lo nlo.
1114.Ise t’o se’mo l’ogun odun, iya t’o jomo l’ogbon osu, bi ko ba pa omo, yoo sin lehin omo.
1115.Iwo t’a nw’aparo bi k’a fi da ‘la, or eye ni ko p’eye.
1116.Iyan buru, a f’aja.
1117.Isoro ni gbesi, isunkunsi nig be ‘te gan-ngan.
1118.Iromi t’o njo, onilu re nbe ni ‘sale.
1119.Ile eni l’a ti nj’ okete inidodo.
1120.Ile oba t’o jo, ewa l’o bukun.
1121.Ibiti oka ba sun si, l’onje re yoo ti wa ba
1122.Igi ta fi se oori, ti o fi d’oyin, ile we.
1123.Ile l’a now k’a to so’mo l’oruko.
1124.Ina dile lehin asun –su – je.
1125.Arorun igi, ni ‘rorun eye.
1126.Igi gangan ran, ma gun ni l’oju, okeere l’a tin so.
1127.Ironu ikoko ni o p’aja, kinni ng o je sun ni o p’ole.
1128.Ika t’o ba to si ‘mu, l’a fin re’mu.
1129.Ipako onipako l’a nri, eni – eleni l’o nri t’eni.
1130.Ijo nbe l’ara aro, ese nim ko je.
1131.Ile olonje, l’a nd ebiti aya si.
1132.Irun mu l’owo, ko see fa tu.
1133.Ipako ko gbo suti.
1134.Ise ko gb’ekun, ebi jare ole.
1135.Iso inu eku, ara-mora ni.
1136.Ijo tiu alabahun ti jagbon hoo, ni orun ko ti wo ma.
1137.Igbehin l’alayo nta.
1138.Ila ko l’oogun, emu l’oogun ila.
1139.Iku ogun l’o np’ akinkanju, iku odo lo npa omuwe, owo t’ada ba mo l’o t’arugbo nko ‘gba?
1140.Igba yii laaro, t’arugbo nko ‘gba?
1141.Ileke ma ja si’le ma ja si ‘ta, ibikan saa nil eke maa ja si.
1142.Ibiti a f’oju si, ona ko gba ‘be lo.
1143.Ina d;ori koko pin, ona d’ori apata poruru, oosa je nla, ma je nku oosa ma je nku, je nla.
1144.Igi kii da l’oko ko p’ara ile, ona kii jin, ko p’ero ona.
1145.Ibiti a wi si, ko ni a nku si.
1146.Ijanja ni, kii s’ara eran.
1147.Idowu ko lee ja, sugbon o l’aburo to gboju.
1148.Ikun nj’epa, ikun nre’di ikun ko mo pe, ohun t;o dun ni npa ni.
1149.Iwi ni wi onile, ifo ni fo alejo, b’onile ba ni k’a je tan, alejo a ni k’a a je ku.
1150.Ile ti ko t’oju eni su, ookun re soro rin.
1151.Inu l’oke eye ngbe.
1152.Iya kii s’omi obe, baba ma je a jiya.
1153.Ijesa ko rii idi ‘sana, ile l’omo eru wa tin mu ;na r’oko.
1154.Iku m’eja kako.
1155.Isu atenu moran kii jona.
1156.Ihale agbe t’o ru ‘do yan wo ‘lu.
1157.Ikekere merindinlogun l’o nbe l’oju, b’ okan ba ye nibe, ologbon yoo ma.
1158.Ina ile, l’omo eranko yoo ya ybehin.
1159.Ibit’a w’efufuf lele lo ndari igbe si, ibit’o w’ olowo eru, lo nran ni lo.
1160.Ipe kinni a fee se, f’eniti kooko pa ya re je?
1161.Ile lo p’ewura da, ko to di ‘su buruku.
1162.Itoo to hu, to ko f’ara ti ‘igi. Efufu lele ni o gbe lo.
1163.Iro l’a npa m’ebu sun je (Ta – nran – o – pe?)
1164.Irawe kii da jo ‘le, k’o sun ‘na.
1165.Imode iba si be elede, a ba ‘lu, eru iba joba, eniyan iba ti kan’kan.
1166.Ibaje eniyan, ko da’ se oluwa duro.
1167.Iyan l’onje, oka l’oogun, airi – rara l’a nj’eko k’enu ma dile ni ti guguru.
1168.Iko kan kii k’ejo l’ese.
1169.Igbin kii r’ajo, ko fi ‘le re sile.
1170.Idobale kii se ‘wa, ohun a je lee wa.
1171.Ika t;o ba se, l’oba nge.
1172.Igbe kinkinni l’ati awo gbegiri, b’oju ba kuro nibe, okan ko le kuro nibe.
1173.Ibiti agba ba wa, l’omode o ba.
1174.Ibi gbogbo ni ngba alagbara, ole nikan l’ona ko si fun.
1175.Ija l’ode, l’orin d’owe.
1176.Ife ti a f’adie, ko de’nu, enu k’a ri pa je ni.
1177.Ikanju, ohun pele, gboogbogba ni, obun ohun asiwere deed ni won rii.
1178.Ibiti a n lo ko jinna, ibiti a nya lo po.
1179.Igba ko to lo bi orere, aye ko to lo bi opa ibaon.
1180.Igba iponju l’a nm’ore.
1181.Ibit;o ba le, l’a nb’okunrin.
1182.Iso kin-nkin l’o ba di je.
1183.Ilu eko, a r’omi sa legbe-legbe.
1184.Iwofa l’enu, ibit’ o ba w’olowo e, lo lee ran lo.
1185.Iku t’o np’ ojugba eni, owe l’o npa fun ni.
1186.Ile aanu Oluwa, kii su.
1187.Ibi ng o pa o wa, ibne ni ng o gba o wa.
1188.Ida ni yoo pe ‘ra re l’eru.
1189.Ikoko ti yoo j’ata, idi re a gbona.
1190.Iya ko to ‘ya, a s’ada si kun, ikun lo, ada si lo.
1191.Igi woroko l’o nda’ na ru, omo buruku l’o nba ‘le je.
1192.Isale oro l’egbin.
1193.Ekoko ti o nse eyin, eyin ni a fo.
1194.Iju re kii pa ni, wahala ni nko ba ni.
1195.Inu nb’eure, o n fese waa ‘le, yoo b’olowo e je bi?
1196.Ibi ori da si ni a ngbe.
1197.Isibmi ko si, f’eni t’o gb’odo mi.
1198.Iyan odun meta, a maa jo ni lowa.
1199.Iyawo ti a fe ni osu aga, t’o nfi, iyan mo le, yoo ban be l’omo re nje.
1200.Ibiti a ba b’alapinni ni ;bbale re.
1201.Ireti pipe s’okan l’asisan.
1202.Ibiti a gb’epo si, a kii so oko si ‘be
1203.Ibon l’apati, ko l’apati, taani je je ki a koju re s’oun?
1204.Ibiti a ba pe l’ori, enikan kii fi so le.
1205.Ile ni gba ‘wuyo njoko d’awo, ile ni iboye nbo si.
1206.Ile ajubnmogba, itale l’o nsin.
1207.Iya ko d’ola, oruko l’ n so ni.
1208.Isu eni, l’onmu ni t’owo bo pe.
1209.Ipa ti a p’awo, a kii pa ogberi re bee.
1210.Igi t’o to, kii pe ni’gbo.
1211.Iji kii ja, ko d’omi ‘nu agbon nu.
1212.Iya die, die l’o n je okugbe.
1213.Isoro ni gbesi isunkunsi nig be ‘te gan ngan.
1214.Ireje ni nf’ egbe ko si b’obo se s’ori, ti naki ko se.
1215.Ibinu ko ma polowo ohun ko l’ese nle.
1216.Ika ni ko je k’omo paramole o dagba.
1217.Iku pa babalawo bi eni ti ko ni ‘fa, iku p’onisegun bi eeni pe ko l’enikan, iku pa’Alufaa bi eniti ko l’Olorun
1218.Igba l’onigba nk, igba kan ka ‘lo le aye gbo.
1219.Igba ara l’a nbu ra, enikan kii bu sango l’eerun.
1220.Ina eesi kii jo ni l’eemeji.
1221.Idikudi l’a n d’eru ikun, ka s’olopa ti out.
1222.Iba s’emi, iba se wo, ni kii jek’a su s’oko alairoju.
1223.Ile ni abo sin mi oko.
1224.Ile kii su, ki onimi ma ma’nu.
1225.Ibiti ojo ba b’ojo l’o npa si.
1226.Itadogun ku si dede, ojo elesin k’ola.
1227.Ijafara l’ewu.
1228.Iwajowa l’o nj’ore jo’re, sugbon mo’wa f’oniwa ni o.
1229.Ile ti ntoro, omo –ale ibe ni ko tii dagba,
1230.Ijo ti ao jo t’ao fi niyi, koro yara ni ati nbere.
1231.Iwon eku ni iwon ite.
1232.Ibiti a ba f’Elemoso so, ni nso.
1233.Ilesanmi dun j’oye lo.
1234.Ise-se l’oku pe l’oorun.
1235.Ijamba s’ole, onile ta ji.
1236.Igba kan lo, igba kan bo, aye duro titi lae.
1237.Iku ki ba ni sore, ko ma pa ni.
1238.Ibi ko ju ‘bi, b’a ti b’eru l’a b’omo.
1239.Ibi a ma ni l’a ba maa gbe, ibi a mo ni lo ju.
1240.Ibi ojo tin pa ‘gun bo, ona jin. (Taani ran gun se?)
1241.Ibit’o soro, eegun f’awon di.
1242.Iku nde dede, dede nde ‘ku
1243.Iti ogede ni, ko t’ohun t’a nlo da si.
1244.Ina g’ori ile fe ju.
1245.Ipin aise ni o pa alaraoka, idera de.
1246.Ibit’elekun ti nsokun, ibe l’alayo nyo.
1247.Ile l’a ti nko mesan mewa r’ode.
1248.Iku ko da ‘jo, arun ko d’osu.
1249.Iyan-an ja ni nb’ore ja.
1250.Ibaje ojo kan, ko tan l’ogun odun.
1251.Irohin okeere, bi ole kan, a din kan.
1252.Ibiti lekeleke ti nfo’so, ko fi be han ‘paro.
1253.Ile l’adie ko ti ni ‘yi, bob a de’ta, gbeke-gbeke lo to.
1254.Ire nbe ninu ibi, ibi nbe ninu ire.
1255.Ile oko, ile eko ni.
1256.Iya-ni-wura, baba ni diji, ijo iya ku ni wura-ola baje, ijo ti baba ba ku ni digi ola wo’mi.
1257.Imototo bori arun mo’le.
1258.Iku t’o pa, ti gb’apo re lo.
1259.Igberaga l’o nsiwaju iparun, agidi okan l’o nsiwaju isubu. Owe 16:18.
1260.Ibiti aye ba ba ni l’anje, b’ojo npao, maa to s’ara.
1261.Inu o gba, l’aaye o gba, yara kotop[o, gb’ogun ore.
1262.Iberu oluwa ni ipillese ogbon, ati imo eni mimo ni oye. Owe 9:10.
1263.Ile nsu, ile nmo, ojo nlo.
1264.Isapa toro mo, yan gbegiri toro m’oka.
1265.Iya ni nm’ahun sari-ri ki s’onje ahun.
1266.Ainun iba se ‘igba, a ba si.
1267.Idiro l’oko do.
1268.Ibi nu ko da nkan, suuru baba iwa.
1269.Ile ti a ba fi ‘to mo, iri ni o wo.
1270.Irawe t’o ba subu l’ode, degbe.
1271.Iyan d’atungun, obe d’atunse.
1272.Iyawo oju-ona, Olorun lo m’oko.
1273.Igi ti baa f’oju ree na, a ma gun ni l’oju.
1274.Ipako – obe ko ran ‘la, odi obe ko ran tete.
1275.Ile ni apoti njoko de idi.
1276.Inu nikoko dudu, l’eko funfun tin jade wa.
1277.Igba eke l’o nf’owo ti ‘le, igba alaamu l’o nf’owo t’ogiri.
1278.Ikun fe lee wa, aja ni ko je.
1279.Ise kii pa ni, aise re l’abuku.
1280.Igbati a ba ni ko ma ja, l’o nyo ‘be.
1281.Ibiti a ti nw’alaisan la ti now ra eni.
1282.Iwakuwaa l’a nwa ‘hun to nu.
1283.Iyawo ti a fi ‘ijo fe, iran ni o wo lo.
1284.Ijamba ta, fun ‘jamba ra.
1285.Ibanuje d’ori agba ko’do.
1286.Inu didun l’onm’ori yaw a.
1287.Ilu nla ko si mo, omo nla lo wa.
1288.Iran ogede kii sunkun atide, ara ko gbodo ni mi.
1289.Ijo t’o ba ka ni l’ra, iku – ku l’a fi njo.
1290.Iranmu l’ogbo, irungbon l’agba, tubomu ni t’afoju di.
1291.Ifura l’oogun agba,
1292.Igi gbogbo ni ns’owo, oto ni t’obi.
1293.Iru esin ko se deede, bakannaa ko l’a m’ori wa’ye.
1294.Itose lo l’oyo, onibode l’o l’alapinni.
1295.Ipako ni ‘le iya, iwaju ni ‘le baba.
1296.Ise de omo alaseje, owo ree, omo alasela.
1297.Iwa ko ni f’oniwa sile.
1298.Inu enu ki dun, k’a pamora.
1299.Ina njo, ogiri ko sa.
1300.Irir l’ogbon agba.
1301.Iran igun ni nje ‘bo, iran akala ni nj’oku.
1302.Igba wo ni Maku o ni ku, Maku ti ko mo’wem t’o nbo s’odo?
1303.Igbe da mi da mim l’o np’alakara.
1304.Igbaju igbamu, ni kerikeri nba wo ‘lu.
1305.Ilasa ko sunwon, ohun lo bi ‘la.
1306.Iya l’alaburo omo.
1307.Iku pa o wayi.
1308.Ise ofe ko ya.
1309.Igba esinsin kii dena d’owo.
1310.Iro ni nje a ku tan l’oko eniyan lo wa so ni ‘le.
1311.Iponju ko jek’aye o sotito, aisotoo ko jek’aye o roju.
1312.Iyan apelehin, a bi ‘di gongo.
1313.Irin kii ya gbajumo.
1314.Inunibini ko kan aima ‘waa hu.
1315.Ije-nje ana dun m’ehoro, o di ‘jo keji, o gbe ‘kun lowo.
1316.Igi to p’etun, l’ o pete eruko.
1317.Iran s’owo ni njere.
1318.Ile dida ni np’ore.
1319.Ilo omi-ojo.
1320.Ile ijamba kii su.
1321.Jeje l’aye gba.
1322.Je ki o yo, oogun ni ko je, oogun ti ko je, ewe re l’o ku kan.
1323.Jakunmo kii rin ‘de osan, eni a bii re kii rin ‘ru.
1324.Jewo obun k’a lee da ‘so roo.
1325.Je bee, ti Oluwa ni.
1326.Je kin je, l’o nmu ayo dun.
1327.Jebete gb’omo le l’owo.
1328.
1329.Ko run ni, ko run ni, o n d’oyi ka ni.
1330.Kokoro t’o nje ‘gba, ara igba lo wa.
1331.Ko nii buru-buru, k’o ma k’eniakn mo ni, eniti o ku l ao ma.
1332.K’a wi ki a too dani, agba ijakadi ni.
1333.K’agbado o to d’aye, nkan kan l’adie nje.
1334.Kekere l’a ti npeetan ‘roko, bob a dagba tan apa ko ka mo.
1335.Kokoro inu efo, aje-m-efo ni.
1336.Koriko t’erin ba tit e, a te gbe ni.
1337.K’a rib a wi. San ju k’a ma rib a wi lo.
1338.Ki ‘le too p’osika, ohun rere yoo ti baje.
1339.Ko lee je ti baba t’omo, k’o ma l’aala.
1340.K’oju ma ri ‘bi gbogbo ara l’oogun re.
1341.Ko ni tan ni ‘gbo osun, k’a ma ri fi p’omo l’ara.
1342.Kin ni agbe nse l’oko t’o fi su si ‘na, t’o nla fe?
1343.Kilo ya ‘pon l’ori, t’o fi su si ‘na, t’o nal fe?
1344.Ko moora, ti ng’esin lori apata.
1345.Ko si bi ao ti se fa, ti ko nii huwa ekuro.
1346.Kaka ki ‘le o ku, ile nsa ni.
1347.Ko r’ohun falejo, o yan guguru s’awo.
1348.K’okunrin r’ejo, k’obinrin pa, k’ejo sa ma tilo.
1349.Ko s’eda to lee t’aye l’orun.
1350.K’a m;eran so ‘kun, k’a m’okun, s’eran, k’ori opo sa ma ti gb’ofo.
1351.K’a p’emo nnu ‘la, k’a semnrue ‘lasa, oko emo ni emo lo.
1352.K’a ku ku l’omode, k’a f’esin se rele eni san ju k’a dagba dagba k’a ma l’adie ‘rano.
1353.Kin l’obo fi s’ori, ti ‘naki ko se?
1354.Kin ni nbe ninu adie, t’aawodioke ko mo?
1355.Ka rin k’a po, nye ni nye ni bii t’ona orun ko.
1356.Kin l’o ri l’obe, t’o fi wa ‘ru s’owo?
1357.Ko ni buru-buru, ki baba o so p’ o d’owo, omo oun l’orun.
1358.Ko si bi ao se s’ebolo, ti ko ni run yan.
1359.K’ee dun kop o, bintin l’obe oge.
1360.Ko to nkan l’o nso’ni d’ahun.
1361.A’a too fi karahun ha’koko, o d’ehin igbin.
1362.Kan-kan-kan, l’a ye ri.
1363.Kii ba ni, k’a ye ri.
1364.Kun0kun0kun, l’a nran ;fa aditi.
1365.Kin l’a nje ti kii tan, a f’ola Olorun.
1366.Ko s’ewu l’egberin eko, a f’ola Olorun.
1367.K’a f’owo we wo, l’owo fin mo.
1368.Ko s’alabaro, a f’olorun.
1369.Kuru-fin, ata l’ogun n emu.
1370.Ko ba won wa, ko nib a won lo, ajere ki ba won yun ‘do ose.
1371.Keregbe ni yoo so ‘biti ao ti f’okun s’ohun l’orun.
1372.Kaka k’omo oloore o jin si koto, mao-mano a sise imole f’omo Olorun.
1373.K’emi wo o, ki wow o o, ohun a dijo wo, gege ni ngun,
1374.K’a wi fun ni k’a gbo, iyi omo eni, k’a soro fun ni, k’a gba iyi omo eniyan.
1375.K’odi o lee ba gboran, l’a se nso l’oju omo re.
1376.Knni kan ajao je, apa re gun ju ‘tan lo.
1377.Kinniun ko j’oye, Olorun oba l’o fun l’ade.
1378.K’egbe o ma baje, k’egbe o ma baje, omode nbu baba agbalagba, o npe k’egbe naa o too fo.
1379.Kasa kasa l’a nri, o ku kesekese baba kasakasa.
1380.Ko dun mi, ko dun mi, agbalagba nb’opa l’ee-mefa nitori iyan ewu ana.
1381.K’a ro so mo ‘di k’a ro ‘di m’aso, ki ‘di o sa ma ti gb’ofo.
1382.Kelebe ba ‘le, dir a mu.
1383.Koko l’eegun ‘yan, suku l’eegun agbado, k’soro, k’a ba bee, l’eegun otito.
1384.K’eni maa sise bi erin, k’o maa je je eliri.
1385.Ko s’eniti yoo f’obe t’o nu je su.
1386.K’a wi, k’a fo!
1387.Kii deede binu, omo ale l’o nfa.
1388.Kaka k’eku ma je sese, fi s’awadanu.
1389.Ko’salapata to gbodo pa ‘gun je, eewo orisa aja kii j’obi.
1390.Ko s’obo kan ni ‘dere, eyi t’o ku nibe ewu etu. l’o now.
1391.Ki l’anfaani orogbo, a pa, ko l’awe a tun je, o koro?
1392.Ko si ‘gbati a da ‘so, ti a ko ri ‘le fi wo.
1393.Ko s\aaye ‘leke nidi adie.
1394.K’olorun ma jek’a nijo t’ebi np’ona.
1395.Kin l’ohun nse, ti ko lee gbe ‘kun le mu?
1396.Ko sin baba, ko sin ya, o so ‘lu onilu d’ahoro.
1397.Ko s’eniti a gbe g’esin, ti ko ni so ‘pako luke.
1398.Keregbe t’o fo dehin lehin odo.
1399.Ko s’ewu l’oko, a fi girir odo.
1400.Ko s’eniti nf’ida pa gbin, baba tani nfi ponpon p’alabahun.
1401.Koro ilu, ni ‘lu ti ntoro.
1402.Kokunrin duro to, k’obinrin duro to, k’a w’ara eniti o re.
1403.Kanko t’o b’akere fo, a da l’apa.
1404.K’a f’oro ro ‘ra eni wo, k’a too j’omo ole si kan ga.
1405.K’a ri ni lokeere k’a sariya, o yo ni o j’onje lo.
1406.Kin l’omo eye o se fun ‘ya re, ju pe ko dagba, k’p fo lo?
1407.Ko tan, ko tan, l’aja nla ‘mi.
1408.K’a w’eniti o lehin k’a f’omo furi, abuke koo be?
1409.Ko si ‘ku ti ko r’adie l’orun.
1410.Ko mese o yo.
1411.Ko je nsin mi, l’obinrin ngb’ale fun.
1412.K’otun we osi, k’osi we otun, l’owo fin mo.
1413.Kaka ko san, l’ara iya aje, o nf’omo re b’obinrin, eye nyi lu eye.
1414.Kaka k’ewe agbon de, nle l’o nle koko.
1415.Kii gun, k’o ma p’etun.
1416.K’onile o gbe ‘le, agba ti ko gbe ‘le e ori re a sun ta.
1417.Keke pa ,’atioro l’enu.
1418.Ko di ‘gbati a bna bi mo, k’a too p’omo ran nse.
1419.Kaabo o rewa, kii ti da ‘na ale, obe l’o ndun ju ra won lo.
1420.Ko si bi ti a kii ti sa ‘na ale, obe l’o ndun ju ‘ra won lo.
1421.Ko wo, ko wo, araba o wo ma, oju ti ‘roko.
1422.Kundu ke, bara o see di l’okun, omo ‘nu e, lo see fon ‘yan.
1423.Ko ni’le, ko l’ona, t’o nsinku abiku.
1424.Ko mu t’owo re, ko gba t’owo eni.
1425.Ko si kekere ana.
1426.K’a da si ‘le, k’a tun da, asa omo ele’yin ko o.
1427.Kinni nbe ni sa, ti nb’ oko l’eru?
1428.Kinni lagbalagba o se, ija ni nbe nibe.
1429.Ko si ‘biti a ko iti, kadie ale.
1430.K’a too yin ni, o f’abo oja.
1431.Ko lee dara f’aja, ko lee dara f’eran, l’onkungbe fin kun ‘gbe
1432.Ki Bara o sun, ko fi owu d’eti, ohun ti yoo ji Bara, yoo ji Bara.
1433.Lara eniyan ni ire wa.
1434.Lehin su, k’adie o fo ni.
1435.Laalaa ni t’agbe, Olorun ni npe ki ‘su o ta.
1436.Laalaa t’o r’oke, ile ni nbo.
1437.Labelabe ko ko ‘ja.
1438.Labalaba fi ‘ra re weyem ee lee se ‘se eye.
1439.Laise ani-ani….
1440.Lehin aponle, abuku lo ku.
1441.Lati kekere ni imole ti nk’omo re l’esin.
1442.Lekeleke t’o di korikosun maalu, ogbon a ti je ni.
1443.Laisi ofin, ese ko si.
1444.Laisi ese, ijiya ko si.
1445.Lani – ntan kan ko ni ‘ru esin.
1446.Lehin eedegbewa, eedegbebuse l’oku.
1447.Laya-nlaya o wo? Eewo, b’okunrin laya o wo, eewo, b’obinrin laya o wo?
1448.Lekewogbe, b’o ba leke – wogbe tan, ko see wa ri moo.
1449.Lainidi ese kii se
1450.Mo s’oore, ko gbe mi, l’owo kan ika nnu ni.
1451.Ma f’eran ikun gbaon eran agbonrin damu.
1452.Mo ri’le, mo r’ode, kii jeun awujo ti.
1453.Maalu ti ko ni ‘ru, olorun ni nbaa l’eesein.
1454.Mo f’oro naa se, osun mo fi pa ‘ra.
1455.Meji ni okiti, ata-tu ati ata f’ehin be ‘le.
1456.Ma f’owo mi ku, l’o nyan guguru f;eegun.
1457.Ma’ wa f’oni wa l’o nje ore j’ore.
1458.Mo mo’wa ara ile mi, kii se eebu.
1459.Mo nwa nkan kii jek’a ri nkan.
1460.Maalu ku, wahala b’obe.
1461.Mo p’ehin da tan, oju mi ko t’ehin mo.
1462.Ma fi tie ko mi l’orun, l’o difa f’eekan.
1463.Ma j’isu, ma j’eru, enu ayo lo mo.
1464.Ma ta ‘mi si mi l’ara, kii d’odo.
1465.Mo fi gboro je ‘ka, mo pegede.
1466.Ma yo mi iwo ota mi, bi mo ba subu, ng o dide.
1467.Ma koja mi oluigbala, kii s’orin akunleko.
1468.Mo j’ore mi lowo, ko sin mi, oluwa re ko ni ‘tiju ni.
1469.Mo je ki eti eni o di, kii je eni o dun.
1470.Ma je k’a gbo, iro l’ao ba nibe.
1471.Mo gbon tan, mo mo tan, ni o jek’agbon ile o loro.
1472.Ma gun l’oogun magun.
1473.Ma se l’oogun ma mo.
1474.Mo da were l’ohun, aja ni ngbe.
1475.Ma lo nbe kan ko si f’Alapa – nsan 0pa f’eniti o ba jiya ajerin-ajerin.
1476.Ma f’owuro sere, ore mi.
1477.Mo dagba, nko s’oge mo, owo ni ko si.
1478.Ma fe mi, ma fe ‘yaale mi, kinni eni nikan lao f’owo mu.
1479.Maa je nso, l’a mu oya tobi ju okete lo.
1480.Moni-moni boonu epo talo, ara ro.
1481.Ma j’oju ore akalamagbo ma j’oju ore oju ara eni leye nje.
1482.Mo pa ni apafon.
1483.Mo f' aimona bawon da pade npade
1484.N o lee k’owo r’esin, ki ntun k’owo ray ago l’ona.
1485.N o so, inu mi o fa, yoo si b’elomiran ninu je.
1486.Nigbati onile ba nf’apari isu han alejo, o nso pe ile too lo ni.
1487.Nkan nbe, agutan t’omo re so nu.
1488.Nbe in nbe, ni ana mi de, bi ko ba si b’ana ti wa ni yoo lo.
1489.Nitori akata l’a se da yangan, tori ijimera l’a fi so asotala, t;ori okunrin ni Olorun se da obinrin, t’ori ara ile l’Olorun fid a ‘ra oko.
1490.Ni ojoni ojo jije, okere, l’ojo aije okere, ojo ti okere f’ebi sun lo po j’ayo lo.
1491.N o ban a ‘wo re, ibi isana l’o ti nbere.
1492.Nigbat’ arunkun ba kunle, enu yoo so tire.
1493.Nko fe s’agba mo bun o.
1494.N o se ya, ko lee joy a, n o se baba ko lee jo baba.
1495.Nigbat’ afinju bay an ‘ko tan, obun naa yoo yan tire.
1496.Nibo ni ‘le ti njo, nibo l’a ti nk’eru?
1497.Ninu iku l’oro nje, ohun ti o je ni nwa.
1498.Nse l’aye nyi, a kan nto lehin ni.
1499.Ninu ikoko dudu l’eko fufnfun tin jade wa.
1500.Nigbati ologbo o ba fi p’agutan, gbogbo ile ni yoo ji.
1501.Nigbti nko ni ‘mu je, kinni ni o maa l’aja l’akiatan si?
1502.Nigbati nko ni mariwo ns’eso.
1503.Ntori eyin l’ai da eetan, ninu odidi la da eyin.
1504.Nibiti erin meji ba ti nja, koriko ibe awon ni yoo jiya.
1505.Ninu ofii olaa, ni omo pandoro ndagba.
1506.Nigbati aja nse ‘le, oko obo wa.
1507.Oniruru aso ni nbe lara alagemo b’o fe, a mu dudu, b’o wu a mu papa.
1508.O so si mi l’enu, o bu’ yo si, iso ko see gbe mi, beeni iyo ko see tu danu.
1509.Omi titun de eja titun si wo nu e.
1510.Ohun ti a ba fi sile l’ewure ngbe.
1511.O nle ‘run lo, o nba ale l’efon.
1512.Owe l’oro aye, kadara eda ko dogba.
1513.Owe l’esin oro, oro l’esin owe, b’ore ba so nu, owe l’ao fi wa.
1514.O wo sin bi obe paanu.
1515.Ohun owo mi o to, ma fi gogo fa.
1516.Ohun t’a nwa lo si Sokoto, nbe l’apo Sokoto.
1517.Okele akobu kii rahun obe.
1518.Omi po j’oka lo.
1519.Okeere l’oloju jimjim ti nm’ekun sun.
1520.Ohun t’o jo ‘hun l’a fi new ohun, eepo epa l’o jo posi eliri.
1521.Ohun t’aloko fi nso kun, l’oloko fi nrerin.
1522.O ri oko l’oko ‘kun ki o too gb’epa si.
1523.O ni sokoto penpe, l’o s’elewu – etu riyeriye.
1524.Onikun lo mo, ‘ka, alaso lo mo ‘ro.
1525.Ohun t’aja ri t’o fi ngbo, ohun d’agutan fin se’ranwo.
1526.Ogun odunm kii se titi lae.
1527.Ojo t’o pa ‘lapa l’ o fi d’amugun ewure.
1528.Ose ni nsaaju ekun, abamo l’o ngbehin oro gbogbo, otokun pe won ko r’ebo abamo se.
1529.Oju eni moo la, a ri ‘yonu.
1530.Owo tan l’owo oniwa, o’sonu.
1531.Owo t’a ba ni le, t’a nsise kun, owo naa ko lee run.
1532.Ohun a dijo ro, gege ni n gun.
1533.Ohun to ye ni l’oye ye n, okun orun ko y’adie, bob a tile y’adie, ko ye enit’o fa l’owo.
1534.Ogun ni mo bi, omo koriko, ogbon ni mo wo dagba omo eruwa kaka k’a bi okan, oga.
1535.Oju boro ko ni a fi ngb’omo l’owo ekuro.
1536.Oniyan se, olobe se, emi ti mo je ku aibinu.
1537.Oruko ti ao so ‘mo, inu eni ni ngbe.
1538.Oorun t’o ku l’oke, to aso sa.
1539.Oju apa ko j’oju ara.
1540.Onibata t’o jo ti ko mi yeri ara re l’ota.
1541.Ohun ti tooro se, egba idobale ko lee se.
1542.Oo ti m’ewa, l’onje ejesun.
1543.Osise wa l’oorun, nawo nawo wa ni booji.
1544.O se ‘le ana, ko je k’a lee sunkun si.
1545.Ori l’ fi nm’eran l’awo,
1546.Oju iwaju ki pa ‘hun, tehin kii pa gbin.
1547.Olohun ko ni gb’esan aawo ko ni tan l’orun.
1548.Oku, ko mo ‘ye a nra ‘go.
1549.Ogun awiile, kii pa ‘ro to bag bon.
1550.O ko s’emu l’ogbe, o ko t’oguro l’ofa, o de ‘ide ope, o gbenu s’oke, ofe ni nro?
1551.Ohun to wa lehin ofa, ju oje lo.
1552.Ori eniti yoo su’po, kii je kolokun o ye.
1553.Ohun ti ko too su ‘po kii je k’olokun o ye.
1554.Ologun na kan, kii rin leti omi.
1555.Oju mewa, ko j’oju eni.
1556.Oju kan l’ada nni, eyiti’ o l’oju meji di obe.
1557.Owo l’obin’mo.
1558.Oore t’a se f’adie ko gbe b’o ba pe titi, a s’omi ota si ni lenu.
1559.Ojo ko b’enikan s’ota, eni eji ri, l’eji npa.
1560.Oko kii da ni, lehin epon.
1561.Okeere, l’a tin se, ma t’opa bo mi l’oju.
1562.Oniru – nru obe la f’a nri ni ‘jo ku erin.
1563.Owo t’a fi r’eko omuro nii jeki a so nu.
1564.Orisa ni nf’abaimo l;enu san, a ni ;jo t’ouh ti de le oko ehin oun oun ko dide.
1565.Oode ni, ti a ba de bi eyin ti kop on ko.
1566.Omi gbigbona dapo mo tutu, Olorun lo le yanju re.
1567.Osi ni iye ta nmo o, owo ni nje mo ba o tan.
1568.Osika gbagbe ola, adaniloro gbagbe ojo ikehin.
1569.Oosa b’o lee gbemi, se mi bi o ba mi.
1570.Owo t’omode ba koko ni, akara ni fi nra je.
1571.Oruko rere san ju wura ati fadaka lo. Owe 22:1
1572.Onisango to jo, ti ko yeri, abuko ara re lota.
1573.Oo l’obinrin, oo l’a fi aje, oninu re yoo fi tire sile fun?
1574.Oju l’pge.
1575.Omi l’o danu, k’Olorun mase jeki agbe o fo.
1576.Ole t’o gbe kakaki, nibo ni o ti fon?
1577.Oore pe, asiwere eniyan gbagbe.
1578.Ogbe run ‘le, ki o too run ‘de.
1579.Alogini t’ajo de, ekute ile pa ‘ra mo.
1580.Okete bayi ni ‘wa re, o ba ‘f mule, o da ‘fa.
1581.Oko ti a mu s’ope, l’ope nmu so ni.
1582.Ofo l’omi efo sne.
1583.O y’omo t’o nsokun. O ye, ‘ya re to ne.
1584.Onisuuru l’o s’oko omo Alausa.
1585.O pe ni, o ya ni, otito ni yoo leke.
1586.Ohun t’o m’omo je kii r’omo nu.
1587.Ojo t’o ro s’ewuro, naa lo ro si ‘reke.
1588.Ohun a f’ele mu kii baje, ohun a ba f’agbara mu kan –kan-kan lo nni l’ara.
1589.Oore kii gbe.
1590.Omi eko, eko ni.
1591.Ori ja j’oogun lo.
1592.Ori bibe ko ni ogun inu rerun.
1593.Oko abinuso, kii b’ewure.
1594.Oju ti yoo b ni k’ale, ki t;owuro se pin.
1595.Oni loni nje, eni a be lowo.
1596.Ori wo ‘bi ‘re gbe mi de, ese wo ‘bi re sin mi re.
1597.Owo ni bi ohun ko ba si ni ‘le enikeni ko gbodo da ‘moran, alaafia ni a f’ohun, o ni a fi bee.
1598.Olooto kii l’eni, sugbon ko ni sun ni ‘po ‘ka.
1599.Ohun to ye ni lo ye ni, agbabo sokoto ko y’omo niyan.
1600.Oju l’o nti omo, enu ko gbodo ba omo.
1601.O ro, o ju eko lo.
1602.Ohun ni a nmu ofafa, idi igi l’a nba.
1603.Osupa abe iti, a ran d’odede ole.
1604.Ogun l’o nsi ni mu, epe kii si ni pa.
1605.Oko rin’rin gbooro.
1606.Oju awo, l’awo fi ngb’obe.
1607.Olofofo year ao so’ro awo, a ns’oro l’owo, nkan ‘lu keke olofofo year, ao soro awo.
1608.Oo lo ni’le, kii s’epe alejo.
1609.Obinrin tori oro r’odo.
1610.Ori ade, ko nis sun’ta.
1611.O ta fa soke, o yi ‘do bori, b’oba aye ko ri o, oke nko?
1612.Ofo eni, kii s’elomiran.
1613.Obinrin bi’mo fun ni, kop e k’o ma pa ni.
1614.O b’enikan ja, f’owo gun gbogbo ‘le nmu.
1615.Oku omo ‘ya yi.
1616.Ofo, jo keji oja.
1617.Ojo owuro, ti nb’olowo nnu, olowo gelete, iwofa gelete.
1618.Obinrin ko ni gogo-ngo.
1619.Ori to yoo la ni, l’o ngb’alawoore ko ni,
1620.Ohun ti ko ba ye ni, ko m;agba da.
1621.Ori kunkun bi’ iwofa adao-jo ya.
1622.Omi ti ao ba mu, ko ni sasn koja eni.
1623.Oku odun meta, kuro ni alejo saree.
1624.O ni ohun ti ajanaku ri ko to se ‘nu gbendu s’oloode.
1625.O ri enit’eegun nle lo, o fa l’obe la, ojo wo l’o to maa r’ere ara orun je?
1626.A f’ete sile, o npa lapalapa.
1627.Oogun ti ko je, ewe re ni kop e.
1628.Owu kii la, ki nu o b’oloko.
1629.Ole kii j’agba, k’o ma ko firi.
1630.Oru ko m’olowo, o dif a fun ‘wo tanu u?
1631.Oju alejo l’a nje gbese, ehin re l’a nsan.
1632.Oromadie t’o l’ohun o fi t’asa se, osan gan-gan l’asa o gbe.
1633.Olowo s’oke di le.
1634.Ori eniti a ti f’agbon kii duro je.
1635.O f’ete oke da’ko l’eerun.
1636.Ole l’oko aje.
1637.Ohun a ni okobo o bo, ko lee bo, o ni oun bo ile ana oun, o di tete.
1638.Ole lo m’ese ole to, l’ori apata.
1639.Ookan ni won nt’esin l’orun, taani yoo loo ba ni ra?
1640.Owo ko si, eniyan ko sun won.
1641.Oore l’o pe, ika kop e.
1642.Ohun t’oju agba ri to fi jin, b’oju omode ba ri yoo fo.
1643.O nwa owo lo, o pade iyi l’ona, bi o ba ri owo naa tan kin ni oo fir a?
1644.Ole ti a ba lori ope, t’o ni oun fee sa ekuro?
1645.Orogbo ni ngbo ni s’aye, obi l’o nbi won s’orun.
1646.Omi l’a nte ki a too te yanrin.
1647.Ohun ti a ko ni je, a kii fi run mu.
1648.Okele kii bo l’owo ojeun.
1649.Oju omode kii kuro nibiti o ti he ‘gbin lana.
1650.Ohun to mu aaro, lee mu ale.
1651.Oosa je np’eji obinrin ko de nu.
1652.Owuye, a soro so bi oro.
1653.Oorun l’o ngba t’owo omode.
1654.Oju l’a nmo didun epo, enu l’a nmo didun obe, bi ‘le san bi o san, awo l’a now.
1655.Oni l’ao mo b’ola o ti ri.
1656.Oju mo ohun t’o yo ‘nu, idodo ni ‘dariji ara.
1657. Oro akoda, ko to o now ni.
1658.Olowo ns’ore olowo, otosi ns;ore otosi, keni-mo-ni ns’ore ara won.
1659.Ojowu ‘binrin a bi ponrin l’eti, b’o l’ohun sun lo, a si maa wu ‘ko.
1660.Ojowu ‘binrin a bi ‘ponrin l’eti, b’o l’ohun sun lo, a si maa wu ‘ko.
1661.Ojo ko tii da, a ni ko to t’ana.
1662.Oju l’oro wa.
1663.Oju orun t’eye fo, lai f’ara kan ‘ra.
1664.Oju l’o nkan ‘mo ole t’o nda ‘jo eyiti won da lana, baba re lo ko lo.
1665.Obinrin ko see fi ‘nu han.
1666.O d’owo ale ki alaburuda (agboorun) too mo pe eru ni.
1667.O wu ni k’a je ‘ran pe l’enu, sugbon onfa ona ofun ko je.
1668.Ohun sesere, ni nj’ house l’oju.
1669.Ojo t’o ro, lee wu ‘lu ole.
1670.Oogun ti a ko f’owo se ehin aaro l’o ngbe.
1671.Oloju ko ni la’ju re sile, kop e ki talubo o yi wo.
1672.Ohun ti eye ba je, l’eye ngbe fo.
1673.O fi tire sile gbo t’eni eleni, Olorun ni nba gbo tire.
1674.Ohun ti a ba fo fun fere, ni fere nfo jade.
1675.Ohun ti a ko ba jiya fun, kii t’ojo.
1676.Oju l’a mo se, oro gbe ‘nu omo eniyan fohun.
1677.Omi ti tan l’ehin eja.
1678.Ohun t’ose ‘la ti ‘la fi ko, ohun lo se kaan, t’o fi w’ewu eje.
1679.Oju ina l’ewura nhun ‘run?
1680.Ogun omode, kii sere gba ogun odun.
1681.O d’ehin igbin, k’a too fi ‘karahun ha koko.
1682.Oju t’olowo, t’o ko’le tan, ti ‘le tun seku.
1683.Ori agba maa m’ewe nso.
1684.Oorun ale, ko ba ‘do mo.
1685.Olowo eni kii roro, k’o pe k’a ma su.
1686.O to gee, alubata kii da ‘rin.
1687.O f’oju j’ekun j’ekun ni, kii p’eraran je.
1688.Owu iya gbon, l’omo o ran.
1689.Oju l’o nroju saanu.
1690.Orisa bi ofun ko si, ojoojumo l’o ngb’ebo.
1691.Ojo ko lee pa ‘ogogo, ko ma lee ro.
1692.Oju t’o ri bi ti ko fo, ni yoo si maa ri.
1693.Ojoojumo l’ekun alabosi.
1694.Olowo l’agba.
1695.Oju l’a ti m’akusin.
1696.Ojojo ns’ogun, ora ogun ko le.
1697.Oko see ro, l’omo agbede np’oko ta?
1698.Owo ni koko.
1699.Owo fun ni, ko t’eniyan.
1700.Owo ko ni ran.
1701.Owo kii ni ‘ye, k’omo o ku si ‘lu.
1702.Oju to ti wo gedegede, ti d’opin, won kii kan.
1703.Oku aja, won kii gbo, oku agbo, won ki kan.
1704.Ofof ko gb’egbaa, enu ope l’o mo.
1705.O npe ni l’o ns’ ola, eno a pe kii s’ola.
1706.Oni l’a ri, ko s’enit o m’ola.
1707.Ole t’o be si le, t’o ni ki, ki re ku eekan.
1708.Odo t’o gbagbe orisun re yoo gbe.
1709.Ohun ti a ni l’a nnani, omo asegita nnannni eepo gi.
1710.O ye k’a m’eewo ara wa, ki a ma baa se ‘ra wa.
1711.Oku nsokun oku, akasolori nsokun ara won.
1712.O nse mi, o ngba mi, a see dupe l’owo enit’o nse ni t’o tun ngba ni?
1713.Ohun ti a ba fi pamo, l’o nniyi.
1714.Ohun ti ko l’emu, ko gbodo gbon ju ni lo.
1715.Odo t’o t’oju eni se, ko lee gbe ni lo.
1716.Ohun to se akalamagbo to fi dekun erin-rin, b’o ba se gunnugun, a le wonkoko s’ori eyin.
1717.O r’eni t’o nkan ‘ju lo si Ilorin, o ni k’o ba o ra tiro bo, oju otun l’oo le si, abi t’osi?
1718.Ori ni eja fin la ‘bu.
1719.O ku die ki nwi, ojo l’o nso ni da.
1720.Olowo ko r’omo ra.
1721.Oju to ti r’okun, ko le r’osa ko beru.
1722.Ohun tin be ninu eni, l’oti nib a.
1723.Ohun t’ o wu ni l’o npo l’ola eni.
1724.Okun kii duro riri k’a wi riri, suru l’oro gba.
1725.Obinrin t’o ti le ale de, t’o ngb’ oko re l’eti, Olorun yoo da.
1726.O nr’Oyo, o nkanju, Alaafin ko re ‘bikan.
1727.Oruko eni, ni janu eni.
1728.Okun ti a de f’aparo, agility lo mu!
1729.Oloogun l’o ns’oko abiku, amulenu, l’o ns’oko alapepe.
1730.Ogidan ko ni se ‘barber’, k’aja de be loo ge run.
1731.Ohun t’agba fi nj’eko, abe ewe l’o wa,
1732.O nlo, o nbo, bi ‘leke idi atioro.
1733.O ho gudu-gudu da wai-wai.
1734.Ofin t’o de eegun l’o de eleha.
1735.Oorun ko mo ‘ku.
1736.Oju – la – ri, ore ko de ‘nu.
1737.O kere nibi owo ojule, o dagba nibi oka saraa.
1738.O tule – tule, t’owo b’oku l’oju.
1739.Onile ni l’owo, alejo di s’eru.
1740.Olooka gb’ooka, owo awe d’ofo.
1741.Oni-magun t’o nje ‘bepe, ki ‘rin aajo re ba le ya ni.
1742.Owo a maa tan, oore-ofe Olorun nikan l’o nwa titi – lae.
1743.Odu kii se aimo oloko.
1744.Onisu l’o ni yan, agbon – sale l’o ni hou-hou.
1745.Oni-jibiti, l’o nla ‘igi saree da ‘na.
1746.O feje si ‘nu, tuto funfun jade.
1747.Ogbodo ti o fi ni sesin, gongori imu l’o tin mu ni.
1748.Olooto ilu, ni ‘ka ilu.
1749.Ohun gbogbo, l’o n nira l’oju ahun.
1750.Ode l’a ns’agba, ile kan bi ibo.
1751.Oni-nkan laa je o se.
1752.Oju gbona, olomo o m’omo ma.
1753.Oni-kuruna t’o ni ‘nu o dun, s’ ode re naa dara?
1754.Omi ngba yanrin gerere, omi ko l’apa, omi ko l’ese, pmi ngba yanrin geregere.
1755.Ori obinrin ko ni buru, k’o ma ni iyako.
1756.Ole kii ti ‘di m’ejo ro, bi won ba ni bawo, a ni oro ti ko to nkan.
1757.O ntan lo niyen, baba t’o nfe ‘binrin omo re.
1758.Oju ko lee pon babalawo, ko beere ebo ana.
1759.Okuta meta ko see gbe k’ori ara won (eyin).
1760.Oju yo ro, nu rore nso.
1761.Okete gbagbe ‘bosi, o d’ori ate, o ka ‘wo l’ori.
1762.Okete bo, ru!
1763.Owo kii f’owo l’orun, je nse t’emi.
1764.O nre ‘sun da sinu ibu.
1765.O tutu bi omi amu.
1766.O ri ‘yawo ko ‘yaale.
1767.Ohun ti a ba je, la nsu okere j’eyin, o su ‘ha.
1768.O wo ‘lu-apara, yan ‘ko para?
1769.Osika ko lee gba le, eni re ni o ka.
1770.Omi ti tan lehin eja.
1771.Ohun kan l’eniyan ti fi niyi, ohun kan si ni eniyan nse ti fit e.
1772.Okoto iro kii pe jadi.
1773.Oruko iro kii pe jadi.
1774.O nd’ eja.
1775.Orisa bi ‘ya ko si, iya l’alabaro omo.
1776.Onbigbese ns’ebo, dundun ngbin.
1777.Oruko Aromiyo dun da.
1778.Ojo nro si koto, gegele nbina.
1779.O ti gbe saraa koja Mosalasi.
1780.O fi ‘yan sile, o nd’ oka l’aamu.
1781.Oni kangun nkangun.
1782.O nparo, o nsofofo, o njale oro gbogbo l’ara re.
1783.O ye k’eru o sa, o si ye k’olowo re o wa.
1784.Oju aja ns’eje.
1785.O tan nnu oko l’obinrin, ko tan oko ko lee saiku bi ‘su – elu.
1786.Oju ni nkan oko, ale meji o jab o pe.
1787.O so ‘ko oro si mi.
1788.O pa won ku.
1789.Ori abiku ko lee tobi to ori baba re, o b’o ti wu k’ o tobi to.
1790.Otito koro.
1791.O juba ehoro.
1792.O f’ehin ‘le, o f’ese fe.
1793.Ohun to se ‘gun t’o fi pa l’ori, lo s’akalamagbo t’o fi yo gege l’orun, b’o ba s’odidere, yoo le  wonkoko s’ori eyin.
1794.Ofofo kii duro gbo ‘di oro.
1795.Olu – sesi, ni ‘na o tan ‘wo.
1796.Olowo nsoro talaka nda si, o ni petepete o fo, se yoo su si sokoto ni?
1797.Okobo kii bimo si’tosi.
1798.Ogede kii gb’odo, ko yagan.
1799.Olorun m’aja, o d’egbo l’ori.
1800.Ona t’omi gba wo nu agbon, taa lo ye?
1801.O kehen-nkehen, ode ni o tio kehen wa ‘le.
1802.Omo t’o jib a ni nidi onje, t’o ni k’a maa mu ni meji-meji, bi won ba nmu bee, se yoo ba nkankan ni     ‘le.
1803.Ogede nbaje, a ni npon.
1804.Omo go, a ni ko sa ma ku, kinni npa omo bi ago?
1805.Ona l’oore ngba wo ‘lu.
1806.Omo atiro t’o bata fun baba re, oro l’o fee gbo.
1807.Ojo aajo ko ni nre ‘kanna.
1808.Ole ko lee se ‘gbagbo, oroju ko lee se’mole.
1809.Omode ko lee m’oori je, k’o ma ra l’owo.
1810.Ologbon d’ori eja mu.
1811.Ojo t’omo bad a epo nu, a kii ba wi, sugbon ojo ti o bad a omi nu – a je po iya.
1812.Ole yun’do, o ka kun ‘se.
1813.Omo t’o ba sipa ni a ngbe.
1814.Omo ko l’onibawi, omo ra, o sindin.
1815.Oloode t’o ba sipaa ni a n gbe.
1816.Oro buruku, kii ba ‘kun nle.
1817.Omo ko layole, eni omo sin l’o bimo.
1818.Omo gbon, agba gbin, l’a fid a ‘le ife.
1819.Ojo gbogbo ni t’ole, ojo kan ni t’olohun.
1820.Obe ko lee mo ‘ye’la t’ohun ti re.
1821.Oro se ni wo, k’a lee m’eni t o fe ni.
1822.Omo ku, ya j’omo nu lo.
1823.Ofan to si gbegiri, ki kaluku k’eko re s’owo ni o.
1824.Oro agba, bi o se l’owuro, a se l’ojo ale.
1825.Obe t’o dun, owo l’o pa.
1826.Oro l’o ny’obi l’apo, oro naa, l’o nyo ‘fa ninu apo.
1827.Obe kii mu, ko gb’eeku ara re.
1828.Ola nlo, ti nfi kete s’amu.
1829.Owo omode ko to pepe, t’agbalagba ko wo keregbe ise ewe b’agba, ko mai ko, gbogbo wa l’a ni se, ti a nbe ara wa.
1830.Okanjua ndagba, ogbon nu re npo si.
1831.Oto ni ti Tolu, oto ni Tolu, oto ni ti Toluwo.
1832.Ona yoo m’ole, ahee ni yoo m’oloko.
1833.Oto ni ti kan-un laarin okuta, Pataki ni t’iyo l’obe.
1834.Oro t’aboyun ba so, eni meji lo so.
1835.Oro sun nukun, oju sun nukun, l’a fi now.
1836.Oro ti a ni ki bale o ma gbo, bale ni yoo pai e.
1837.Oro l’oni, itan l’ola.
1838.Oro okeere, bi ko le’kan, yoo din ‘kan.
1839.Ona l’o jin, eru ni baba.
1840.Oye nfe, oo funfun, iri nse, oo jolo, onisegun ni yoo f’owo re mu ‘ko.
1841.Operekete ndagba, inu adamo nbaje, mo di baba tan , inu nbi won.
1842.Owo oloju l’a ti nbeere, ki a too gba.
1843.Opolo yan kongbe l’oju elegusi, elegusi ko gbodo yi l’ata.
1844.Opolo ko ko jo konko, ma mu.
1845.Oto l’owo, oto ni, yii.
1846.Omo arugbo kii jek’a s’arugbo l’oore.
1847.Ore s’otito k’a le ri ‘ja re gbem Olorun nbe lehin asododo.
1848.Oro l’ore e, o l’ooko, b’o lo s’oko, b’o lo s’odo, o nbo waa b’oro re nile.
1849.Oko oloko l’a fi ngbun ‘gan.
1850.Omode ko m’oogun, o npe l’efo.
1851.Omo ajanaku ko ni yara, omo t’tekun bi ekun ni yoo jo.
1852.Omo ogongo, ni yoo mu ‘ya re wa.
1853.O yokun nyokun, agba ti ko yokun, ahun lo ni.
1854.Okunrin din ‘wo, ndin ‘gun.
1855.Omo t’o ni ki ‘ya oun o ma sun, oun na ko ni f’oju ba oorun.
1856.Ojo ti a gun ko ni a nkan ‘run.
1857.Ogede l’o wo koko ye ko too di ‘gi buruku.
1858.Olele t’o ba wo ‘nu eko ko lee jade mo.
1859.Oba mewa, igbamewa, Seriki ngoomo, sanmoni ngoomo.
1860.Omo eni iba ko ni, a bay o.
1861.Okansoso ajanaku, ti nmi’gbo kiji-kiji.
1862.Omuti gbagbe ise, ajokondo gbagbe igba ti o ro l’oko lola.
1863.Opo oro kii k’agbon, afefe ni ngbe e lo.
1864.Omo o ku ni, yoo ye ni, ao k’olomo ku ewu.
1865.Owo epo l’omo araye nba ni la, won kii ba ni la’wo eje.
1866.Omo kuro lowo nina, o k’awomoju.
1867.Oro t’owo ba se, t’o se ti ile ni ngbe.
1868.Ogede dudu ko ya bu san, omo buruku ko ya lu pa.
1869.Obele nbe ‘le wo, b’ewure o ba sun, a ye ‘le wo.
1870.Ona po l’eerun.
1871.O ja ‘le onile bo tire l’ehin.
1872.Obo ni t’ohun ba je tan, t’ohun ba mu tan, t’ohun bar anti apa to wa ni di’ohun, aye a sis u ohun.
1873.Oro t’ologbon ba so, enu asiwere l’a ti ngbo.
1874.Obun ri ‘kun oko ti ‘ran mo, o ni jo oko oun ti ku, oun ko d’odo we ri.
1875.Obe tutu, adamu fon la.
1876.Ogbon t’alabahun ni nri ‘nu, ti kii bi omo – ale ni a nbe ti kii gba.
1877.Okookan l’a nyo ‘se ‘l’ eku.
1878.Ogbon t’alabahun ba gbon, ehin ni o maa to ‘gbin.
1879.Ona ki di, k’adie o ma de ‘bi eyin re.
1880.Opo iru kii b’obe je.
1881.Omo ale eniyan ni nri ‘nu, ti kii bi, omo-ale ni a nbe ti kii gba.
1882.Owo ara eni l’a fi nt’oro ara enu se.
1883.Ona ofun ko gb’egungun eja, ma dan wo.
1884.Oto ni ti gangan, oto ni t’ewura, oto ni t’esuru lawujo awon isu.
1885.Oga ta, oga ota, owo alaru o pe.
1886.Ore kitikiti, iyekan katakata, ojo ti ore kiti kiti ba ku, iyekan katkata ni o ku.
1887.Ologbon ko le ta omi ni koto, omoran kan ko lee fi ara re j’oye.
1888.Ore nj’ore, ora nj’ora, a kii dupe mo t’opo.
1889.Odoju l’a b’owo, itiju l’o bi gbese.
1890.Omode ko j’obi, agba ko j’oye.
1891.Ogbon enikan, alawe eko ni.
1892.Oro t’o ba koja ekun, erin l’a fir in.
1893.Ola abata l’o nm’odo san, ola baba ni nm’omo ya.
1894.Okere g’ori iroko, oju ode da.
1895.Owo die die l’ara nfe.
1896.Oro ko ni le.
1897.Oba ran ni ni ‘se, odo oba kun, ise oba ko see ki beeni odo oba ko see ro lu.
1898.Obe ti bale ile kii je, iyaale ile ki se.
1899.Odun mejo l’ao se l’aye, t’ao maa w’ewu irin?
1900.Ona jinjin kii ta ni l’osi, wahala l’o nko ba ni.
1901.Ogbon odun ni, were emii.
1902.Omo olomo l’a nran ni ‘se de toru toru.
1903.Ore t’ao fe, ni ‘le re njinna.
1904.Oro ni ko je k’enu o hun ‘run.
1905.Omo oju o r’ola, ni nso ‘mo re l’olaniyanu.
1906.Ona inu jin.
1907.Oro l’omo l’eti je.
1908.Oro kii tobi k’a f’obe bu.
1909.O ge fila, ni yoo buru, ko mo ‘pe re.
1910.Okose ko mo ‘pe buru, ko mo ‘pe re.
1911.Omo – odo kii lu ‘ya re lasan, agbe l’o dija sile.
1912.Ogbon ko ni tan l’aye, k’a wa lo s’orun.
1913.Ode t’o re gbe ti ko m’eran bo, irin are ni o rin de ‘le.
1914.Omo ‘na l’a nran si ‘na.
1915.Omo t’o ba m’owo we, yoo ba ‘gba jeun.
1916.Orun nya a bo, kii s’oro enikan.
1917.Ojo melo ni ‘ku arugbo ku, ti a ni k’o roju, k’o roju mu?
1918.Omode l’o nse ni agba kii s’eniyan.
1919.Owon –ni – yan, l’o nrin abuke je bale.
1920.Ofon ni eni ti o pa ohun, ko to enit’o njan ohun mo’le.
1921.Ole ba ti, o gb’odo nla.
1922.Opele kii ba ‘le, k’o ma so t’enu e.
1923.Olorun ma je k’a rejo, a t’ebi, a t’are.
1924.Oro b’ologbon, o d’egbe omugo.
1925.Olorun ti mnse ‘be, ko kuro nidi aaro.
1926.Owo ni nt’ara se.
1927.Olumole ko gbodo wipe igi o da, kin l’oniyaalu o so?
1928.Omode l’o nm’orin agba a si maa mo ‘tan.
1929.O pe titi aboyun, osu mesan.
1930.Owo too, ni n m’;owo too wa.
1931.Oro ko pariwo, gbe panla jewo, o l’oun se bi eepo igi ni.
1932.Ogbon nbe ninu aro ese ni ko si.
1933.Obe t’o se ti ‘le fi jo, o o so.
1934.Oro di ‘su, a ta – yan – yan.
1935.Olorun ko d’enikan k’o ma ni laari, eniyan ni ko je.
1936.Opo eniyan l’o nd’eru nu.
1937.O gba ‘le gba saara, a gba t’oko ma gba ti ‘yaale.
1938.Ototo eyi l’ana ‘gbin, ‘gbin ku, ikarahun ko sunkun?
1939.Obe o dun, oko o je, gbese de oko yeri.
1940.Ojo ti a ba ri ‘bi, ni ‘bi now ‘le.
1941.Oba bu mi, mo bu, iran – n – ran re, ko ni je k’eniyan o sun.
1942.Ojo nii pe, ipade kii jinn a.
1943.Obun ko mo p’ohun to po, a maa tan.
1944.Omo t’aye bi l’aye npon.
1945.Ole d’orun.
1946.Oko bi emo, aya bi afe.
1947.Ojo kan ojo, t’egbaa oda.
1948.Ore da ‘be nyan ‘ko.
1949.Ota eni, kii p’odu oya.
1950.Ona ofun, ona orun.
1951.Owo palaba se’gi.
1952.Opo ojo l’o ti ro, ti ‘le ti fi mu.
1953.Oro p’esi je.
1954.Opolo ko mo ‘na odo ma o wad a s’auruju.
1955.Olaja n info ‘ri gb’ogbo.
1956.Pasan teere ti a fin a ‘yaale, nbe ni yara iyawo.
1957.Puro nniyi, bi a ba ja ni, ete nii da.
1958.Pa leekinni, pa leekeji, eleeketa l’ajenje – tan.
1959.Pipe ni yoo pe, akololo yoo pe baba.
1960.Pele l’ako, o l’abo.
1961.Piri l’olongo nji, a kii b’okunrun eye l’orin ite.
1962.Petepete t’a na ni popa, eniti o bat a ba, k’o foriji wa.
1963.Pati ko m’ola, k’a sise bi eru, ko da nkan. Owe 10:22.
1964.Pasan ologinni, ko si l’owo ekute.
1965.Patpata l’a nfo’ju kuna kuna ni a nkuna, oju a foo fotan, ija ni nda sile.
1966.Pa mi nku, s’ori benbe s’oko.
1967. Pa leekinni, pa leekejim b;oju ohun ko ba fo, yoo di bara-bara.
1968.Pipe l’a npe gbon, a kii pe go.
1969.Parakoyi l’o ni ‘le, oba lo ni sesefun.
1970.Pa mi si ‘le, ma pa mi s;ode.
1971.Popo ni ‘le ogun, isale ni ‘le ore, b’ogun ba tan, ao pade l’odo.
1972.Riro ni t’eniyan, sise ni t’Olorun.
1973.Rikisi pa won po, won d;ore.
1974.Ranti omo enitiu iwo ise.
1975.Ri ni se ni l’ojo.
1976.Sasa eniyan l’o nfe ni l’ehin bi ao ba si ni ‘le, t’aja t’eran l’o nfe ni l’oju eni.
1977.Seran seran, l’eniti nje wo fun.
1978.Sibi gbolide, alantakun ta ‘wu di ‘saasun, sibigbolide.
1979.Saawo, l’eebu agba.
1980.San-an l’aa rin, aje ni nmu ni pekoro.
1981.Sun mo ni l’a nma ‘se eni, eniyan gb’okeere ni yii.
1982.Suru baba iwa, agba t’o ni suuru, ohun gbogbo lo ni.
1983.Sangba fo!
1984.Sa bi oloogun.
1985.Sise koro, jije ofe.
1986.Se mi nbi o, l’oogun ore.
1987.Sika gbagbe ajobi, adaniloro gbagbe ola.
1988.Sigidi fee sere ete, o ni ki won gb’ohun s’omi.
1989.Sokoto ti nsise aran, ko gbe ‘le.
1990.Sawo, l’a fi ngb’ ada lowo agba, agbe suuru t’o l’ojo ni.
1991.Suuru t’o l’ojo ni.
1992. Suuru la fi n se oko obirin.
1993.Se s’elomiran, b’o ba ti fe ki won se si o.
1994.Sokoto ko bale, a ni k’a gba l’eti?
1995.Sogun sogun ewure, enu oriso re lo mo.
1996.Sakata-paara l’agbalagba nwu’ko, ko si gbongbo kan l’ona ofun.
1997.Se b’o ti mo, elewa sapon (Abeokuta.
1998.Se ka ri mi, t’o fi paali eja to ‘le.
1999.Sango o gbona, elegun lo gboo-run.
2000.Se b’o ti mo, t’o f’adie kan se ‘komo.
2001.S’abiya re mo?
2002.See ‘le ni nje see ke.
2003.Se’oju lo pe si, omo alapata ti nj’eegun?
2004.Tori akata, l’a fid a yangan, tori eya l’aa ko yanju.
2005.Ti ‘na ba jo ni, t’o jo omo eni, t’ara l’aa ko yanju.
2006.Tode tode l’o ns’alaso titun.
2007.Timu timu k’egbin da si ‘nu.
2008.Taani nj’omo akuwaapa, l’oju omo aku yan – yan?
2009.T’owo ni ko jeki t’eeke o kunna.
2010.T’omode ba r’egbe re t’o ngesin lo niwaju o ye ko w’egbe baba re t’o nf’ese rin bo l’ehin.
2011.Tori mojiya l’a se nya majiya l’ofa.
2012.T’eni o gun l’o gbon.
2013.Taani je j’ose, k’o f’ogiri fo ‘so?
2014.T’eni be ‘gi l’o ju, igi a ru ‘we.
2015.To omo re, yoo si fun o ni isinmi. Owe 29:17.
2016.T’egun ba de ‘bo hun o fee yo ni.
2017.Tori ologbon, l’a se nd’aso asiwere dada.
2018.Ti a ba ki f’awo, awo a ki f’ogberi.
2019.Taa l’a ba wi, bi enit’o f’omo f’oko, ti ko jeki ‘le o mo?
2020.Tosan tosan l’o npon aitale l’oju, b’o ba d’ale a d’oko olonje.
2021.Tooro asiko, ya ju poun kana se lo.
2022.T’oju t’iye l’aparo fi nriran.
2023.T’eru t’eru, l’abuke now ‘lu.
2024.T’ojo t’eerun, ile alakan kii gbe.
2025.Tita riro l’a nko’la, b’o ba jinn a tan, a di t’oloun.
2026.Taani esinsein yoo gbe bi ko se ologbo?
2027.Tete opopo ti l’omi tele k’ojo too ro si.
2028.T’onjebi, t’onjare, ni nsan ‘wo epa.
2029.Teni nteni, t’ekisa nt’aatan.
2030.Tulaasi l’ohun o ba o joko, o ni ko s’aaye, bo se gongori imu re.
2031.Taani je f’obe to nu je ‘su?
2032.Taa l’a bi mo fun, ta l’amo jo?
2033.Ti ara ile eni ba f’ori lu, ti a ko ba mo pele se a maa di ‘ja.
2034.Ti onibo ko ba ku, enikan kii gba ‘bo re se.
2035.Temi to mi l’eru, ma di kun mi.
2036.Ti ‘ka lo soro.
2037.Ti ‘ka t’oore, okan kii gbe.
2038.Ta nfe a je, k’oto pe oo yo?
2039.Ta mo ti ‘ye da ‘so fun ni, a fi ko gba t’orun eni.
2040.Ta nfe anu, eniyan o fe ni f’oro ta nfe a ni?
2041.Tori ogun atehin ja, l’o mu pepeye k’omo re si waju.
2042.Taani njeun, t’aja nju ‘ru?
2043.Tipa tipa l’a fi ns’orire, pelekutu k’omo re si waju.
2044.Taaru yoo gba kanbo lowo imu?
2045.Ko si oro fun u.
2046.Wo so de mi, ko ni j’oniso.
2047.Won nin afoju fo ‘keeremu, o ni eyiti ko ye ko fo ti fo (iyen ni oju re)
2048.Won ni k’apa ‘se po k’a j’iyan ‘ko, enikan l’oun l’agba.
2049.Wahala ni t’agbe Olroun ni npe ki ‘su o ta.
2050.Were dun wo, ko see ni l’omo.
2051.Won fun o l’obi, o f’ewe si, o gbon bi enit o bun o?
2052.Won ni a j’ekuru ko tan, e tun ngbon ‘won re s’awo?
2053.Won ni o su, o ko nu ‘di, eni melo l’o fee fe di han?
2054.Won ti nf’ese ehin de ‘le.
2055.Won ni o waa jeun, o ko, o mo ‘se t’obe o ran o?
2056.Won na o l’egba mefa, o ni ko dun o, se bi ara re l’o wa.
2057.‘Wo o gba pe ehin mu j’abe lo.
2058.Were were ni ‘kan nje ‘le, b’ao ba ku l’ogun odun baba enikan ko lee gbe wa sin.
2059.Won – ran won – ran a maa ni ‘ran.
2060.Waa da ‘wo, waa ku ni o.
2061.Won ni ohun t;o wuni o wa, ohun t’o dara bo sibe ti o ba dara ti ko wu ni nko?
2062.Yoo se ko se, adura san j’epe lo.
2063.Yin ni, yin ni, k’eni lee se mii.
2064.Yoo bale, yoo bale, ni labalaba se ntori bo ‘gbo.
2065.Yoo dara ni, ko dara ni, eniyan pupa yoo wuyi lokeere.
2066.Yiyo ekun t’ojo ko.
2067.Yoyo l’enu araye nda.
E je kamo bi awon owe ati akanlo ede yoruba wonyi wulo fun o nipa kiko si isale.