Bi a ba wo oju opolopo awon omo orile-ede
Naijiria, a o ri orisirisi ila loju won. Ogooro eniyan ni ko mo idi re ti a fii
ko ila.
Nje
kini idi re ti a fi ko ila?
Idahun fun enikeni ti o ba se ibeere yi pin
si ona meji. Nigba laelae, ogun ati ote po ni orile –ede Naijiria.
Lakoko yi ni omo nsonu lairo-tele. Awon
alagbara nko awon omo eniti ko ni agbara bi ti won ta. Bi nwon ti n ko omo won
be ni nwon nko aya won paapaa. Beni opo gende (youth) nsonu, ti a nfi won se
awaari. Bi a ti nko won la n tawon leru fun awon orile-ede miran. Bi awon ti a
ta leru wonyi, yala lati idile kan naa tabi ilu kan naa ba pade, nwon ko ni mo
ara won rara. Sugbon awon agbalagba ronu pe o ye ki kini kan bi ami wa, eyi ti
nwon yoo fi maa mo ara won. Ti nwon o si le so lesekannaa ilu ti eniyan kan ti
wa ni kete ti aba rii. Ogbon ila kiko yi kii se ti gbogbo orile-ede yi ni lati
ibere bikose ohun ti awon eniyan orile-ede yi jogun lati Iwo-Orun nibi ti asa
naa ti koko bere.
Alaye keji fun ila kiko ni pe boya awon
eniyan Iwo-orun nibi ti asa yi ti bere ro pe yoo bukun ewa ara won nipa sise
bee. Bi a ba wo ju elomira ninu awon Okunrin tabi awon obinrin ti o ko ila, ao
rii pe ila naa dara pupo loju opolopo won. Dajudaju, asa lati bu si ewa ara ni
iru awon bee ka ila kiko si. “Bi a ko ba tori isu jepo, a o tori epo je isu”.
Bi a ba wo finnifinni, a o rii pe ila yi yato si ara won lati agbegbe si
agbegbe tabi ilu si ilu nibomiran. Awon Oyo nii ko orisirisi Abaja, Pele ati
Ture. Nwon tun nko Abaja meta-meta, tabi Gombo, Keke ati Gombo papo. Awon Ekiti
a bu meta-meta ti o gbooro, tabi eyo kan soso ti o gbooro, tabi meta oro lori
meta ibu ti o gbooro. Awon Egba ni nko meta-meta ti ko gun ti ko si gbooro.
Awon Ijebu a maa ko meta-meta tabi meta loke, meta ni isale re. Awon Owu naa
mbu Abaja, nwon si mbu Keke pelu. Pupo ninu awon Ife kii kola, sugbon awon
miran nko meta-meta nigba miran. Awon Ijesa nko mefa. Ondo nko meta-meta. Awon
Iyagba nko meta-meta ti o fere papo l’eba enu won.
Ogunlog ile la ti pa asa yi re, sugbon
opolopo idile wa ti ko fe fi asa yi sile rara. Lara awon apeere iru awon ila ti
awon Yoruba ma n ko niwonyi lati fi dawaloju pe awon ila wonyi yato si ara won
lati ilu ati ile si ara won.
ABAJA
Eyi ni awon ila meta ti a fa nibu lori ara
won tabi mefa ti a to ni meta-meta nibu bakanna.
ABAJA
MERIN
Iyato to wa laarin eleyi ati eyi to ea loke
yi ni pe. A bu ila toke ni meta-meta, sugbon a bu eleyi ni merin-merin.
ABAJA
ALAGBELE
Iru abaja eleyi ni a ma n bu si oju eniyan
ti a si tun gbe meta oro miran le lori.
PELE
Ila meta ti a fa sereke ti o duro looro. O
maa nye awon ti o ba bu ila bee. A si maa npe awon eniyan bee ni “peleyeju” fun
ewa tii fun won.
TURE
Ila meta kekeeke looro ati meta miran ti o
gun ju meta isaaju lo.
KEKE
TABI GOMBO
Awon ila ti o gun ti a fa lati ori wa ti o
si te woroko logangan aarin oju ati eti si isale eeke.
Gbogbo awon ila oju wonyi lati ekini (1)
titi de ekefa (6) lo wopo laarin awon omo Oyo, Ibadan, Ogbomoso, Ede, Iwo ati
Osogbo.
Awon ila miran tun wa ti o fi diedie yato
si awon ti o wa loke wonyi.
Opolopo won lo dabi abaja, keke, pele
sugbon nwon ko gbooro to abaja, keke ati pele awon Oyo.
Apere awon ila bee niiwonyi:
ABAJA
OLOWU
Ila meta oro ati meta ibu ni isale won.
KEKE
OLOWU
Eleyi yato si keke ti akoko. Siso ni keke
Olowu, bibu ni Keke Oyo.
PELE
IFE
Ila meata oro
ILA
ONDO
Eyokan soso ti o gun ti o si jinle ni
PELE
IJEBU
Ila meta ti o gun die ni
ABAJA
EGBE
Meta ooro ati meta ibu, ti a ko lori ara
won.
PELE
IJESA
Meta looro
ABAJA
IJESA
Merin ni ibu.
PELE
ATI ABAJA EKITI
Awon wonyi yato si pele ati abaja ti a ti
salaye soke nitori pe nwon gbooro pupo ju ti isaju lo.
ABAJA EKITIPELE KAN
PELE META
Thanks a lot.
ReplyDeleteYou are welcome
DeleteThanks a lot.
ReplyDeleteYou are welcome. Keep visiting for more
DeleteE se pupo, ede yoruba ko ni parun l'agbara Edumare.
ReplyDeleteAmin ooo. E se
DeleteE se pupo, ede yoruba ko ni parun l'agbara Edumare.
ReplyDeleteEku ise opolo. Opolo yin ko ni doba. Olorun a tun bo ma ran yin lowo o. Ese pupo.
ReplyDeleteAdupe pupo lowo yin, a mo loore
Deleteeku igbe asa Yoruba laruge, opolo yin o ni wookun, ejowo mo ni ibeere kan ni, awon ila won yii ni oni bi ati se maa n pe kiko won, apeere; sa keke, wa gombo, ati beebe lo, ejowo, kinni ti PELE?
ReplyDeleteOgbeni Ola, A ma n bu Pele ni.
DeleteAdupe pupo lowo yin fun imoriri yin
Enter your comment...adupe pupo opolo yin koni joba
ReplyDeleteAmin oooo
DeleteEse pupo nitoripe omomi ti wa ko si to e ma ri ere nibe
ReplyDeleteEse pupo fun idanileko.E o maa mo si
ReplyDeletePls show me ila Osun and where in Osun and the name of the ila
ReplyDelete