Tuesday 5 December 2017

Oriki



Asa kan Pataki ti awa omo Yoruba ngbe sonu bayi ni asa oriki. Orisirisi idile ni o ni oriki tiwon. Bi o ba je iya agba tabi baba agba, paapaa julo iya agba; bi omo re ba nlo si irnajo, tabi ki o ti irinajo de; tabi ki se nkan isiri kan; ohun ti o koko maa se ni ki o gba omo naa mu, ki o si kii deledele. Nigba ti o ba ki sile iya, a tun ki si ile baba.
Yato si gbogbo eleyi, awon oriki ile Yoruba wa ninu awon arofo ti o sunwon ju ohun ti a le gbo. Orisirisi itan ayeraye; orisirisi itan idile ati ibi ipilese olukuluku ni awon Yoruba sopo tin won si ti ri oriki won. Oriki je awon oro isiri ti awon Yoruba ma n fi yin ara won tabi eni ti inu won ba dun si. Asa yi ni a fi nda eniyan lara ya fun ohun rere to se tabi lati fihan eniyan nigbamiran pe inu wa dun si oluware. Bi eniyan ban se ise tabi o njo loju agbo, bi o ba gbo oriki re, ara re a ya gaga a si mura si ohun ti o ban se nigbana daradara.


Orisirisi ona la nki eniyan si. Bi a ti nki Oba bee la nki mekunnu pelu. A nki Oba bi ile ati agbara re ba ti to. A sit un le ki si owo ti o bay o nigba ti o gun ori ite oye. Iru oro tabi ayo oro ijinle bee ti o suyo ninu oruko eniyan tabi ise re laa npe ni oriki.
A le ki Oba bayi pe:
Kabiyesi Oba luwaye
Odundun asolu dero
Oba ade kile roju
Oba ade kile rorun
Arowolo bi Oyinbo
O fiile wu ni
O foona wu ni
Ogbigba ti ngba ara adugbo
Oba ataye ro bi agogo
Awon Yoruba tun gbadun lati maa fi oriki da eniyan laraya yala lojo igbeyawo ni, iwuye ni, ikomo ni, ile kiko ni tabi ohun ayo miran ti a nse lowo.
A le ki eniyan si oruko re, paapaa oruko amutorunwa bi apeere Idowu, Ige, Ojo, Dada, Ajayi ati bebe lo.
O ya e je ka wo oriki won lokookan:
Idowu la maa nki bayi pe:
Idowu ogbo
Ogbo asogede jia
Esa okun
Monganna aro, abikere leti
Esu lehin ibeji
Idowu eru ibeji, eketa omo.
Ige la maa nki bayi pe:

Ige adubi
Agbolenu bi agogo
Omo onigba irawo
Bi iya leku, ko ku
Bi baba le lo, ko maa lo
Elegede mbe loko
Gboro mbe laatan
Ohun Ige Adubi o je, ko nii won on
Ige ko roju iya
Oju baba lo ro
Ige iba roju iya
Ki ba kese sita
Eni be Ige Adubi nise
Ara re lo be.
Ojo la maa nki bayi pe:
Ojo olukori, Ojo Yeuge
Ojo olukori, ogede soomo gbagan gnagan
Ojo kure, alagada ogun
Ojo jengetiele
Ojo osi nle, omo adiye dagba
Ojo tajo de, omo adiye ku fenfe
Okinakina ti ntoju aladiye kii na
Ojo kenke bi ele
Esin rogun jo omo yeye ni
Ojo ajo ni ewe
Ojo ti new lodo, tomoge nnawo ose
Ojo sun nile ba ara re leru
Ojo akitikori, ajagun bi akura
Ojo ajowu bi eni jeran
Ojo alade igbo jingbinjingbin
Ojo abija bi eni tarin
Ojo ajagun loju ologun
Ojo agbogungboro, aranti oro ehin
Ojo arigbede joye
O fi gbogbo ara sode ekute
O fi obeke sode agbonrin o
O fi ako okuta sode erin
Ojo ababa-tiriba
Ojo elete ko gbodo pa loju eni
Amele ijakaki ija bi eni jagun aremabo
Ojo kurekure, alagada ogun
Dada la maa nki bayi pe:
Dada awuru yale, yagi oko
Olowo eyo, gbongbo ni ahoro
Asiso o lara
Otosi o niyekan
Dada ogbegun, irunmangala
Eran gbigbe o nijanja
Aladeleye, abisu jooko
Dada ogbegun
Mo rade yo obinrin
Gbon ori ade
Gbo ori esu siwaju
Dada ogbegun
Gbo ori oro sodo mi
Ajayi la nki bayi pe:
Ajayi, ogidiolu
Ololo, onikanga ajipon
Obomi osuuru weda
Ekun baba ode
Ekun pakoko wole
Eni Ajayi gba gba gba
Ti o le gba tan, Igunnugun nii gba oluware
Ajayi ti new lodo
Ti gbogbo omoge nyowo ose
Daramodu ose temi ni o gba
Ajayi a sin gbewa
Ajayi lerin oje, arowosoge
Ohun mira ti a tun se akiyesi nipa oriki nip e bi a se n ki okunrin bee la nki obinrin pelu. Ko si eni ti ko ni oriki tire ninu won. Awon oriki ti o je mo obinrin le suyo nipa oruko won tabi ile ti a ti bi won. Bi o ba je eyi ti o je mo idile ni, tokunrin tobinrin la o maa so oriki bee si, Fun idile ti a tin se egungun, a le ki won si egungun. Bi apeere ni
Omo Egungun
Omo Epa
Omo Oniyara ajeji ko le wo
Ajeji ti o wo ibe, o di eni ebo
A le ki okun tabi obinrin ti o ba je ibeji. Oruko amutorunwa naa ni ti won. Oriki won ko si soro pupo paapaa lenu awon abiyamo. A nki awon ibeji bayi pe:
Ejire okin, ara isokun
Yindin yindin loju orogun
Eji woro loju iya
Eji ng ba bi ng bay o
Omo ko ile alase
Wo o lopolopo a wo fi seerin
O so alakisa di alaso
Ejire Okin omo edun nsere ori igi

11 comments:

  1. Ha! e seun gidigidi fun Ise takuntakun ti e se yii, sugbon e daakun e fun wa ni oriki Olugbodi abika mefa naa ki gbogbo e le pe, perepere. E se pupo! Zhuraj Adesina nicestzhuraj@gmail.com

    ReplyDelete
    Replies
    1. Ogbeni Adesina, ese adupe lowo yin. A o sise lori oun ti ebere

      Delete
  2. Koda,ise nla lese. E fun was ni oriki etaoko

    ReplyDelete
  3. Eku ise takuntakun, olorun oba yo mafun yii se

    ReplyDelete
  4. Eku ise opolo, opolo yin koni daru

    ReplyDelete
    Replies
    1. Amin.
      Adupe pupo lowo yin ogbeni Olanrewaju

      Delete
  5. ESE OLOHUN a ma se alekun opolo yin fun eko ti enfi fun wa. Ameen

    ReplyDelete
  6. E jowo kini oriki idile Amele

    ReplyDelete