Asa kan Pataki ti awa omo Yoruba ngbe
sonu bayi ni asa oriki. Orisirisi idile ni o ni oriki tiwon. Bi o ba je iya
agba tabi baba agba, paapaa julo iya agba; bi omo re ba nlo si irnajo, tabi ki
o ti irinajo de; tabi ki se nkan isiri kan; ohun ti o koko maa se ni ki o gba
omo naa mu, ki o si kii deledele. Nigba ti o ba ki sile iya, a tun ki si ile
baba.
Yato si gbogbo eleyi, awon oriki ile
Yoruba wa ninu awon arofo ti o sunwon ju ohun ti a le gbo. Orisirisi itan
ayeraye; orisirisi itan idile ati ibi ipilese olukuluku ni awon Yoruba sopo tin
won si ti ri oriki won. Oriki je awon oro isiri ti awon Yoruba ma n fi yin ara
won tabi eni ti inu won ba dun si. Asa yi ni a fi nda eniyan lara ya fun ohun
rere to se tabi lati fihan eniyan nigbamiran pe inu wa dun si oluware. Bi
eniyan ban se ise tabi o njo loju agbo, bi o ba gbo oriki re, ara re a ya gaga
a si mura si ohun ti o ban se nigbana daradara.
Orisirisi ona la nki eniyan si. Bi a ti
nki Oba bee la nki mekunnu pelu. A nki Oba bi ile ati agbara re ba ti to. A sit
un le ki si owo ti o bay o nigba ti o gun ori ite oye. Iru oro tabi ayo oro
ijinle bee ti o suyo ninu oruko eniyan tabi ise re laa npe ni oriki.
A
le ki Oba bayi pe:
Kabiyesi Oba luwaye
Odundun asolu dero
Oba ade kile roju
Oba ade kile rorun
Arowolo bi Oyinbo
O fiile wu ni
O foona wu ni
Ogbigba ti ngba ara adugbo
Oba ataye ro bi agogo
Awon Yoruba tun gbadun lati maa fi oriki
da eniyan laraya yala lojo igbeyawo ni, iwuye ni, ikomo ni, ile kiko ni tabi
ohun ayo miran ti a nse lowo.
A le ki eniyan si oruko re, paapaa oruko
amutorunwa bi apeere Idowu, Ige, Ojo, Dada, Ajayi ati bebe lo.
O ya e je ka wo oriki won lokookan:
Idowu
la maa nki bayi pe:
Idowu ogbo
Ogbo asogede jia
Esa okun
Monganna aro, abikere leti
Esu lehin ibeji
Idowu eru ibeji, eketa omo.
Ige
la maa nki bayi pe:
Ige adubi
Agbolenu bi agogo
Omo onigba irawo
Bi iya leku, ko ku
Bi baba le lo, ko maa lo
Elegede mbe loko
Gboro mbe laatan
Ohun Ige Adubi o je, ko nii won on
Ige ko roju iya
Oju baba lo ro
Ige iba roju iya
Ki ba kese sita
Eni be Ige Adubi nise
Ara re lo be.
Ojo
la maa nki bayi pe:
Ojo olukori, Ojo Yeuge
Ojo olukori, ogede soomo gbagan gnagan
Ojo kure, alagada ogun
Ojo jengetiele
Ojo osi nle, omo adiye dagba
Ojo tajo de, omo adiye ku fenfe
Okinakina ti ntoju aladiye kii na
Ojo kenke bi ele
Esin rogun jo omo yeye ni
Ojo ajo ni ewe
Ojo ti new lodo, tomoge nnawo ose
Ojo sun nile ba ara re leru
Ojo akitikori, ajagun bi akura
Ojo ajowu bi eni jeran
Ojo alade igbo jingbinjingbin
Ojo abija bi eni tarin
Ojo ajagun loju ologun
Ojo agbogungboro, aranti oro ehin
Ojo arigbede joye
O fi gbogbo ara sode ekute
O fi obeke sode agbonrin o
O fi ako okuta sode erin
Ojo ababa-tiriba
Ojo elete ko gbodo pa loju eni
Amele ijakaki ija bi eni jagun aremabo
Ojo kurekure, alagada ogun
Dada
la maa nki bayi pe:
Dada awuru yale, yagi oko
Olowo eyo, gbongbo ni ahoro
Asiso o lara
Otosi o niyekan
Dada ogbegun, irunmangala
Eran gbigbe o nijanja
Aladeleye, abisu jooko
Dada ogbegun
Mo rade yo obinrin
Gbon ori ade
Gbo ori esu siwaju
Dada ogbegun
Gbo ori oro sodo mi
Ajayi
la nki bayi pe:
Ajayi, ogidiolu
Ololo, onikanga ajipon
Obomi osuuru weda
Ekun baba ode
Ekun pakoko wole
Eni Ajayi gba gba gba
Ti o le gba tan, Igunnugun nii gba
oluware
Ajayi ti new lodo
Ti gbogbo omoge nyowo ose
Daramodu ose temi ni o gba
Ajayi a sin gbewa
Ajayi lerin oje, arowosoge
Ohun mira ti a tun se akiyesi nipa oriki
nip e bi a se n ki okunrin bee la nki obinrin pelu. Ko si eni ti ko ni oriki
tire ninu won. Awon oriki ti o je mo obinrin le suyo nipa oruko won tabi ile ti
a ti bi won. Bi o ba je eyi ti o je mo idile ni, tokunrin tobinrin la o maa so
oriki bee si, Fun idile ti a tin se egungun, a le ki won si egungun. Bi apeere
ni
Omo Egungun
Omo Epa
Omo Oniyara ajeji ko le wo
Ajeji ti o wo ibe, o di eni ebo
A le ki okun tabi obinrin ti o ba je
ibeji. Oruko amutorunwa naa ni ti won. Oriki won ko si soro pupo paapaa lenu
awon abiyamo. A nki awon ibeji bayi pe:
Ejire okin, ara isokun
Yindin yindin loju orogun
Eji woro loju iya
Eji ng ba bi ng bay o
Omo ko ile alase
Wo o lopolopo a wo fi seerin
O so alakisa di alaso
Ejire Okin omo edun nsere ori igi