Monday 1 November 2021

Awon Aso Ile Yoruba

Aso awon Yoruba yato si amulumala ti a now ni ode oni. Awon okunrin ni aso tiwon, beni awon obinrin ni aso tiwon pelu. Opolopo as ni omode le lo ti ko si ye ki agbalagba wo iru re. Aye nyi a nto o. Aye ti di aye olaju. Ni akoko kan, ihoho omoluwabi ti a was aye naa ni a nrin kiri. Ki ise iran Yoruba ti o wa nibe yi lansor re sugbon iran awon baba nla baba wa. Ti nwon ba ti ri ohun kan bo idi won, oro ti buse.
Ni aye atijo ohun ti o se Pataki julo ti awon omode ati opolopo awon agbalagba ti o je agbe maa now ni ibante. Ibante yi, fun opolopo igba, aso kijipa ni a maa nfi ran an. Nwon maa nso okun meji sii ni igun mejeeji eyi ni a si maa nfi soo mo idi. Nigba ti a ba ti so okun meji ti o wa ni igun wonyi mo idi wa, a o wa la aso naa bo idi wa, a o si fi okun ti a so si igun re ni isale boo kun ti a so mo idi wa yika pelu iru ibante yi ni idi wa, ki a maa ba ise lo loko ni pereu loku.
Awon as miran ti awon okunrin maa n lo ni ile Yoruba bere lori aso egbejoda lo si asso ijade.
Dandogo
Okan lara awon aso ijade fun okunrin ni ile Yoruba ni dandogo je. Dandogo je aso ti o tobi pupo. Ti a bad a tan, o gbodo de orun ese, sugbon dipo ki o kun mo eniyan lara, pasoro ni o maa nse lo si isale. A kii la egbe dandogo de isale. Lati isale se enu ibadi a maa nran an pa ni a o wa ran apa mo o lati enu ibadi wa si ibi orun ewu naa; nitori idi eyi, apa dandogo maa nri pasoro bi ti ara ewu naa. Nwon maa n ko ona si aso yi lara niwaju ati lehin ati ni orun pelu. Eleyi ko je ki o roru fun awon aranso lati le ean an kiakia. Idi niyi ti a fi ma n pa lowe pe “Dandogo koja abinuda.”
Agbada
A le fi aso oke tabi aso oyinbo da agbada. Agbada tobi gan, sugbo ko soro lati da bi igba ti a ba fed a Dandogo. Ara agbada ko gbodo ri pasoro bi ara dandogo. Apa agbada si maa nla kanle gbooro ni. Nwon maa nfi opolopo abe bo inu agbada gege bi dandogo; a si maa nko ona sii niwaju ati l’orun ati lehin pelu. Awon agbalagba lo saaba maa nlo agbada; sugbo awon omode ti owo won ba ji sowo naa le lo agbada.
Gbariye
Okan lara awon aso Yoruba ni gbariye je. Aso ti o ba wu wa ni a le fi daa. O maa nde isale ese wa ti a ba ran an tan. Ko ni apa nla bi ti agbada tabi dandogo, a maa nse apo meji sii niwaju, a si maa nko enu apo naa daadaa. A ma nyo abe si gbariye daadaa, eleyi maa nje ki o kun mo wa lara gidigidi.
Sulia
Okan lara awon aso ijade Yoruba ni sulia je. Ohun ti o se Pataki nipa re nip e toke-tile ni a maa nfi iru aso bayi da. Looto, ewu re ni a npe ni sulia, sugbon ko si eni ti o le wo sulia laiwo awotele re ati sokoto soro re. Iru as kan naa ni a si gbodo fi ran awotele ati soro re.
Oyala
Eleyi da bi sulia sugbon ko tun tobi to sulia daadaa. O ye ki oyala naa ni awotele ati soro. Iru aso kanna ni o si ye ki a fi ran awotele ati soro ati oyala yi. Oyala naa, bi ti sulia, ko ni abe bi ti awon agbada ati dandogo.
Buba
Eleyi je aso ti a le wo, yala gegebi awotele tabi gegebi aso iwole fun ara re. Aso fulefule bi as oyinbo ni a saaba maa nfi ran buba. Buba le je olowo gigun tabi olowo kukuru. A maa nla buba laya, a o si fi botini bi ti awon aso ti oku, apa buba maa nse pooro.
Dansiki
Okan ninu awon aso ti a le wo gegebi awotele tabi ki a woo gegebi aso iwole fun ara re. Dansiki yi ni awon ara Ibadan maa npe ni esiki, o je ewu kekere ti a maa nla ni egbe meji lati yo abe jade. Ti a ba fe ki dansiki kun die, a le yo abe merin sii- meji niwaju, meji lehin.
Sokoto
Eleyi ni awon Yoruba maa now si idi nigba tin won ba ti wo aso tan. Orisirisi sokoto ni o si wa. Sanyinmotan ni sokoto akoko ta koko soro le lori. A maa nda sokoto yi koja orokun die, yoo si fun mo ese wa timotimo. A maa nllo iru sokoto yi ti a ba fe se ise kan tabi ti a ba fe lo si irin ajo ti a ko si fe ki sokoto nla ma yow a lenu.
Sokoto keji ti a o tun so nipa re ni a n pe ni soro ni ile Yoruba. Sokoto soro maa nde orun ese wa, enu re ko gbodo se yauyau; oun ni a si maa nlo si awon aso bi buba; sulia ati oyala.
Kembe tabi Abadan ni orisi sokoto miran ti a o tun menu ba. Sokoto kembe yi maa ntobi pupopupo lati isale, sokoto naa yoo maa tere sii titi yoo fi de orun ese nibi to o ti fun mo ese daadaa, Abe sokoto yi maa ntobi gidigidi nitori pea won aranso maa nran jagburu, ti a ba sig be omode pamo sinu sokoto yi, a feree le wa ti.
Efa ni orisi sokoto miran ti a ko gbodo mo menu ba, oun na si ma ntobi. Ni badi, o feere tobi to kembe. Abe efa ko nri jagburu bi abe kembe, sugbon ese efa ko nfun mo wa ni orun ese bi ti kembe. Awon agbalagba lo maa nlo iru sokoto yi nitori pea won omode ko feran sokoto ti o ba je labu bi iru eleyi mo.
Fila
Awon Yoruba ko gba pe eniyan ti wo aso bi omoluwabi bi o ba wo ewu ati sokoto lasan lai de fila. Lehin igba ti won ba ti de fila tan ni nwon sese le jade gegebi omoluabi.

Tuesday 5 December 2017

Oriki



Asa kan Pataki ti awa omo Yoruba ngbe sonu bayi ni asa oriki. Orisirisi idile ni o ni oriki tiwon. Bi o ba je iya agba tabi baba agba, paapaa julo iya agba; bi omo re ba nlo si irnajo, tabi ki o ti irinajo de; tabi ki se nkan isiri kan; ohun ti o koko maa se ni ki o gba omo naa mu, ki o si kii deledele. Nigba ti o ba ki sile iya, a tun ki si ile baba.
Yato si gbogbo eleyi, awon oriki ile Yoruba wa ninu awon arofo ti o sunwon ju ohun ti a le gbo. Orisirisi itan ayeraye; orisirisi itan idile ati ibi ipilese olukuluku ni awon Yoruba sopo tin won si ti ri oriki won. Oriki je awon oro isiri ti awon Yoruba ma n fi yin ara won tabi eni ti inu won ba dun si. Asa yi ni a fi nda eniyan lara ya fun ohun rere to se tabi lati fihan eniyan nigbamiran pe inu wa dun si oluware. Bi eniyan ban se ise tabi o njo loju agbo, bi o ba gbo oriki re, ara re a ya gaga a si mura si ohun ti o ban se nigbana daradara.


Orisirisi ona la nki eniyan si. Bi a ti nki Oba bee la nki mekunnu pelu. A nki Oba bi ile ati agbara re ba ti to. A sit un le ki si owo ti o bay o nigba ti o gun ori ite oye. Iru oro tabi ayo oro ijinle bee ti o suyo ninu oruko eniyan tabi ise re laa npe ni oriki.
A le ki Oba bayi pe:
Kabiyesi Oba luwaye
Odundun asolu dero
Oba ade kile roju
Oba ade kile rorun
Arowolo bi Oyinbo
O fiile wu ni
O foona wu ni
Ogbigba ti ngba ara adugbo
Oba ataye ro bi agogo
Awon Yoruba tun gbadun lati maa fi oriki da eniyan laraya yala lojo igbeyawo ni, iwuye ni, ikomo ni, ile kiko ni tabi ohun ayo miran ti a nse lowo.
A le ki eniyan si oruko re, paapaa oruko amutorunwa bi apeere Idowu, Ige, Ojo, Dada, Ajayi ati bebe lo.
O ya e je ka wo oriki won lokookan:
Idowu la maa nki bayi pe:
Idowu ogbo
Ogbo asogede jia
Esa okun
Monganna aro, abikere leti
Esu lehin ibeji
Idowu eru ibeji, eketa omo.
Ige la maa nki bayi pe:

Ige adubi
Agbolenu bi agogo
Omo onigba irawo
Bi iya leku, ko ku
Bi baba le lo, ko maa lo
Elegede mbe loko
Gboro mbe laatan
Ohun Ige Adubi o je, ko nii won on
Ige ko roju iya
Oju baba lo ro
Ige iba roju iya
Ki ba kese sita
Eni be Ige Adubi nise
Ara re lo be.
Ojo la maa nki bayi pe:
Ojo olukori, Ojo Yeuge
Ojo olukori, ogede soomo gbagan gnagan
Ojo kure, alagada ogun
Ojo jengetiele
Ojo osi nle, omo adiye dagba
Ojo tajo de, omo adiye ku fenfe
Okinakina ti ntoju aladiye kii na
Ojo kenke bi ele
Esin rogun jo omo yeye ni
Ojo ajo ni ewe
Ojo ti new lodo, tomoge nnawo ose
Ojo sun nile ba ara re leru
Ojo akitikori, ajagun bi akura
Ojo ajowu bi eni jeran
Ojo alade igbo jingbinjingbin
Ojo abija bi eni tarin
Ojo ajagun loju ologun
Ojo agbogungboro, aranti oro ehin
Ojo arigbede joye
O fi gbogbo ara sode ekute
O fi obeke sode agbonrin o
O fi ako okuta sode erin
Ojo ababa-tiriba
Ojo elete ko gbodo pa loju eni
Amele ijakaki ija bi eni jagun aremabo
Ojo kurekure, alagada ogun
Dada la maa nki bayi pe:
Dada awuru yale, yagi oko
Olowo eyo, gbongbo ni ahoro
Asiso o lara
Otosi o niyekan
Dada ogbegun, irunmangala
Eran gbigbe o nijanja
Aladeleye, abisu jooko
Dada ogbegun
Mo rade yo obinrin
Gbon ori ade
Gbo ori esu siwaju
Dada ogbegun
Gbo ori oro sodo mi
Ajayi la nki bayi pe:
Ajayi, ogidiolu
Ololo, onikanga ajipon
Obomi osuuru weda
Ekun baba ode
Ekun pakoko wole
Eni Ajayi gba gba gba
Ti o le gba tan, Igunnugun nii gba oluware
Ajayi ti new lodo
Ti gbogbo omoge nyowo ose
Daramodu ose temi ni o gba
Ajayi a sin gbewa
Ajayi lerin oje, arowosoge
Ohun mira ti a tun se akiyesi nipa oriki nip e bi a se n ki okunrin bee la nki obinrin pelu. Ko si eni ti ko ni oriki tire ninu won. Awon oriki ti o je mo obinrin le suyo nipa oruko won tabi ile ti a ti bi won. Bi o ba je eyi ti o je mo idile ni, tokunrin tobinrin la o maa so oriki bee si, Fun idile ti a tin se egungun, a le ki won si egungun. Bi apeere ni
Omo Egungun
Omo Epa
Omo Oniyara ajeji ko le wo
Ajeji ti o wo ibe, o di eni ebo
A le ki okun tabi obinrin ti o ba je ibeji. Oruko amutorunwa naa ni ti won. Oriki won ko si soro pupo paapaa lenu awon abiyamo. A nki awon ibeji bayi pe:
Ejire okin, ara isokun
Yindin yindin loju orogun
Eji woro loju iya
Eji ng ba bi ng bay o
Omo ko ile alase
Wo o lopolopo a wo fi seerin
O so alakisa di alaso
Ejire Okin omo edun nsere ori igi

Asa Isomoloruko

Asa isomoloruko je okan pataki ti a ko le ko danu ninu as Yoruba, id niyi ti awon Yoruba fi ya ojo isomoloruko yi si oto lai tele eto ti awon babanla wa ti fi lele. Bi ojo isomoloruko ti se Pataki to ni, sibesibe eto ati inawo re yato lati ilu si ilu. Bi aboyun ile ba bi tibi, tire, gbogbo ebi idile oko ati idile re ni yoo wa kii barika, e ku ewu omo. Orisirisi ibeere laa o maa gbo lati enu awon eniyan lati fi mo iru omo ti eni naa bi. Nwon a ma beere pe, ako (okunrin) ni tabi abo (obinrin).
Nibi ti aboyun ti nrobi ni agbalagba tin se akiyesi iru omo ati oruko ti o le je. Ona ti omo naa gba waye gba akiyesi pelu, yala ese lo fi jade ni tabi ori ni. Ise omo naa lehin ti a bi tan wa ninu akiyesi bakan naa. A o se akiyesi boya omo naa nsokun pupo loru tabi ko fe ki a ro oun ni ounje lori idubule. Bi o ba je omo ti nsokun pupo loru a o ma ape ni Oni, bi ko ba si fe ka ro oun lonje lori idubule, a o maa pee ni Oke. Bakan naa ni awon Yoruba maa nse akiyesi akoko ti a bi omo si. Eyi ti a ba bi ni akoko odun laa npe ni Bodunde tabi Abiodun. Eyi ti a ba bi lakoko ibanuje awon obi maa npe ni Remilekun, Dayo tabi Ehundayo. Eyi ti a bi lakoko ayo tabi igbadun awon obi la npe ni Adebayo, Adesola, Ayodeji, Bolaji, Bolanle ato bebe lo. Bi o ba si je omo ti a bi lehin ti iya omo naa ti se abiku titi, a o maa pee ni Ropo, Kokumo, Igbokoyi, Kosoko. Omo ti a bi si oju ona oko tabi oja tabi odo laa npe ni Abiona. Eyi ti a bi sinu ojo tabi lakoko ti ojo nro laa npe ni Bejide.
Gbogbo ohun lo ni akoko tire. Bee ni akoko wa fun isomoloruko. Ojo kesan ti a ba bi omokunrin ni a maa nso loruko, ojo keje ni ti omobinrin. Ojo kejo si ni ti awon ibeji. Iba je ako tabi abo, awon onigbagbo ati imole a maa so omo won loruko ni ojo kejo ti a ba bi omo. Eleyi wa ni ibamu pelu asa ati eto isin won. Ni igba atijo, iya omo tuntun ko gbodo jade tit a o fi se isomoloruko. Inu iyara ni iya omo naa yoo duro titi a o fi ko omo naa jade. Ojo isomoloruko yii ni iya omo yoo gbe omo jade, yoo si joko sarin gbogbo ebi. Eto nipa akiyesi akoko, ipo ati irin ti omo naa rin yoo ti pari ki a to se isomoloruko yi. Awon miran ko asa ati maa se iwadi tabi ayewo si oruko ti o ye ki omo tuntun maa je.
Ni ibomiran, lehin ti gbogbo ebi ati ojulumo ba pe jo tan, iyale ile naa yoo bu omi si ori orule, yoo si fi ara omo tuntun naa gba osooro omi tin san ti ori orule bo. Bi omo tuntun ba ti fi ara gba omi yi tan ni yoo kigbe bi ti ojo ti a bii si aye. Gbogbo ebi yoo bu serin, nwon o pariwo pe omo tuntun, o ku atorunbo, aye dun, bawa je o. Ni kete ti a ba se eyi tan ni bale ile yoo gba omo na, yoo si se alaye bi omo naa se was aye, iru akoko ti omo naa wa si aye boya akoko ayo ni tabi ibanuje fun awon obi re.
Baale ile yoo maa mu awon ohun tie nu nje ti a ti pese sile gegebi orogbo , iyo, oyin, omi tutun ati oti tabi ohun miran ti a ban lo ni idile naa lati fi se adura fun omo naa. Awon oruko miran ti a tun le fun awon omo lehin ti a ba ti wo idile re niyi:
Fun Idile Ola:
Afolabi, Olabode, Olaleye, Afolalu, Olarewaju, Olabisi, Olaitan Ajibola, Popoola, Ladigbolu, Agboola, Ojuolape, Olawoyin, Kolawole, Lakanmi, Oladipo ati bebe lo.
Fun Idile Alajagun:
Akinwande, Akinyemi, Akinbode, Akinsanya, Akinlotan, Akinola, Akinwumi, Akintola at bebe lo
Fun Idile Oloye:

Oyediran, Oyewumi, Oyeyemi, Oyekanmbi, Oyetusa, Oyenike, Olowofoyeku, Oyegbenga ati bebe lo.
Fun Idile Alade:
Adekanmi, Adegbite, Adesina, Aderemi, Adeniyi, Adelabu, Adegoke, Adesoji, Ademola, Adebiye, Adedoyin Adesida, Adeyefa, Adeyemi, Atilade, Adegboye ati bebe lo.
Fun Idile Awo:
Awolowo, Awosika, Awotoye, Fasuyi, Fajuyi, Fagbemi, Odutola, Fayose, Fabunmi, Fadahunsi, Fakunle ati bebe lo.
Fun Idile Ode:
Odewale, Odeyemi, Odesanmi, Odewumi, Odegbenro, Odesakin, Odesiyan ati bebe lo.

Fun Idile Oloogun:
Ogundele, Ogunde, Ogunmola, Ogungbade, Ogunbiyi, Ogunsola, Ogundeji ati bebe lo.
Fun Idile Oloosa:
Osagbemi, Osunremi, Osunbiyi, Osunluyi, Osuntokun, Omitade, Efunkemi, Aborisade Abegunde, Aborode, Omiremi ati bebe lo.
Fun Inagije tabi Apeje:
Jegede, Omodara, Jeje, Okonrin-jeje, Logunleko, Afelebe ati bebe lo.
Fun Abiku Omo: Matanmi, Igbekoyi, Kosoko, Akinsatan, Kokumo, Bamitale, Lambe ati bebe lo.
Fun obinrin ti a po toju re: Aduke, Abike, Apeke, Amoke, Apinke, Abeke, Alake, Akanke, Arike, Ajoke ati bebe lo.
Gbogbo awon ona wonyi laa gbodo wo ki a to so omo loruko. Igbagbo awon Yorubqa nip e bi omo ba si oruko je ko ni gbadun. Eyi nip e yo maa yo iya ati baba re lenu nipa sise aisan tabi dida wahala miran kale. Idi niyi ti owe kan lede Yoruba fi so pe “Ile laa wo ka to somo loruko.”

Asa Igbeyawo ni Ile Yoruba

O je ohun Pataki fun okunrin tabi obinrin lati se igbeyawo ni igba atijo. Ni igba ti a ba gbadura fun eniyan ni ile Yoruba pe yoo se anfaani, ibi ti anfaani yoo ti bere ni ibi igbeyawo. Bi eniyan kan ba wa ti ko ba fe aya nigba ti gbogbo awon egbe re nfe aya, oju ko ni kuro lara re, enu ko si ni kuro lara re pelu; gbogbo or ti awon eniyan ba sin so sii ni yoo ma toka sii pe ko ye ki eniyan ya apon (apon ni okunrin to ti to ni aya, sugbon to ko lati ni aya). Gege bi owe awon Baba wa to so wipe bi ko ba nidi obinrin ki je Kumolu; bi ko ba ni idi, eniyan ki ded ya apon. Idi re niyi ti o fi je wipe gbogbo awon ti o ba ti ya apon ni nwon ma n fi ilu sile ni atijo, paapaa tie nu ba poju lara won.
Gbogbo iriri ti a n ri lode oni ti fiha w ape eniyan le ya apon ti o ba wuu, nitori bi o ba se wu eni ni a se nse imale eni.
IFOJUSODE
Nigba ti odomokunrin kan ba ti balaga, awon obi re yoo ti bere si fi oju sile boya nwon a le ri omobinrin kan tin won yoo fe fun omo won. Omokunrin yi paapaa laije pe enikeni so fun un, yoo bere si se finnifinni ju ti ateyinwa lo; yoo we nigba meta loojo, yoo toju eyin, enu, eekanna owo ati tese, gbogbo ara yoo si maa jolo. Ni kete ti okunrin ba fi oju kan wundia (omobinrin ti ko ti mokunrin) ti o je oju ni gbese, ise wa di ti alarina.
ALARINA
Alarina ni eni ti o ngbokegbodo laarin omokunrin ati omobinrin ti wo ba ni ife si ara won. Awon obinrin lo saba maa nsise yi daradara. Ise alarina ni lati wa idi ohun gbogbo kinnikinni nipa omobinrin yi. Idi re ti a fi nwa idi ni wipe ko si eni ti yoo fe gbe eni ti won n dete ni idile won, tabi iran asinwin, tabi obinrin onijagidijagan ni iyawo. Ise alarina ni lati pon ati lat ge omokunrin yi loju omobinrin ki o si la oju agi si agi (yoo seto bi omokunrin yoo se pade omobinrin).
ISIHUN TABI IJOHEN
Leyin igba ti alarina ba ti la oju awon mejeeji kan ara won, omokunrin ati omobinrin yi yoo bere si pade ni orisirisi ibi (labe igi odan nigba osupa, ni eyin ilea won omobinrin). Leyi igba ti won ba ti se eleyi fun igba pipe, omobinrin yoo wa je hoo fun lati gba beni yoo so fun omokunrin ki o seto bi baba ati iya oun yoo se gbo nipa ore won. Gbigba ti omobinri gba yi ni awa Yoruba npe ni Ijohen tabi Isihun.
ITORO
Leyin igba ti omobinrin ba ti juwo sile patapata, omokunrin yoo lo so fun baba re pe oun ti ri ododo kan ti o pupa, ti o si lewa ni ile Lagbaja tabi Lakasogbe ti oun fe ja. Baba re yoo wa bi lere boya ododo naa yoo see ja tabi ko ni see ja. Omokunrin naa yoo wa so gbogbo adehun ti oun ati omobinri yi ti se fun ara won. Eyi ni yoo fun baba re ni anfani lati lo baa won agbaagba adugbo re soro gegebi won yo se lo toro omo. Ni igba kini tin won yoo lo ri baba omobinrin, baba omokunrin ati omo ile kan tabi meji ni yoo lo. Owuro kutu hai ni nwon si maa nrin iru irin yi. Nwon o ko, nwon yoo sir o fun baba omobinrin. Oro yi ko ni je kayefi si baba omobinrin yi notori o ti bere si ri irin ese omo re. Idahun ti baba yi yoo si fun awon wonyi nip e kii se oun nikan lo bimo yi ati pe kin won wa pade molebi oun ni ojo bayibayi.
IDANA
Leyin igba ti won ba ti toro omo tan, idana ni gbogbo won yoo fi okan si. Gbogbo awon ti o ye kin won gbo nipa itoro ti nwon ko gbo, ati gbogbo awon ti o gbo ti won ko ri aye lo, akoko niyi lati fi owo si. Awon idile mejeeji yoo ranse si awon eniyan won nibikibi ti nwon ba wa. Idana yi se Pataki pupo nitori ibe ni awon idile mejeeji ti maa npade lekunrere. Ni ojo idana yi awon iyawo baba omobinrin ati iyawo baba omokunrin yoo pagbo ere, olukuluku won yoo maa ki oko won. Owuro kutukutu tabi irole patapata ni a nse idana. Lati ile omokunrin ni nwon ti maa ru gbogbo ohun idana wa.
AWON OHUN IDANA
Oyin, ireke ati iyo – eyi nip e aye won a dun; obi ati orogbo- eyi nip e nwon yoo gbo (dagba), atare- eyi nip e iyawo yoo bimo pupo; epo- eyi ni wipe yoo de won lara. Leyin eyi ni nwon yoo war u opolopo emu ati opolopo oti oyinbo fun mimu awon ti o wa sibi aseye naa. Gege bi asa Yoruba, eni ti o dagba ju nile iyawo yi ni yoo fa iyawo le eni ti o dagba ju ni ile oko lowo. Yoo si ka awon iba die funn alagba yip e nwon kii na omo won; ebi kii pa, kii je gbaguda (ege) ati beebee lo.
IPALEMO
Eyi tio ku ni ki iyawo maa pa ile re mo diedie leyin ti won ti dana tan. Ona meji ni oko iyawo le gba lati ran iyawo re lowo lati palemo. Ona kini, oko iyawo le fun iyawo re ni owo lati pese as ati yeti ti yoo maa lo ni ile oko. Ona keji ni ki oko be eniyan fun ara re lati ra gbogbo awon nkan wonyi, ki o si lo gbe e fun iyawo re lodidi.
E ma je ka gbagbe wipe isise kookan ti iyawo bag be lati gba fun oko re ni yoo ti gba owo. Iyawo ni lati gba owo idegiri. Owo idegiri je okan lara asa Yoruba,  nigba ti alarina ba sese la oju awon mejeeji kan ara won, obinrin kii le wo oju  okunrin, dipo bee, ile ni yoo maa wo, yoo si maa fi owo wa nkan ti ko junu lara ogiri. Eyi ni awon eniyan ri, tin won maa nwi pe iyawo nde ogiri ati wipe o si gbodo gba owo re lowo oko re.
Nigba ti iyawo ba si je hoo fun oko re, o ni lati gba owo isihun. Yato si orisirisi owo wonyi, opolopo owo miran ni awon obinrin ile iyawo tun maa ngba. Nwon ngba owo isilekun, eyi ni pe awon oko iyawo mbo, awon lo silekun; nwon ngba owo wiwe, eyi ni pea won lo we iyawo lojo idana. Leyin igba ti oko iyawo ba ti san awon owo wonyi leseese ni won yoo wa mu ojo igbeyawo.
IGBEYAWO
Igbeyawo ma nyato lati agbegbe si agbegbe; lati ilu kan si ilu keji ati lati ileto si ileto. Sugbon, awon nkankan wa ti o je pe ko le yato niwon igba ti o ba ti je ile Yoruba ni a ti n se igbeyawo naa. Ni oju ale patapata ni iyawo maa nlo si ile oko re. Ni ojo igbeyawo yi, ati ile iyawo ati ile oko, ojo ti o yato ninu ojo nii se. Gbogbo awon eniyan oko iyawo ati eniyan iyawo ni yoo ti maa fun won ni ebun.
Nigba ti iyawo ba fe kuro ni ilea won obi re, gbogbo awon obi re ati awon ibatan obi re ni yoo pejo. Olori idile won ni yoo si saaju lati gbadura fun iyawo naa pelu omije loju, iyawo naa yoo maa se amin pelu omije, gbogb ile a si maa gbadura fun omidan yi leselese pelu omije. Yoruba ma n pe ekun ti awon to n gbadura fun iyawo n sun ni isun idagbre ti won si ma n pe ekun ti iyawo nsun ni ekun iyawo.
Nigba ti iyawo ba ti nsunmo ile oko re, oko re gbodo jade ni ile nitori eewo ni ni ile Yoruba ki iyawo ba oko re ni ile. O je asa ni awon agbegbe kan lati pa ohun eleje si ese iyawo ki o to wo ile oko re. Sugbon ki iyawo to wo ile oko re ni awon agbegbe miran, a gbodo fi omi we ese re ni enu ona. Nigba ti iyawo ba wole gbara, odo olori idile ni nwon yoo muu lo. Ibe ni a o ti sure fun un.
Asa Yoruba ni ki oko sunmo iyawo re ni ale ojo keta lati mo boya o ti mo okunrin kan tele tabi ko mo okunrin rara. Ti iyawo ba ti mo okunrin, oro itiju patapata ni fun ohun ati molebi re, paapaa julo iya re. Sugbon bi iyawo ko ba ti mo okunrin kan tele, gbara ti oko iyawo ti se tan ni ariwo yoo ti so ni ile won. Awon ara ile won yoo si ko ere lo si ile baba iyawo ti won yoo si maa sajoyo pea won ba omo won nile.

Sunday 9 October 2016

ASA IKINI NI ILE YORUBA: KIKI NI ILE YORUBA

Ikini tabi kiki ni  ni ile Yoruba je ohun pataki ninu asa ile Yoruba. Awon Yoruba ko gba omo won laaye lati hu iwa omugo Kankan. Awon Baba wa bo, won ni “bi a ba bi omo ni ile ogbon, o gbodo moiran wo”.   Omo ti o ba ji loowuro lodo agabalagba ti ko si mo ohun ti o lati se yoo gba abuku. Sugbon omo ti o ji ti o ti ki gbogbo ara ile, ti o ki baba, ti o ki iya, eleyi ti kogo ja gege bi omo Yoruba gidi. Asa ikini je asa ti awon Yoruba fi nko ara won ti ko si se gba lowo eni ti a ba fi asa naa to dagba.
Bi a ba se akiyesi iran Hausa daradara, nse ni won ma n wole ki baba tabi iya won. Bi a ba si wo bi iran Ibo ti n ki baba tabi iya won, nse ni won ma ate ori ba laasan bi o se okunrin tabi obinrin won. Sugbon bi a ba wo iran omo Yoruba lookunrin nibi ti o ti n ki bab, iya tabi agbalagba, pelu idobale gbooro ni. Nwon a na ese, nwon a si faya bale, nwon a si ni “e kaaro oo”. Baba tabi iya naa yoo dahun pe “Pele o, Aremu omo Akin, o kaaro, o o jire bi?” Omokunrin ko ni kuro lori idobale titi baba tabi iya re yoo fi dake. Asa yi ti mora to be ti a fi npe awon omo Yoruba ni “Omo e kaaro, e o jii re?”
Bi o tise Pataki fun omokunrin lati ki baba tabi iya re loowuro naa lo je dandan fun omobinrin lati ki baba tabi iya loowuro bi won ba ji. Idobale ni ti omokunrin sugbon ori ikunle laa mba omobinrin. Omobinrin a kunle, a si wipe baba tabi iya, e ku aaro o. Baba tabi iya yoo dahun pe, “Apeke mi, omo Ekun to fin toritori, se daradara lo ji o?” Omobinrin gbodo duro soori ikunle naa tit obi re yoo fi pari kiki re.
Owuro nikan ko la nki eniyan ni ile Yoruba. Bi a ti n ki ara wa ku aaro, e ji re, bee laa nki ara w ape, ‘E ku osan’, ni deede agogo mejila si meji osan; ‘E ku irole ni deede agogo merin si mefa’; ‘E ku ale ni deede agogo meje ale si monkanla’. Ohun kan ti o se Pataki ninu asa ikini Yoruba ni wipe, bi o se aaro, osan, irole ati ale ni, pelu idobale fun omokunrin ati ikunle fun omobinrin la n ki awon to ba ju ni lo. Yato fun ikunle, eyi ti o wopo laarin awon omobinrin, awon kan tun wa ninu awon Yoruba t ii fi ori bale bi nwon ba nki ni. Asa iforibale tabi kaa fori ba iganna tabi igi nigba ti oju ba nkan ni yi wopo pupo laarin awon Ekiti.
Awon oyo lo ni ikunle, Ekiti lo ni iforibale. Sugbon bayi, asa iforibale yi ti n kasenile, gbogbo awon omobinrin ile Yoruba ni o maa nkunle ki awon asaaju won. Awon Yoruba tun ki ara won nigba tin won ba fe lo sun ni ale. Akoko yi ni a ma ngbo pe ‘O daaro o, ki Olorun ji wa re o, kaa ma toju orun doju iku o, tabi laayo la o ji o’.
Awon ikini Pataki miran tun wa fun igba otooto, yala ninu odun tabi fun isele ayo ati ti ibanuje. Ni igba eerun a ma nso pe, ‘e ku eerun yi, eku ogbele yi e ku ooru yi’. Ni igba ojo a maa nki nip e ‘e ku ojo yi, ku oginnitin yi tabi e ku otutu yi’. Bi o ba je akoko ti onje won ni a maa nki eniyan pe, e ku iyan, e ku aheje tabi e ku owon onje yi. Bi o ba si je akoko ti onje po ni a maa nki nip e, ‘e ku opo onje, e kun mudun-mudun, e ku imuje, e ku iwasaya’. Awon Musulumi ti n gbawe la nki pe e ku ongbe, e ku ise laada.
Orisirisi ona lo wa ti a ngba ki awon eniya ni ile Yoruba. Sugbon ma menu ba die ninu re.
A. Aboyun ile laa nki pe:
                                    E ku idura.
                                    Isokale anfani.
                                    Afon a gbo ko to wo o.
                                    A o gbo ohun iya, a o gbo tomo o.
                                    Tibi tire le o bi o.
                                    Abiwere o.
                                    Eku o ni gbo, eye o ni mo o.
B. Bi aboyun ba sese bimo re, a o ki pe:
                                    Barika, e ku ewu omo.
                                    Omo tuntun, o ku atorunbo.
                                    Mo yo fun yin o.
                                    Oluwa yoo da omo si, Oluwa yoo wo.
                                    Eku owo lomi.   
                                    Yoo loowo rere lehin.
                                    Yoo se omo kale.
                                    Oluwa a somo ni bantale.
                                    Eku owo losun o.
D. Eni ori ko yo ninu ewu la nki pe:
                                    Barika, e ku orire.
                                    E ku ewu.
                                    E ku inu ire.
                                    Bi o ba ku, ki Olorun yo ni.
E. Bi omo-owo tabi omode ba jalaisi, a o ki awon obi re pe:
                                    E pele.
                                    E ku amu-mora naa.
                                    Omi lo danu.
                                    Oluwa o nijagbe o fo
                                    Oluwa yoo pese bantale.
                                    Oluwa yoo pese ti elemi gigun.
                                    Oluwa yoo se dada miran.
                                    Olorun a so ibanuje dayo fun yin.
E. Bi odomode ba ku ninu ewu moto, iji, efuufu tabi ti ina, a o ki awon obi tabi ara re bayi pe:   
                                    E pele o, e ku ara fera ku.
                                    E ku ajalu.
                                    E ku iroju.
                                    E ku ofo.
                                    E ku afimora naa.
                                    Olorun yoo fi mo bayi.
                                    Olorun yoo ti ilekun ibanuje.
                                    Olorun o ni je ka ri iru eyi mo.
                                    Ojo a jina si ara won.
                                    Emi a jina semi o.
F. Bi enikan ba wa ninu ejo tabi aisan, a o ma kii pe:
                                    E ku wahala.
                                    E ku rigboriye.
                                    Ori a ko o yo.
                                    Inu rere a ko o yo.
                                    Edumare a da o lare.
G. Bi enikan ba padanu ohun ini re sinu ewu ina tabi effufu, a o ma kii pe:
                                    E pele o.
                                    E ku ofo.
                                    E ku adanu.
                                    Ki Oluwa fofo ra emi.
                                    Olorun ko ni je ka riru re mo.
                                    Olorun yoo fi mo be.
GB. Bi baba tabi iya to lojo lori ba ku, a o ma ki awon omo re pe:
                                    E ku aseyinde
                                    E ku inawo.
                                    E ku idele.
                                    Eyin baba tabi iya a dara.
                                    Olorun a basiri o.
                                    Baba tabi Iya a fohun rere paroko.
                                    Baba tabi Iya a moore.
I. Eni to sese kole tan to nsi i la n kip e:
                                    E ku inawo ile yi.
                                    Emi a lo o.
                                    Oluwa ko ni se e ni akota.
                                    Tire tomo ni o lo ile yi.
                                    Ile a tura o.
                                    E o ko eyi to ju yi lo o.
Bi a ti nki awon eniyan si ohun to sele naa la nki won si ohun ti won nse lowo. Ma menu ba die ninu orisirisi ona ti a ngba ki eni to n sise lowo.
A. Awon Agbe la ma n ki pe: Aroko boodun de tabi owo a ya o.
B. Awon Akope tabi Agunpe la ma nki pe: Igba a ro o tabi Emo o
D. Awon Atuko tabi Awako la ma nki pe: Oko a refo o.

E. Awon Alaro la ma nki pe: Aredu o, Areye o tabi Amugbe, ti won a si dahun pe Olokun a gbe o.
E. Awon Onidiri la ma nki pe: Oju gbooro, ti won a si dahun pe Ooya o, Iya moja a gbe o.
F. Awon Babalawo la manki pe: Aboru-boye o, ti won a si dahun pe Aboru-boye bo sise, Ifa a gbe o.
G. Awon Ode la ma nki pe: Arepa ogun, ti won a si dahun pe Arepa ntogu.
GB. Awon Alagbede la ma nki pe: Aroye o tabi Owu a ro o, ti won a si dahun pe Ogun a gbe o.
Iteriba ati iyesi ti awon Yoruba ni ni won fi ma n ki oba ati oloye, die ninu ba ti n ki wo niwonyi:
A ma n ki oba pe:
                               Kabiyesi, alase ekeji orisa.
                               Kia de pe lori.
                               Ki bat ape lese.
                               E o je ju ara iwaju o.
Awon Oloye la nki pe:
                               Ebo a fin o
                               Eru a da
                               Baba re a gbe e o.
                               E ku eto ilu.
Ori awon oba ati oloye ma n ya bi a ba nki won bayi, nitoripe a fi han pe a mo riri ipo won. Bi a ba farabale wo daadaa, a o ri wipe kikini lede Yoruba ko lopin be si ni idahun wok o si lonka. Asa yi ti wa di ajebi, ko si ohun ti o le gba a sonu lowo wa, bi o tile je wipe opo omo bibi ile Yoruba lo ti n te asa na mere sugbon “igbo kii di ka a ma mo Iroko, oja kii di ka a ma mo afin.” Bi o ti wu ki oju la to, a ko ni saimo omo Yoruba tooto lawujo nibi won gbe nki ni.