Tuesday 25 November 2014

ASA ILA KIKO NI ILE YORUBA

Bi a ba wo oju opolopo awon omo orile-ede Naijiria, a o ri orisirisi ila loju won. Ogooro eniyan ni ko mo idi re ti a fii ko ila.
Nje kini idi re ti a fi ko ila?
Idahun fun enikeni ti o ba se ibeere yi pin si ona meji. Nigba laelae, ogun ati ote po ni orile –ede Naijiria.
Lakoko yi ni omo nsonu lairo-tele. Awon alagbara nko awon omo eniti ko ni agbara bi ti won ta. Bi nwon ti n ko omo won be ni nwon nko aya won paapaa. Beni opo gende (youth) nsonu, ti a nfi won se awaari. Bi a ti nko won la n tawon leru fun awon orile-ede miran. Bi awon ti a ta leru wonyi, yala lati idile kan naa tabi ilu kan naa ba pade, nwon ko ni mo ara won rara. Sugbon awon agbalagba ronu pe o ye ki kini kan bi ami wa, eyi ti nwon yoo fi maa mo ara won. Ti nwon o si le so lesekannaa ilu ti eniyan kan ti wa ni kete ti aba rii. Ogbon ila kiko yi kii se ti gbogbo orile-ede yi ni lati ibere bikose ohun ti awon eniyan orile-ede yi jogun lati Iwo-Orun nibi ti asa naa ti koko bere.
Alaye keji fun ila kiko ni pe boya awon eniyan Iwo-orun nibi ti asa yi ti bere ro pe yoo bukun ewa ara won nipa sise bee. Bi a ba wo ju elomira ninu awon Okunrin tabi awon obinrin ti o ko ila, ao rii pe ila naa dara pupo loju opolopo won. Dajudaju, asa lati bu si ewa ara ni iru awon bee ka ila kiko si. “Bi a ko ba tori isu jepo, a o tori epo je isu”. Bi a ba wo finnifinni, a o rii pe ila yi yato si ara won lati agbegbe si agbegbe tabi ilu si ilu nibomiran. Awon Oyo nii ko orisirisi Abaja, Pele ati Ture. Nwon tun nko Abaja meta-meta, tabi Gombo, Keke ati Gombo papo. Awon Ekiti a bu meta-meta ti o gbooro, tabi eyo kan soso ti o gbooro, tabi meta oro lori meta ibu ti o gbooro. Awon Egba ni nko meta-meta ti ko gun ti ko si gbooro. Awon Ijebu a maa ko meta-meta tabi meta loke, meta ni isale re. Awon Owu naa mbu Abaja, nwon si mbu Keke pelu. Pupo ninu awon Ife kii kola, sugbon awon miran nko meta-meta nigba miran. Awon Ijesa nko mefa. Ondo nko meta-meta. Awon Iyagba nko meta-meta ti o fere papo l’eba enu won.
Ogunlog ile la ti pa asa yi re, sugbon opolopo idile wa ti ko fe fi asa yi sile rara. Lara awon apeere iru awon ila ti awon Yoruba ma n ko niwonyi lati fi dawaloju pe awon ila wonyi yato si ara won lati ilu ati ile si ara won.

ABAJA
Eyi ni awon ila meta ti a fa nibu lori ara won tabi mefa ti a to ni meta-meta nibu bakanna.

ABAJA MERIN
Iyato to wa laarin eleyi ati eyi to ea loke yi ni pe. A bu ila toke ni meta-meta, sugbon a bu eleyi ni merin-merin.
ABAJA ALAGBELE
Iru abaja eleyi ni a ma n bu si oju eniyan ti a si tun gbe meta oro miran le lori.

PELE
Ila meta ti a fa sereke ti o duro looro. O maa nye awon ti o ba bu ila bee. A si maa npe awon eniyan bee ni “peleyeju” fun ewa tii fun won.

TURE
Ila meta kekeeke looro ati meta miran ti o gun ju meta isaaju lo.

KEKE TABI GOMBO
Awon ila ti o gun ti a fa lati ori wa ti o si te woroko logangan aarin oju ati eti si isale eeke.
Gbogbo awon ila oju wonyi lati ekini (1) titi de ekefa (6) lo wopo laarin awon omo Oyo, Ibadan, Ogbomoso, Ede, Iwo ati Osogbo.
Awon ila miran tun wa ti o fi diedie yato si awon ti o wa loke wonyi.
Opolopo won lo dabi abaja, keke, pele sugbon nwon ko gbooro to abaja, keke ati pele awon Oyo.
Apere awon ila bee niiwonyi:
ABAJA OLOWU
Ila meta oro ati meta ibu ni isale won.

KEKE OLOWU
Eleyi yato si keke ti akoko. Siso ni keke Olowu, bibu ni Keke Oyo.

PELE IFE
Ila meata oro

ILA ONDO
Eyokan soso ti o gun ti o si jinle ni

PELE IJEBU
Ila meta ti o gun die ni

ABAJA EGBE
Meta ooro ati meta ibu, ti a ko lori ara won.

PELE IJESA
Meta looro

ABAJA IJESA

Merin ni ibu.

PELE ATI ABAJA EKITI
Awon wonyi yato si pele ati abaja ti a ti salaye soke nitori pe nwon gbooro pupo ju ti isaju lo.
                                                                   ABAJA EKITI

                                                                        PELE KAN

                                                                      PELE META

16 comments:

  1. E se pupo, ede yoruba ko ni parun l'agbara Edumare.

    ReplyDelete
  2. E se pupo, ede yoruba ko ni parun l'agbara Edumare.

    ReplyDelete
  3. Eku ise opolo. Opolo yin ko ni doba. Olorun a tun bo ma ran yin lowo o. Ese pupo.

    ReplyDelete
  4. eku igbe asa Yoruba laruge, opolo yin o ni wookun, ejowo mo ni ibeere kan ni, awon ila won yii ni oni bi ati se maa n pe kiko won, apeere; sa keke, wa gombo, ati beebe lo, ejowo, kinni ti PELE?

    ReplyDelete
    Replies
    1. Ogbeni Ola, A ma n bu Pele ni.
      Adupe pupo lowo yin fun imoriri yin

      Delete
  5. Enter your comment...adupe pupo opolo yin koni joba

    ReplyDelete
  6. Ese pupo nitoripe omomi ti wa ko si to e ma ri ere nibe

    ReplyDelete
  7. Ese pupo fun idanileko.E o maa mo si

    ReplyDelete
  8. Pls show me ila Osun and where in Osun and the name of the ila

    ReplyDelete