Ikini tabi kiki ni ni ile Yoruba je ohun pataki ninu asa ile
Yoruba. Awon Yoruba ko gba omo won laaye lati hu iwa omugo Kankan. Awon Baba wa
bo, won ni “bi a ba bi omo ni ile ogbon, o gbodo moiran wo”. Omo ti
o ba ji loowuro lodo agabalagba ti ko si mo ohun ti o lati se yoo gba abuku.
Sugbon omo ti o ji ti o ti ki gbogbo ara ile, ti o ki baba, ti o ki iya, eleyi
ti kogo ja gege bi omo Yoruba gidi. Asa ikini je asa ti awon Yoruba fi nko ara
won ti ko si se gba lowo eni ti a ba fi asa naa to dagba.
Bi a ba se akiyesi iran
Hausa daradara, nse ni won ma n wole ki baba tabi iya won. Bi a ba si wo bi
iran Ibo ti n ki baba tabi iya won, nse ni won ma ate ori ba laasan bi o se
okunrin tabi obinrin won. Sugbon bi a ba wo iran omo Yoruba lookunrin nibi ti o
ti n ki bab, iya tabi agbalagba, pelu idobale gbooro ni. Nwon a na ese, nwon a
si faya bale, nwon a si ni “e kaaro oo”. Baba tabi iya naa yoo dahun pe “Pele
o, Aremu omo Akin, o kaaro, o o jire bi?” Omokunrin ko ni kuro lori idobale
titi baba tabi iya re yoo fi dake. Asa yi ti mora to be ti a fi npe awon omo
Yoruba ni “Omo e kaaro, e o jii re?”
Bi o tise Pataki fun
omokunrin lati ki baba tabi iya re loowuro naa lo je dandan fun omobinrin lati
ki baba tabi iya loowuro bi won ba ji. Idobale ni ti omokunrin sugbon ori
ikunle laa mba omobinrin. Omobinrin a kunle, a si wipe baba tabi iya, e ku aaro
o. Baba tabi iya yoo dahun pe, “Apeke mi, omo Ekun to fin toritori, se daradara
lo ji o?” Omobinrin gbodo duro soori ikunle naa tit obi re yoo fi pari kiki re.
Owuro nikan ko la nki
eniyan ni ile Yoruba. Bi a ti n ki ara wa ku aaro, e ji re, bee laa nki ara w
ape, ‘E ku osan’, ni deede agogo mejila si meji osan; ‘E ku irole ni deede
agogo merin si mefa’; ‘E ku ale ni deede agogo meje ale si monkanla’. Ohun kan
ti o se Pataki ninu asa ikini Yoruba ni wipe, bi o se aaro, osan, irole ati ale
ni, pelu idobale fun omokunrin ati ikunle fun omobinrin la n ki awon to ba ju
ni lo. Yato fun ikunle, eyi ti o wopo laarin awon omobinrin, awon kan tun wa
ninu awon Yoruba t ii fi ori bale bi nwon ba nki ni. Asa iforibale tabi kaa
fori ba iganna tabi igi nigba ti oju ba nkan ni yi wopo pupo laarin awon Ekiti.
Awon oyo lo ni ikunle,
Ekiti lo ni iforibale. Sugbon bayi, asa iforibale yi ti n kasenile, gbogbo awon
omobinrin ile Yoruba ni o maa nkunle ki awon asaaju won. Awon Yoruba tun ki ara
won nigba tin won ba fe lo sun ni ale. Akoko yi ni a ma ngbo pe ‘O daaro o, ki
Olorun ji wa re o, kaa ma toju orun doju iku o, tabi laayo la o ji o’.
Awon ikini Pataki miran
tun wa fun igba otooto, yala ninu odun tabi fun isele ayo ati ti ibanuje. Ni
igba eerun a ma nso pe, ‘e ku eerun yi, eku ogbele yi e ku ooru yi’. Ni igba
ojo a maa nki nip e ‘e ku ojo yi, ku oginnitin yi tabi e ku otutu yi’. Bi o ba
je akoko ti onje won ni a maa nki eniyan pe, e ku iyan, e ku aheje tabi e ku
owon onje yi. Bi o ba si je akoko ti onje po ni a maa nki nip e, ‘e ku opo
onje, e kun mudun-mudun, e ku imuje, e ku iwasaya’. Awon Musulumi ti n gbawe la
nki pe e ku ongbe, e ku ise laada.
Orisirisi ona lo wa ti
a ngba ki awon eniya ni ile Yoruba. Sugbon ma menu ba die ninu re.
A. Aboyun ile laa nki
pe:
E ku idura.
Isokale anfani.
Afon a gbo ko to wo o.
A o gbo ohun iya, a o gbo tomo o.
Tibi tire le o bi o.
Abiwere o.
Eku o ni gbo, eye o ni mo o.
B. Bi aboyun ba sese
bimo re, a o ki pe:
Barika, e ku ewu omo.
Omo tuntun, o ku atorunbo.
Mo yo fun yin o.
Oluwa yoo da omo si, Oluwa yoo wo.
Eku owo lomi.
Yoo loowo rere lehin.
Yoo se omo kale.
Oluwa a somo ni bantale.
Eku owo losun o.
D. Eni ori ko yo ninu
ewu la nki pe:
Barika, e ku orire.
E ku ewu.
E ku inu ire.
Bi o ba ku, ki Olorun yo ni.
E. Bi omo-owo tabi
omode ba jalaisi, a o ki awon obi re pe:
E pele.
E ku amu-mora naa.
Omi lo danu.
Oluwa o nijagbe o fo
Oluwa yoo pese bantale.
Oluwa yoo pese ti elemi gigun.
Oluwa yoo se dada miran.
Olorun a so ibanuje dayo fun yin.
E. Bi odomode ba ku
ninu ewu moto, iji, efuufu tabi ti ina, a o ki awon obi tabi ara re bayi pe:
E pele o, e ku ara fera ku.
E ku ajalu.
E ku iroju.
E ku ofo.
E ku afimora naa.
Olorun yoo fi mo bayi.
Olorun yoo ti ilekun ibanuje.
Olorun o ni je ka ri iru eyi mo.
Ojo a jina si ara won.
Emi a jina semi o.
F. Bi enikan ba wa ninu
ejo tabi aisan, a o ma kii pe:
E ku wahala.
E ku rigboriye.
Ori a ko o yo.
Inu rere a ko o yo.
Edumare a da o lare.
G. Bi enikan ba padanu
ohun ini re sinu ewu ina tabi effufu, a o ma kii pe:
E pele o.
E ku ofo.
E ku adanu.
Ki Oluwa fofo ra emi.
Olorun ko ni je ka riru re mo.
Olorun yoo fi mo be.
GB. Bi baba tabi iya to
lojo lori ba ku, a o ma ki awon omo re pe:
E ku aseyinde
E ku inawo.
E ku idele.
Eyin baba tabi iya a dara.
Olorun a basiri o.
Baba tabi Iya a fohun rere
paroko.
Baba tabi Iya a moore.
I. Eni to sese kole tan
to nsi i la n kip e:
E ku inawo ile yi.
Emi a lo o.
Oluwa ko ni se e ni akota.
Tire tomo ni o lo ile yi.
Ile a tura o.
E o ko eyi to ju yi lo o.
Bi a ti nki awon eniyan
si ohun to sele naa la nki won si ohun ti won nse lowo. Ma menu ba die ninu
orisirisi ona ti a ngba ki eni to n sise lowo.
A. Awon Agbe la ma n ki
pe: Aroko boodun de tabi owo a ya o.
B. Awon Akope tabi
Agunpe la ma nki pe: Igba a ro o tabi Emo o
D. Awon Atuko tabi
Awako la ma nki pe: Oko a refo o.
E. Awon Alaro la ma nki
pe: Aredu o, Areye o tabi Amugbe, ti won a si dahun pe Olokun a gbe o.
E. Awon Onidiri la ma
nki pe: Oju gbooro, ti won a si dahun pe Ooya o, Iya moja a gbe o.
F. Awon Babalawo la
manki pe: Aboru-boye o, ti won a si dahun pe Aboru-boye bo sise, Ifa a gbe o.
G. Awon Ode la ma nki
pe: Arepa ogun, ti won a si dahun pe Arepa ntogu.
GB. Awon Alagbede la ma
nki pe: Aroye o tabi Owu a ro o, ti won a si dahun pe Ogun a gbe o.
Iteriba ati iyesi ti
awon Yoruba ni ni won fi ma n ki oba ati oloye, die ninu ba ti n ki wo niwonyi:
A ma n ki oba pe:
Kabiyesi, alase ekeji orisa.
Kia de pe lori.
Ki bat ape lese.
E o je ju ara iwaju o.
Awon Oloye la nki pe:
Ebo a fin o
Eru a da
Baba re a gbe e o.
E ku eto ilu.
Ori awon oba ati oloye
ma n ya bi a ba nki won bayi, nitoripe a fi han pe a mo riri ipo won. Bi a ba
farabale wo daadaa, a o ri wipe kikini lede Yoruba ko lopin be si ni idahun wok
o si lonka. Asa yi ti wa di ajebi, ko si ohun ti o le gba a sonu lowo wa, bi o
tile je wipe opo omo bibi ile Yoruba lo ti n te asa na mere sugbon “igbo kii di
ka a ma mo Iroko, oja kii di ka a ma mo afin.” Bi o ti wu ki oju la to, a ko ni
saimo omo Yoruba tooto lawujo nibi won gbe nki ni.
Eku ise igbe eko ati agboye Ede Yoruba laruge,
ReplyDeleteE jowo mo ni ibeere lori bawo gaan ni ase ma nki awon Apeja (How do we greet the Fishermen in Yoruba Language)?
E se pupo.
Abiodun
ESE pupo fun Eko yii... Olorun ama ranyi lowo...
ReplyDeleteBawo ni a se nki eni ti o hun eni lowo
ReplyDeleteBawo ni a second nki Amokoko
ReplyDeleteEku use opolo o .ASA wa ko ni baje o.Tiwa lasa
ReplyDeleteE ku ise ede oluko e jowo bawo ni ase n ki ahunso ati idahun.
ReplyDelete