Friday, 19 September 2025

Àlàyé awon òrò ati Itumò

Àáké: Ohun èèlò irin pelebe tí a fi n kétabi là igi.

Ààrò: Ibi ti a n dá iná;ohun ti a n dánáninu rè.

Ààtàn: Ibi ti a n da pàntí sí; àkitàn.

Àáyá: Obo; irú ijímèrè kan.

Abanijé: Eni ti n so oro buburú nipa eni;elénìní.

Abánikówó: Eni ti ó se onídùúró fun èniyàn latiyá owó.

Abanilóríjé: Eni ti n kó ori burúkú bá èniyàn; (itumò ológeere; eni ti ó gé irun orièniyàn bàjè)

Abániré: Òré eni;eni t'ó n bá ni sòré.

Àbàtà: Ilè olómi; ilè erè.

Abarapá: Èniyàn ti ara rè le, tí kò ní àisàntabi àárè.

Abèse: Asebi;eni ti n se jàmbá fun èniyàn

Àbí-ikó: Omo tí a bí tí a kò kó lí èkó.

Abonà:  Eyí tí a se isé onà sí lára,yàto síòbòró.

Àdàpè: Orúko idákóńkó tf a fi pe ènlyàn tí kií se orúko rè gidi; orúko àyésí.

Àdáse: Ohun ti enikan dá se yato si eyi ti èniyàn meji tabi ju bée lo jo se; òdikeji àjose.

Aditi: Eni ti eti rè di tí kò lè gbó orò.

Àdó-isí: Ki a duro si ibikan pelu iforíti ti a kòní kúrò nibe bi o ti wù kí nkan nira tó.

Afaségbèjò: Asé ni ohun-èèlò oníhò lara ti omi kòlè duro ninu rè; eni t'ó n fi asé gbeòjò n dáwólé ohun kan ti ó mò pe kòlè seése.

Afénilóbinrin: Eni ti n fé aya aláya;àlè iyàwó eni.

Afinihàn: Eni tí a gbékèlé sugbon ti ó dalè t'ó sifi ni lé òtá eni lowo.

Agada: Àdá; idà; obe nla.

Agemo: Eégún oníjó.

Àgùàlà: Iràwò ti n bá òsùpá rìn, tí a n pè níajá òsùpá.

Agbada: Ikòkò nla ti a fi n yan àgbàdo,gàrí atiawon ohun mìíràn.

Àgbáti: Èyí tí a gbá jo, tí a kò kó danù; pànti.

Agbèjé: Onísègùn; eni ti a jé èjé fún pé a ó sanowó isé rè nigbà ti alaisan bá ti sàntán.

Agbójúlógún: Ole èniyàn tí kò sisé sugbon t'ó n retikí enikan kú kí oun sì jogún dúkiá rè.

Àgbólà: Gbígbó (igbe) tí eranko ké tí àisàn ararè gbon danu, ti kò si kú mó; igbe igbàlà.

Àgbó-igbótán: Èdè ti a gbó die sugbon ti a kò gbógbogbo rè tán.

Agbón: Kòkòrò kan ti orí re tóbi, idí re tóbi, sugbon agbedeméji rè tín-in-rín, ó nta èniyàn bi oyin ti í ta èniyàn.

Tuesday, 16 September 2025

Oríkì ìdílé Amẹ́lẹ̀

Oríkì ìdílé Amẹ́lẹ̀ je ìyìn fún ìdílé kan tí orúkọ wọn jẹ́ Amẹ́lẹ̀ (itumó: “One conditioned to gentleness” / “Ẹni tí a tí mú sí i ìfarabalẹ̀ / ìrẹ́pọ̀”). 

Oríkì ìdílé Amẹ́lẹ̀

Amẹ́lẹ̀, jẹ́ ìjẹ́tọ́ ìfẹ́,

Ẹbí tí ìrẹ́pọ̀ ń rójú lórí ilé,

Ogún ìyì ń tọ́ wọ́n báyìí,

Ẹni tí ìfarabalẹ̀ ni ọkàn wọn,

Àánú lọ́kọ̀ọ́kan, ìtùnú ní gbogbo ìgbà.

Ẹbí tí ọ̀pẹ́ ń san bí odò,

Ẹni tí ìwà rere ń ṣọrun sí i,

Amẹ́lẹ̀, ìfẹ́ kò ṣẹ́ ní ilé yín,

Ọmọ rẹ̀ jẹ́ àkúfọ̀jọ tó ní ìbọ̀rẹ́,

Ọmọ òyìnbó rẹ̀ kọ́ ní gbé, ṣùgbọ́n nípa ìṣé ní ń dí àṣẹ,

Bí ọ̀sán ti ń tan lórí òkè, bẹ́ẹ̀ ni ìmọ́lẹ̀ yín ń tan.

Ohun gbogbo tí ẹ̀ dá lè rí;

Ilé yín kún fún ayọ̀, ìlera, orí burúkú kò ní bọ́ lẹ́yìn,

Ẹ̀bùn Ọlọ́run ń sún mọ́ra, ìbọ̀rẹ́ ń pẹ́ kí ó má ṣetán,

Orí yín máa ga, ojú ọ̀run sì máa tìrẹ,

Amẹ́lẹ̀, ìfọkànbalẹ̀, ìtọ́jú, ìfẹ́ gidi ni pé.

Oríkì Ẹ̀ta Òkò

Oríkì Ẹ̀ta Òkò jẹ́ oríkì fún ìbejì mẹ́ta (triplets) ní àṣà Yorùbá. “Ẹ̀ta Òkò” túmọ̀ sí “mẹ́ta òkò” – òkò ní ìtàn pé ibi tí ìbejì mẹ́ta ti wá sí ayé ni Oko­lè, ìlú kan ní agbègbè Ògbómọ̀ṣọ́. 


Oríkì Ẹ̀ta Òkò

Ọmọ mẹ́ta, ìrẹ́pọ̀ bí okuta mẹ́ta,

Ẹyọ́ ọwọ́ rere, ìbùkún ayé,

Ẹ̀yin ọmọ tí ọ̀run tùrù ní ọjọ́ ìbí yín,

Ẹ fàájì, ẹ jókòó ní ìbùkún,

Ẹ̀ta òkò, a kì í ya yín ní gígùn ọ̀nà,

Ẹ gbẹ́kẹ̀lé ara yín bí èso ìrẹsì tí kò́ ń tú,

Ẹ lọ́wọ́́ àwọn àmì ayé: ìyè, ìlera, àsá, ọlá.

Olórí gbogbo ọmọ ìbílẹ̀,

Ẹ wí ìtàn ìbùkún,

Ẹ ló ànímọ́́ra ti ìdílé àti agbára,

Ẹ̀ta òkò náà ń jẹ́ kí ilé ń rẹ́rìn-ín,

Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìrìn-ajo yín ní ayọ̀,

Ọlọ́run yóò fi ìmọ̀́ra yín sábà,

Kí àánú àti ọ̀pẹ́ tirẹ̀ pọ̀ sí i ní gbogbo ọjọ́.



E bàwa pin àwon àkosílè yí lórí àwon ibanidore yin fun ìwúnilórí

Oríkì Olugbodi

Oríkì Olugbodi ní oríkì tàbí ìyìn fún ẹni tí a ń pè ní “Olugbodi.” “Olugbodi” jẹ́ orúkọ àmútọ̀runwá Yorùbá; ó túmọ̀ sí “ẹni tí awọn ọwọ́ rẹ̀ ló ní ọwọ́ mẹ́fà” (child born with six fingers).

Nípa ìtumọ̀ orúkọ:

“Olugbodi” túmọ̀ sí ẹni tí ó ní ìka bọ̀dì (ẹni tí ìka kàn yàtọ̀ sí ti gbogbo ènìyàn).

A máa kà á sí àṣeyọrí tàbí àmì ìbùkún Ọlọ́run, kì í ṣe àìlera.

Nípa àṣà:

Ní ilè Yorùbá, ọmọ tó bá jẹ́ Olugbodi a maa jẹ́ kí wọ́n mọ̀ pé ó ní àṣẹ àti orí rere.

A máa nbọ́ wọ́n, a máa pe wọn ní ọmọ rere tí kò wọ́pọ̀, a sì maa ka wọn sí ẹni tí orí wọn yóò gbé wọ́n sókè.


Oríkì Olugbodi

Olugbodi, omo ọwọ́ mẹ́fà,

Ara rẹ́ a dà bí ẹ́dá ológo,

Ariwo ilu ń fún ọ̀rẹ́ ọ̀pẹ́,

Aye yóò ranti ipa rẹ;

Ọ̀nà rẹ̀ mọ́ra, ìgbẹ́yà rẹ̀ gíga,

Olugbodi, ìbúgbé gba ọ,

Ohun gbogbo ti a fẹ́ rí, kọ́ lára rẹ,

Ọlọ́run o fẹ́ kí ìbọ̀rẹ́ rẹ̀ pọ̀ sí i.


E bàwa pin àwon àkosílè yí lórí àwon ibanidore yin fun ìwúnilórí

Monday, 1 November 2021

Awon Aso Ile Yoruba

Aso awon Yoruba yato si amulumala ti a now ni ode oni. Awon okunrin ni aso tiwon, beni awon obinrin ni aso tiwon pelu. Opolopo as ni omode le lo ti ko si ye ki agbalagba wo iru re. Aye nyi a nto o. Aye ti di aye olaju. Ni akoko kan, ihoho omoluwabi ti a was aye naa ni a nrin kiri. Ki ise iran Yoruba ti o wa nibe yi lansor re sugbon iran awon baba nla baba wa. Ti nwon ba ti ri ohun kan bo idi won, oro ti buse.
Ni aye atijo ohun ti o se Pataki julo ti awon omode ati opolopo awon agbalagba ti o je agbe maa now ni ibante. Ibante yi, fun opolopo igba, aso kijipa ni a maa nfi ran an. Nwon maa nso okun meji sii ni igun mejeeji eyi ni a si maa nfi soo mo idi. Nigba ti a ba ti so okun meji ti o wa ni igun wonyi mo idi wa, a o wa la aso naa bo idi wa, a o si fi okun ti a so si igun re ni isale boo kun ti a so mo idi wa yika pelu iru ibante yi ni idi wa, ki a maa ba ise lo loko ni pereu loku.
Awon as miran ti awon okunrin maa n lo ni ile Yoruba bere lori aso egbejoda lo si asso ijade.
Dandogo
Okan lara awon aso ijade fun okunrin ni ile Yoruba ni dandogo je. Dandogo je aso ti o tobi pupo. Ti a bad a tan, o gbodo de orun ese, sugbon dipo ki o kun mo eniyan lara, pasoro ni o maa nse lo si isale. A kii la egbe dandogo de isale. Lati isale se enu ibadi a maa nran an pa ni a o wa ran apa mo o lati enu ibadi wa si ibi orun ewu naa; nitori idi eyi, apa dandogo maa nri pasoro bi ti ara ewu naa. Nwon maa n ko ona si aso yi lara niwaju ati lehin ati ni orun pelu. Eleyi ko je ki o roru fun awon aranso lati le ean an kiakia. Idi niyi ti a fi ma n pa lowe pe “Dandogo koja abinuda.”
Agbada
A le fi aso oke tabi aso oyinbo da agbada. Agbada tobi gan, sugbo ko soro lati da bi igba ti a ba fed a Dandogo. Ara agbada ko gbodo ri pasoro bi ara dandogo. Apa agbada si maa nla kanle gbooro ni. Nwon maa nfi opolopo abe bo inu agbada gege bi dandogo; a si maa nko ona sii niwaju ati l’orun ati lehin pelu. Awon agbalagba lo saaba maa nlo agbada; sugbo awon omode ti owo won ba ji sowo naa le lo agbada.
Gbariye
Okan lara awon aso Yoruba ni gbariye je. Aso ti o ba wu wa ni a le fi daa. O maa nde isale ese wa ti a ba ran an tan. Ko ni apa nla bi ti agbada tabi dandogo, a maa nse apo meji sii niwaju, a si maa nko enu apo naa daadaa. A ma nyo abe si gbariye daadaa, eleyi maa nje ki o kun mo wa lara gidigidi.
Sulia
Okan lara awon aso ijade Yoruba ni sulia je. Ohun ti o se Pataki nipa re nip e toke-tile ni a maa nfi iru aso bayi da. Looto, ewu re ni a npe ni sulia, sugbon ko si eni ti o le wo sulia laiwo awotele re ati sokoto soro re. Iru as kan naa ni a si gbodo fi ran awotele ati soro re.
Oyala
Eleyi da bi sulia sugbon ko tun tobi to sulia daadaa. O ye ki oyala naa ni awotele ati soro. Iru aso kanna ni o si ye ki a fi ran awotele ati soro ati oyala yi. Oyala naa, bi ti sulia, ko ni abe bi ti awon agbada ati dandogo.
Buba
Eleyi je aso ti a le wo, yala gegebi awotele tabi gegebi aso iwole fun ara re. Aso fulefule bi as oyinbo ni a saaba maa nfi ran buba. Buba le je olowo gigun tabi olowo kukuru. A maa nla buba laya, a o si fi botini bi ti awon aso ti oku, apa buba maa nse pooro.
Dansiki
Okan ninu awon aso ti a le wo gegebi awotele tabi ki a woo gegebi aso iwole fun ara re. Dansiki yi ni awon ara Ibadan maa npe ni esiki, o je ewu kekere ti a maa nla ni egbe meji lati yo abe jade. Ti a ba fe ki dansiki kun die, a le yo abe merin sii- meji niwaju, meji lehin.
Sokoto
Eleyi ni awon Yoruba maa now si idi nigba tin won ba ti wo aso tan. Orisirisi sokoto ni o si wa. Sanyinmotan ni sokoto akoko ta koko soro le lori. A maa nda sokoto yi koja orokun die, yoo si fun mo ese wa timotimo. A maa nllo iru sokoto yi ti a ba fe se ise kan tabi ti a ba fe lo si irin ajo ti a ko si fe ki sokoto nla ma yow a lenu.
Sokoto keji ti a o tun so nipa re ni a n pe ni soro ni ile Yoruba. Sokoto soro maa nde orun ese wa, enu re ko gbodo se yauyau; oun ni a si maa nlo si awon aso bi buba; sulia ati oyala.
Kembe tabi Abadan ni orisi sokoto miran ti a o tun menu ba. Sokoto kembe yi maa ntobi pupopupo lati isale, sokoto naa yoo maa tere sii titi yoo fi de orun ese nibi to o ti fun mo ese daadaa, Abe sokoto yi maa ntobi gidigidi nitori pea won aranso maa nran jagburu, ti a ba sig be omode pamo sinu sokoto yi, a feree le wa ti.
Efa ni orisi sokoto miran ti a ko gbodo mo menu ba, oun na si ma ntobi. Ni badi, o feere tobi to kembe. Abe efa ko nri jagburu bi abe kembe, sugbon ese efa ko nfun mo wa ni orun ese bi ti kembe. Awon agbalagba lo maa nlo iru sokoto yi nitori pea won omode ko feran sokoto ti o ba je labu bi iru eleyi mo.
Fila
Awon Yoruba ko gba pe eniyan ti wo aso bi omoluwabi bi o ba wo ewu ati sokoto lasan lai de fila. Lehin igba ti won ba ti de fila tan ni nwon sese le jade gegebi omoluabi.

Tuesday, 5 December 2017

Oriki



Asa kan Pataki ti awa omo Yoruba ngbe sonu bayi ni asa oriki. Orisirisi idile ni o ni oriki tiwon. Bi o ba je iya agba tabi baba agba, paapaa julo iya agba; bi omo re ba nlo si irnajo, tabi ki o ti irinajo de; tabi ki se nkan isiri kan; ohun ti o koko maa se ni ki o gba omo naa mu, ki o si kii deledele. Nigba ti o ba ki sile iya, a tun ki si ile baba.
Yato si gbogbo eleyi, awon oriki ile Yoruba wa ninu awon arofo ti o sunwon ju ohun ti a le gbo. Orisirisi itan ayeraye; orisirisi itan idile ati ibi ipilese olukuluku ni awon Yoruba sopo tin won si ti ri oriki won. Oriki je awon oro isiri ti awon Yoruba ma n fi yin ara won tabi eni ti inu won ba dun si. Asa yi ni a fi nda eniyan lara ya fun ohun rere to se tabi lati fihan eniyan nigbamiran pe inu wa dun si oluware. Bi eniyan ban se ise tabi o njo loju agbo, bi o ba gbo oriki re, ara re a ya gaga a si mura si ohun ti o ban se nigbana daradara.

Orisirisi ona la nki eniyan si. Bi a ti nki Oba bee la nki mekunnu pelu. A nki Oba bi ile ati agbara re ba ti to. A sit un le ki si owo ti o bay o nigba ti o gun ori ite oye. Iru oro tabi ayo oro ijinle bee ti o suyo ninu oruko eniyan tabi ise re laa npe ni oriki.

A le ki Oba bayi pe:
Kabiyesi Oba luwaye
Odundun asolu dero
Oba ade kile roju
Oba ade kile rorun
Arowolo bi Oyinbo
O fiile wu ni
O foona wu ni
Ogbigba ti ngba ara adugbo
Oba ataye ro bi agogo
Awon Yoruba tun gbadun lati maa fi oriki da eniyan laraya yala lojo igbeyawo ni, iwuye ni, ikomo ni, ile kiko ni tabi ohun ayo miran ti a nse lowo.
A le ki eniyan si oruko re, paapaa oruko amutorunwa bi apeere Idowu, Ige, Ojo, Dada, Ajayi ati bebe lo.
O ya e je ka wo oriki won lokookan:

Idowu la maa nki bayi pe:
Idowu ogbo
Ogbo asogede jia
Esa okun
Monganna aro, abikere leti
Esu lehin ibeji
Idowu eru ibeji, eketa omo.

Ige la maa nki bayi pe:

Ige adubi
Agbolenu bi agogo
Omo onigba irawo
Bi iya leku, ko ku
Bi baba le lo, ko maa lo
Elegede mbe loko
Gboro mbe laatan
Ohun Ige Adubi o je, ko nii won on
Ige ko roju iya
Oju baba lo ro
Ige iba roju iya
Ki ba kese sita
Eni be Ige Adubi nise
Ara re lo be.

Ojo la maa nki bayi pe:
Ojo olukori, Ojo Yeuge
Ojo olukori, ogede soomo gbagan gnagan
Ojo kure, alagada ogun
Ojo jengetiele
Ojo osi nle, omo adiye dagba
Ojo tajo de, omo adiye ku fenfe
Okinakina ti ntoju aladiye kii na
Ojo kenke bi ele
Esin rogun jo omo yeye ni
Ojo ajo ni ewe
Ojo ti new lodo, tomoge nnawo ose
Ojo sun nile ba ara re leru
Ojo akitikori, ajagun bi akura
Ojo ajowu bi eni jeran
Ojo alade igbo jingbinjingbin
Ojo abija bi eni tarin
Ojo ajagun loju ologun
Ojo agbogungboro, aranti oro ehin
Ojo arigbede joye
O fi gbogbo ara sode ekute
O fi obeke sode agbonrin o
O fi ako okuta sode erin
Ojo ababa-tiriba
Ojo elete ko gbodo pa loju eni
Amele ijakaki ija bi eni jagun aremabo
Ojo kurekure, alagada ogun

Dada la maa nki bayi pe:
Dada awuru yale, yagi oko
Olowo eyo, gbongbo ni ahoro
Asiso o lara
Otosi o niyekan
Dada ogbegun, irunmangala
Eran gbigbe o nijanja
Aladeleye, abisu jooko
Dada ogbegun
Mo rade yo obinrin
Gbon ori ade
Gbo ori esu siwaju
Dada ogbegun
Gbo ori oro sodo mi

Ajayi la nki bayi pe:
Ajayi, ogidiolu
Ololo, onikanga ajipon
Obomi osuuru weda
Ekun baba ode
Ekun pakoko wole
Eni Ajayi gba gba gba
Ti o le gba tan, Igunnugun nii gba oluware
Ajayi ti n we lodo
Ti gbogbo omoge nyowo ose
Daramodu ose temi ni o gba
Ajayi a sin gbewa
Ajayi lerin oje, arowosoge
Ohun mira ti a tun se akiyesi nipa oriki nip e bi a se n ki okunrin bee la nki obinrin pelu. Ko si eni ti ko ni oriki tire ninu won. Awon oriki ti o je mo obinrin le suyo nipa oruko won tabi ile ti a ti bi won. Bi o ba je eyi ti o je mo idile ni, tokunrin tobinrin la o maa so oriki bee si, Fun idile ti a tin se egungun, a le ki won si egungun. Bi apeere ni
Omo Egungun
Omo Epa
Omo Oniyara ajeji ko le wo
Ajeji ti o wo ibe, o di eni ebo
A le ki okun tabi obinrin ti o ba je ibeji. Oruko amutorunwa naa ni ti won. Oriki won ko si soro pupo paapaa lenu awon abiyamo. 

A nki awon ibeji bayi pe:
Ejire okin, ara isokun
Yindin yindin loju orogun
Eji woro loju iya
Eji nba bi  nba yo
Omo ko ile alaso
Wo o lopolopo a wo fi seerin
O so alakisa di alaso
Ejire Okin omo edun nsere ori igi

Asa Isomoloruko

Asa isomoloruko je okan pataki ti a ko le ko danu ninu as Yoruba, id niyi ti awon Yoruba fi ya ojo isomoloruko yi si oto lai tele eto ti awon babanla wa ti fi lele. Bi ojo isomoloruko ti se Pataki to ni, sibesibe eto ati inawo re yato lati ilu si ilu. Bi aboyun ile ba bi tibi, tire, gbogbo ebi idile oko ati idile re ni yoo wa kii barika, e ku ewu omo. Orisirisi ibeere laa o maa gbo lati enu awon eniyan lati fi mo iru omo ti eni naa bi. Nwon a ma beere pe, ako (okunrin) ni tabi abo (obinrin).
Nibi ti aboyun ti nrobi ni agbalagba tin se akiyesi iru omo ati oruko ti o le je. Ona ti omo naa gba waye gba akiyesi pelu, yala ese lo fi jade ni tabi ori ni. Ise omo naa lehin ti a bi tan wa ninu akiyesi bakan naa. A o se akiyesi boya omo naa nsokun pupo loru tabi ko fe ki a ro oun ni ounje lori idubule. Bi o ba je omo ti nsokun pupo loru a o ma ape ni Oni, bi ko ba si fe ka ro oun lonje lori idubule, a o maa pee ni Oke. Bakan naa ni awon Yoruba maa nse akiyesi akoko ti a bi omo si. Eyi ti a ba bi ni akoko odun laa npe ni Bodunde tabi Abiodun. Eyi ti a ba bi lakoko ibanuje awon obi maa npe ni Remilekun, Dayo tabi Ehundayo. Eyi ti a bi lakoko ayo tabi igbadun awon obi la npe ni Adebayo, Adesola, Ayodeji, Bolaji, Bolanle ato bebe lo. Bi o ba si je omo ti a bi lehin ti iya omo naa ti se abiku titi, a o maa pee ni Ropo, Kokumo, Igbokoyi, Kosoko. Omo ti a bi si oju ona oko tabi oja tabi odo laa npe ni Abiona. Eyi ti a bi sinu ojo tabi lakoko ti ojo nro laa npe ni Bejide.
Gbogbo ohun lo ni akoko tire. Bee ni akoko wa fun isomoloruko. Ojo kesan ti a ba bi omokunrin ni a maa nso loruko, ojo keje ni ti omobinrin. Ojo kejo si ni ti awon ibeji. Iba je ako tabi abo, awon onigbagbo ati imole a maa so omo won loruko ni ojo kejo ti a ba bi omo. Eleyi wa ni ibamu pelu asa ati eto isin won. Ni igba atijo, iya omo tuntun ko gbodo jade tit a o fi se isomoloruko. Inu iyara ni iya omo naa yoo duro titi a o fi ko omo naa jade. Ojo isomoloruko yii ni iya omo yoo gbe omo jade, yoo si joko sarin gbogbo ebi. Eto nipa akiyesi akoko, ipo ati irin ti omo naa rin yoo ti pari ki a to se isomoloruko yi. Awon miran ko asa ati maa se iwadi tabi ayewo si oruko ti o ye ki omo tuntun maa je.
Ni ibomiran, lehin ti gbogbo ebi ati ojulumo ba pe jo tan, iyale ile naa yoo bu omi si ori orule, yoo si fi ara omo tuntun naa gba osooro omi tin san ti ori orule bo. Bi omo tuntun ba ti fi ara gba omi yi tan ni yoo kigbe bi ti ojo ti a bii si aye. Gbogbo ebi yoo bu serin, nwon o pariwo pe omo tuntun, o ku atorunbo, aye dun, bawa je o. Ni kete ti a ba se eyi tan ni bale ile yoo gba omo na, yoo si se alaye bi omo naa se was aye, iru akoko ti omo naa wa si aye boya akoko ayo ni tabi ibanuje fun awon obi re.
Baale ile yoo maa mu awon ohun tie nu nje ti a ti pese sile gegebi orogbo , iyo, oyin, omi tutun ati oti tabi ohun miran ti a ban lo ni idile naa lati fi se adura fun omo naa. Awon oruko miran ti a tun le fun awon omo lehin ti a ba ti wo idile re niyi:
Fun Idile Ola:
Afolabi, Olabode, Olaleye, Afolalu, Olarewaju, Olabisi, Olaitan Ajibola, Popoola, Ladigbolu, Agboola, Ojuolape, Olawoyin, Kolawole, Lakanmi, Oladipo ati bebe lo.
Fun Idile Alajagun:
Akinwande, Akinyemi, Akinbode, Akinsanya, Akinlotan, Akinola, Akinwumi, Akintola at bebe lo
Fun Idile Oloye:

Oyediran, Oyewumi, Oyeyemi, Oyekanmbi, Oyetusa, Oyenike, Olowofoyeku, Oyegbenga ati bebe lo.
Fun Idile Alade:
Adekanmi, Adegbite, Adesina, Aderemi, Adeniyi, Adelabu, Adegoke, Adesoji, Ademola, Adebiye, Adedoyin Adesida, Adeyefa, Adeyemi, Atilade, Adegboye ati bebe lo.
Fun Idile Awo:
Awolowo, Awosika, Awotoye, Fasuyi, Fajuyi, Fagbemi, Odutola, Fayose, Fabunmi, Fadahunsi, Fakunle ati bebe lo.
Fun Idile Ode:
Odewale, Odeyemi, Odesanmi, Odewumi, Odegbenro, Odesakin, Odesiyan ati bebe lo.

Fun Idile Oloogun:
Ogundele, Ogunde, Ogunmola, Ogungbade, Ogunbiyi, Ogunsola, Ogundeji ati bebe lo.
Fun Idile Oloosa:
Osagbemi, Osunremi, Osunbiyi, Osunluyi, Osuntokun, Omitade, Efunkemi, Aborisade Abegunde, Aborode, Omiremi ati bebe lo.
Fun Inagije tabi Apeje:
Jegede, Omodara, Jeje, Okonrin-jeje, Logunleko, Afelebe ati bebe lo.
Fun Abiku Omo: Matanmi, Igbekoyi, Kosoko, Akinsatan, Kokumo, Bamitale, Lambe ati bebe lo.
Fun obinrin ti a po toju re: Aduke, Abike, Apeke, Amoke, Apinke, Abeke, Alake, Akanke, Arike, Ajoke ati bebe lo.
Gbogbo awon ona wonyi laa gbodo wo ki a to so omo loruko. Igbagbo awon Yorubqa nip e bi omo ba si oruko je ko ni gbadun. Eyi nip e yo maa yo iya ati baba re lenu nipa sise aisan tabi dida wahala miran kale. Idi niyi ti owe kan lede Yoruba fi so pe “Ile laa wo ka to somo loruko.”